Owe 10:1-8
Owe 10:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
OWE Solomoni ni wọnyi. Ọlọgbọ́n ọmọ ṣe inu-didùn baba rẹ̀, ṣugbọn aṣiwere ọmọ ni ibanujẹ iya rẹ̀. Iṣura ìwa-buburu kò li ère: ṣugbọn ododo ni igbani kuro lọwọ ikú. Oluwa kì yio jẹ ki ebi ki o pa ọkàn olododo; ṣugbọn o yi ifẹ awọn enia buburu danu. Ẹniti o ba dẹ̀ ọwọ a di talaka; ṣugbọn ọwọ awọn alãpọn ni imu ọlà wá. Ẹniti o ba kojọ ni igba-ẹ̀run li ọlọgbọ́n ọmọ: ṣugbọn ẹniti o ba nsùn ni igba ikore li ọmọ ti idoju tì ni. Ibukún wà li ori olododo: ṣugbọn ìwa-agbara ni yio bo ẹnu enia buburu. Ibukún ni iranti olõtọ: ṣugbọn orukọ enia buburu yio rà. Ọlọgbọ́n inu ni yio gbà ofin: ṣugbọn ete werewere li a o parun.
Owe 10:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn òwe Solomoni nìwọ̀nyí: Ọlọ́gbọ́n ọmọ á máa mú kí inú baba rẹ̀ dùn, ṣugbọn òmùgọ̀ ọmọ a máa kó ìbànújẹ́ bá ìyá rẹ̀. Ọrọ̀ tí a kójọ lọ́nà èrú kò lérè, ṣugbọn òdodo a máa gba eniyan lọ́wọ́ ikú. OLUWA kì í jẹ́ kí ebi pa olódodo, ṣugbọn ó máa ń da ìfẹ́ ọkàn eniyan burúkú rú. Ìmẹ́lẹ́ máa ń fa òṣì, ṣugbọn ẹni tí ó bá tẹpá mọ́ṣẹ́ yóo di ọlọ́rọ̀. Ọlọ́gbọ́n ní ọmọ tí ó kórè ní àkókò ìkórè, ṣugbọn ọmọ tí ó bá ń sùn lákòókò ìkórè a máa kó ìtìjú báni. Ibukun wà lórí olódodo, ṣugbọn eniyan burúkú a máa fi ìwà ìkà sinu, a sì máa sọ̀rọ̀ rere jáde lẹ́nu. Ayọ̀ ni ìrántí olódodo, ṣugbọn orúkọ eniyan burúkú yóo di ohun ìgbàgbé. Ọlọ́gbọ́n a máa pa òfin mọ́, ṣugbọn òmùgọ̀ onísọkúsọ yóo di ẹni ìparun.
Owe 10:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn òwe Solomoni: ọlọ́gbọ́n ọmọ ń mú inú baba rẹ̀ dùn ṣùgbọ́n aṣiwèrè ọmọ ń ba inú ìyá rẹ̀ jẹ́. Ìṣúra tí a kójọ nípa ìwà búburú kò ní èrè ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú. OLúWA kì í jẹ́ kí ebi máa pa olódodo ṣùgbọ́n ó ba ète àwọn ènìyàn búburú jẹ́. Ọwọ́ tí ó lẹ máa ń sọ ènìyàn di tálákà, ṣùgbọ́n ọwọ́ tí ó múra ṣíṣẹ́ a máa sọ ni di ọlọ́rọ̀. Ẹni tí ó kó irúgbìn jọ ní àsìkò òjò jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ó sùn ní àsìkò ìkórè jẹ́ adójútini ọmọ. Ìbùkún ní ó máa ń kún orí olódodo ṣùgbọ́n ìwà ipá máa ń kún ẹnu ènìyàn búburú. Ìrántí olódodo yóò jẹ́ ìbùkún ṣùgbọ́n orúkọ ènìyàn búburú yóò jẹrà. Ẹni tí ó gbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ máa ń gba àṣẹ, ṣùgbọ́n ètè wérewère yóò parun.