Owe 1:1-15

Owe 1:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn òwe ti Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli. Láti le ní ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́, Láti ní òye àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀. Láti gba ẹ̀kọ́ ọgbọ́n, òdodo, àti ìdájọ́, àti àìṣègbè; láti fi òye fún onírẹ̀lẹ̀, ìmọ̀ àti ìṣọ́ra fún àwọn èwe. Jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n tẹ́tí kí ó sì ní ìmọ̀ kún ìmọ̀, sì jẹ́ kí ẹni òye gba ìtọ́sọ́nà. Láti mọ ìtumọ̀ òwe àti ìtán-dòwe, àwọn ọ̀rọ̀ àti àlọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n. Ìbẹ̀rù OLúWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀, ṣùgbọ́n aláìgbọ́n kẹ́gàn ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́. Tẹ́tí, ìwọ ọmọ mi sí ẹ̀kọ́ baba rẹ, má ṣe kọ ẹ̀kọ́ màmá rẹ sílẹ̀. Wọn yóò jẹ́ òdòdó ẹ̀yẹ olóòórùn dídùn lórí rẹ àti ọ̀ṣọ́ tí ó dára yí ọrùn rẹ ká. Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́, má ṣe gbà fún wọn. Bí wọn bá wí pé, “Wá pẹ̀lú wa; jẹ́ kí á ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan, jẹ́ kí á lúgọ ní ìkọ̀kọ̀ de aláìṣẹ̀ ní àìnídìí; Jẹ́ ká gbé wọn mì láààyè, bí ibojì òkú, àti lódidi, bí àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sínú kòtò; A ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó níye lórí a ó sì fi ìkógun kún inú ilé wa; Da ìpín rẹ pọ̀ mọ́ àárín wa, a ó sì jọ pawó sínú àpò kan náà” Ọmọ mi, má ṣe bá wọn lọ, má ṣe rìn ní ojú ọ̀nà wọn