Filp 3:9-15
Filp 3:9-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki a si le bá mi ninu rẹ̀, li aini ododo ti emi tikarami, ti o ti inu ofin wá, ṣugbọn eyi ti o ti inu igbagbọ wá ninu Kristi, ododo ti Ọlọrun nipasẹ igbagbọ́: Ki emi ki o le mọ̀ ọ, ati agbara ajinde rẹ̀, ati alabapin ninu ìya rẹ̀, nigbati mo ba faramọ ikú rẹ̀; Bi o le ṣe ki emi ki o le de ibi ajinde awọn okú. Kì iṣe pe ọwọ mi ti tẹ ẹ na, tabi mo ti di pipé: ṣugbọn emi nlepa nṣo, bi ọwọ́ mi yio le tẹ̀ ère na, nitori eyiti a ti di mi mu pẹlu, lati ọdọ Kristi Jesu wá. Ará emi kò kà ara mi si ẹniti ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ na: ṣugbọn ohun kan yi li emi nṣe, emi ngbagbé awọn nkan ti o wà lẹhin, mo si nnàgà wò awọn nkan ti o wà niwaju, Emi nlepa lati de opin ire-ije nì fun ère ìpe giga Ọlọrun ninu Kristi Jesu. Nitorina, ẹ jẹ ki iye awa ti iṣe ẹni pipé ni ero yi: bi ẹnyin bá si ni ero miran ninu ohunkohun, eyi na pẹlu ni Ọlọrun yio fi hàn nyin.
Filp 3:9-15 Yoruba Bible (YCE)
Ati pé kí á lè rí i pé mo wà ninu Jesu ati pé n kò ní òdodo ti ara mi nípa iṣẹ́ Òfin bíkòṣe òdodo nípa igbagbọ. Gbogbo àníyàn ọkàn mi ni pé kí n mọ Kristi ati agbára ajinde rẹ̀, kí èmi náà jẹ ninu irú ìyà tí ó jẹ, kí n sì dàbí rẹ̀ nípa ikú rẹ̀, bí ó bá ṣeéṣe kí n lè dé ipò ajinde ninu òkú. Kì í ṣe pé ọwọ́ mi ti bà á ná, tabi pé mo ti di pípé. Ṣugbọn mò ń lépa ohun tí Kristi ti yàn mí fún. Ẹ̀yin ará, èmi gan-an kò ka ara mi sí ẹni tí ó ti dé ibi tí mò ń lọ. Ṣugbọn nǹkankan ni, èmi a máa gbàgbé ohun gbogbo tí ó ti kọjá, èmi a sì máa nàgà láti mú ohun tí ó wà níwájú. Mò ń làkàkà láti dé òpin iré-ìje mi tíí ṣe èrè ìpè láti òkè wá: ìpè Ọlọrun ninu Kristi Jesu. Nítorí náà, gbogbo àwa tí a ti dàgbà ninu ẹ̀sìn kí á máa ní irú èrò yìí. Bí ẹnikẹ́ni bá wá ní èrò tí ó yàtọ̀ sí èyí, Ọlọrun yóo fihàn yín.
Filp 3:9-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí a sì lè bá mi nínú rẹ̀, láìní òdodo tí èmi tìkára mi, tí ó ti inú òfin wá, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti inú ìgbàgbọ́ wá nínú Kristi, òdodo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìgbàgbọ́; Èmi mọ̀ ọ́n, àti agbára àjíǹde rẹ̀, àti láti jẹ́ alábápín nínú ìyà rẹ̀ nígbà tí mo bá fi ara mọ́ ọn nínú ikú rẹ̀; nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀ kí èmi lè ní àjíǹde kúrò nínú òkú. Kì í ṣe pé ọwọ́ mi ti tẹ̀ ẹ́ ná, tàbí mo ti di pípé: ṣùgbọ́n èmi ń lépa sí i, bí ọwọ́ mi yóò lè tẹ èrè náà nítorí èyí tí a ti dì mímú pẹ̀lú, láti ọ̀dọ̀ Kristi Jesu wá. Ará, èmi kò kara mi sí ẹni ti ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ́ ná: Ṣùgbọ́n ohun kan yìí ni èmi ń ṣe, èmi ń gbàgbé àwọn nǹkan tí ó ti kọjá. Lẹ́yìn náà mo ń nàgà wo àwọn nǹkan tí ó wà níwájú. Èmi ń lépa láti dé òpin eré ìje náà fún èrè ìpè gíga Ọlọ́run nínú Kristi Jesu. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí àwa tí a dàgbà nípa ti ẹ̀mí ni èrò yìí; bí ẹ̀yin bá sì ní èrò mìíràn nínú ohunkóhun, èyí náà pẹ̀lú ni Ọlọ́run yóò fihàn yín.