Filp 3:7-16
Filp 3:7-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn ohunkohun ti o ti jasi ère fun mi, awọn ni mo ti kà si òfo nitori Kristi. Nitõtọ laiṣe ani-ani mo si kà ohun gbogbo si òfo nitori itayọ ìmọ Kristi Jesu Oluwa mi: nitori ẹniti mo ti ṣòfo ohun gbogbo, mo si kà wọn si igbẹ́, ki emi ki o le jère Kristi, Ki a si le bá mi ninu rẹ̀, li aini ododo ti emi tikarami, ti o ti inu ofin wá, ṣugbọn eyi ti o ti inu igbagbọ wá ninu Kristi, ododo ti Ọlọrun nipasẹ igbagbọ́: Ki emi ki o le mọ̀ ọ, ati agbara ajinde rẹ̀, ati alabapin ninu ìya rẹ̀, nigbati mo ba faramọ ikú rẹ̀; Bi o le ṣe ki emi ki o le de ibi ajinde awọn okú. Kì iṣe pe ọwọ mi ti tẹ ẹ na, tabi mo ti di pipé: ṣugbọn emi nlepa nṣo, bi ọwọ́ mi yio le tẹ̀ ère na, nitori eyiti a ti di mi mu pẹlu, lati ọdọ Kristi Jesu wá. Ará emi kò kà ara mi si ẹniti ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ na: ṣugbọn ohun kan yi li emi nṣe, emi ngbagbé awọn nkan ti o wà lẹhin, mo si nnàgà wò awọn nkan ti o wà niwaju, Emi nlepa lati de opin ire-ije nì fun ère ìpe giga Ọlọrun ninu Kristi Jesu. Nitorina, ẹ jẹ ki iye awa ti iṣe ẹni pipé ni ero yi: bi ẹnyin bá si ni ero miran ninu ohunkohun, eyi na pẹlu ni Ọlọrun yio fi hàn nyin. Kiki pe, ibiti a ti de na, ẹ jẹ ki a mã rìn li oju ọna kanna, ki a ni ero kanna.
Filp 3:7-16 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn ohunkohun tí ó ti jẹ́ èrè fún mi ni mo kà sí àdánù. Mo ka gbogbo nǹkan wọnyi sí àdánù nítorí ohun tí ó ṣe iyebíye jùlọ, èyí ni láti mọ Kristi Jesu Oluwa mi, nítorí ẹni tí mo fi pàdánù ohun gbogbo, tí mo fi kà wọ́n sí ìgbẹ́, kí n lè jèrè Jesu. Ati pé kí á lè rí i pé mo wà ninu Jesu ati pé n kò ní òdodo ti ara mi nípa iṣẹ́ Òfin bíkòṣe òdodo nípa igbagbọ. Gbogbo àníyàn ọkàn mi ni pé kí n mọ Kristi ati agbára ajinde rẹ̀, kí èmi náà jẹ ninu irú ìyà tí ó jẹ, kí n sì dàbí rẹ̀ nípa ikú rẹ̀, bí ó bá ṣeéṣe kí n lè dé ipò ajinde ninu òkú. Kì í ṣe pé ọwọ́ mi ti bà á ná, tabi pé mo ti di pípé. Ṣugbọn mò ń lépa ohun tí Kristi ti yàn mí fún. Ẹ̀yin ará, èmi gan-an kò ka ara mi sí ẹni tí ó ti dé ibi tí mò ń lọ. Ṣugbọn nǹkankan ni, èmi a máa gbàgbé ohun gbogbo tí ó ti kọjá, èmi a sì máa nàgà láti mú ohun tí ó wà níwájú. Mò ń làkàkà láti dé òpin iré-ìje mi tíí ṣe èrè ìpè láti òkè wá: ìpè Ọlọrun ninu Kristi Jesu. Nítorí náà, gbogbo àwa tí a ti dàgbà ninu ẹ̀sìn kí á máa ní irú èrò yìí. Bí ẹnikẹ́ni bá wá ní èrò tí ó yàtọ̀ sí èyí, Ọlọrun yóo fihàn yín. Ṣugbọn bí a ti ń ṣe bọ̀ nípa ìwà ati ìṣe, bẹ́ẹ̀ ni kí á ṣe máa tẹ̀síwájú.
Filp 3:7-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó ti jásí èrè fún mi, àwọn ni mo ti kà sí òfo nítorí Kristi. Nítòótọ́ láìṣe àní àní mo sì ka ohun gbogbo sí òfo nítorí ìtayọ ìmọ̀ Kristi Jesu Olúwa mi; nítorí ẹni ti mo ti ṣòfò ohun gbogbo, mo si kà wọn sí ohun tí kò ní èrè, kí èmi lè jèrè Kristi, Kí a sì lè bá mi nínú rẹ̀, láìní òdodo tí èmi tìkára mi, tí ó ti inú òfin wá, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti inú ìgbàgbọ́ wá nínú Kristi, òdodo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìgbàgbọ́; Èmi mọ̀ ọ́n, àti agbára àjíǹde rẹ̀, àti láti jẹ́ alábápín nínú ìyà rẹ̀ nígbà tí mo bá fi ara mọ́ ọn nínú ikú rẹ̀; nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀ kí èmi lè ní àjíǹde kúrò nínú òkú. Kì í ṣe pé ọwọ́ mi ti tẹ̀ ẹ́ ná, tàbí mo ti di pípé: ṣùgbọ́n èmi ń lépa sí i, bí ọwọ́ mi yóò lè tẹ èrè náà nítorí èyí tí a ti dì mímú pẹ̀lú, láti ọ̀dọ̀ Kristi Jesu wá. Ará, èmi kò kara mi sí ẹni ti ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ́ ná: Ṣùgbọ́n ohun kan yìí ni èmi ń ṣe, èmi ń gbàgbé àwọn nǹkan tí ó ti kọjá. Lẹ́yìn náà mo ń nàgà wo àwọn nǹkan tí ó wà níwájú. Èmi ń lépa láti dé òpin eré ìje náà fún èrè ìpè gíga Ọlọ́run nínú Kristi Jesu. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí àwa tí a dàgbà nípa ti ẹ̀mí ni èrò yìí; bí ẹ̀yin bá sì ní èrò mìíràn nínú ohunkóhun, èyí náà pẹ̀lú ni Ọlọ́run yóò fihàn yín. Kìkì pé, ki a ma gbe ìgbé ayé gẹ́gẹ́ bi èyí ti a ri gba.