Filp 3:4-6
Filp 3:4-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi emi tikarami tilẹ ni igbẹkẹle ninu ara. Bi ẹnikẹni ba rò pe on ni igbẹkẹle ninu ara, temi tilẹ ju: Ẹniti a kọ nilà ni ijọ kẹjọ, lati inu kukuté Israeli wá, lati inu ẹ̀ya Benjamini, Heberu lati inu Heberu wá; niti ofin, Farisi li emi; Niti itara, emi nṣe inunibini si ijọ; niti ododo ti o wà ninu ofin, mo jẹ alailẹgan.
Filp 3:4-6 Yoruba Bible (YCE)
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti gbára lé nǹkan ti ara nígbà kan rí. Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ní ìdí láti fi gbára lé nǹkan ti ara, mo ní i ju ẹnikẹ́ni lọ. Ní ọjọ́ kẹjọ ni wọ́n kọ mí nílà. Ọmọ Israẹli ni mí, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, Heberu paraku ni mí. Nípa ti Òfin Mose, Farisi ni mí. Ní ti ìtara ninu ẹ̀sìn, mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Kristi. Ní ti òdodo nípa iṣẹ́ Òfin, n kò kùnà níbìkan.
Filp 3:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí èmi tìkára mi pẹ̀lú ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara. Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ni ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara, tèmi tilẹ̀ pọ̀: Ẹni tí a kọ nílà ní ọjọ́ kẹjọ, láti inú kùkùté Israẹli wá, láti inú ẹ̀yà Benjamini, Heberu láti inú Heberu wá; nítorí, ní ti òfin Farisi ni èmi; Ní ti ìtara, èmi ń ṣe inúnibíni sí ìjọ; ní ti òdodo tí ó wà nínú òfin, mo jẹ́ aláìlẹ́gàn.