Filp 3:20-21
Filp 3:20-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí ìlú ìbílẹ̀ wá ń bẹ̀ ní ọ̀run: láti ibi ti àwa pẹ̀lú gbé ń fojúsọ́nà fún Olùgbàlà, Jesu Kristi Olúwa. Ẹni tí yóò sọ ara ìrẹ̀lẹ̀ wa di ọ̀tún kí ó lè bá ara ògo rẹ̀ mu, nípa agbára tí ó mú kí ó ṣe é ṣe fún un láti tẹ orí ohun gbogbo bá fún ara rẹ̀.
Filp 3:20-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori ilu-ibilẹ wa mbẹ li ọrun: lati ibiti awa pẹlu gbé nfojusọna fun Olugbala, Jesu Kristi Oluwa: Ẹniti yio sọ ara irẹlẹ wa di ọ̀tun ki o le bá ara ogo rẹ̀ mu, gẹgẹ bi iṣẹ-agbara nipasẹ eyiti on le fi tẹ ori ohun gbogbo ba fun ara rẹ̀.
Filp 3:20-21 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí pé ní tiwa, ọ̀run ni ìlú wa wà, níbi tí a ti ń retí Olùgbàlà, Oluwa Jesu Kristi, ẹni tí yóo tún ara ìrẹ̀lẹ̀ wa ṣe kí ó lè dàbí ara tirẹ̀ tí ó lógo, gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ tí ó fi lè fi ohun gbogbo sí ìkáwọ́ ara rẹ̀.