Filp 3:18-21
Filp 3:18-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
(Nitori ọ̀pọlọpọ ni nrìn, nipasẹ awọn ẹniti mo ti nwi fun nyin nigbakugba, ani, ti mo si nsọkun bi mo ti nwi fun nyin nisisiyi, pe, ọtá agbelebu Kristi ni nwọn: Igbẹhin ẹniti iṣe iparun, ikùn ẹniti iṣe ọlọrun wọn, ati ogo ẹniti o wà ninu itiju wọn, awọn ẹniti ntọju ohun aiye.) Nitori ilu-ibilẹ wa mbẹ li ọrun: lati ibiti awa pẹlu gbé nfojusọna fun Olugbala, Jesu Kristi Oluwa: Ẹniti yio sọ ara irẹlẹ wa di ọ̀tun ki o le bá ara ogo rẹ̀ mu, gẹgẹ bi iṣẹ-agbara nipasẹ eyiti on le fi tẹ ori ohun gbogbo ba fun ara rẹ̀.
Filp 3:18-21 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí ọpọlọpọ ń hùwà bí ọ̀tá agbelebu Kristi. Bí mo ti ń sọ fun yín tẹ́lẹ̀ nígbàkúùgbà, bẹ́ẹ̀ ni mo tún ń fi omijé sọ nisinsinyii. Ìparun ni ìgbẹ̀yìn wọn. Ikùn wọn ni ọlọrun wọn. Ohun ìtìjú ni wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga. Afẹ́-ayé ni wọ́n gbé lékàn. Nítorí pé ní tiwa, ọ̀run ni ìlú wa wà, níbi tí a ti ń retí Olùgbàlà, Oluwa Jesu Kristi, ẹni tí yóo tún ara ìrẹ̀lẹ̀ wa ṣe kí ó lè dàbí ara tirẹ̀ tí ó lógo, gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ tí ó fi lè fi ohun gbogbo sí ìkáwọ́ ara rẹ̀.
Filp 3:18-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ń rìn, nípasẹ̀ àwọn ẹni tí mo ti ń wí fún yín nígbàkúgbà, àní, tí mo sì ń sọkún bí mo ti ń wí fún yín nísinsin yìí, pé, ọ̀tá àgbélébùú Kristi ni wọ́n: Ìgbẹ̀yìn wọn ni ìparun, ikùn wọn sì ni Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń ṣògo nínú ìtìjú wọn, àwọn ẹni tí ń tọ́jú ohun ti ayé. Nítorí ìlú ìbílẹ̀ wá ń bẹ̀ ní ọ̀run: láti ibi ti àwa pẹ̀lú gbé ń fojúsọ́nà fún Olùgbàlà, Jesu Kristi Olúwa. Ẹni tí yóò sọ ara ìrẹ̀lẹ̀ wa di ọ̀tún kí ó lè bá ara ògo rẹ̀ mu, nípa agbára tí ó mú kí ó ṣe é ṣe fún un láti tẹ orí ohun gbogbo bá fún ara rẹ̀.