Filp 3:17-19
Filp 3:17-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ará, ẹ jumọ ṣe afarawe mi, ẹ si ṣe akiyesi awọn ti nrìn bẹ̃, ani bi ẹ ti ni wa fun apẹrẹ. (Nitori ọ̀pọlọpọ ni nrìn, nipasẹ awọn ẹniti mo ti nwi fun nyin nigbakugba, ani, ti mo si nsọkun bi mo ti nwi fun nyin nisisiyi, pe, ọtá agbelebu Kristi ni nwọn: Igbẹhin ẹniti iṣe iparun, ikùn ẹniti iṣe ọlọrun wọn, ati ogo ẹniti o wà ninu itiju wọn, awọn ẹniti ntọju ohun aiye.)
Filp 3:17-19 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ará, gbogbo yín ẹ máa fara wé mi, kí ẹ máa ṣàkíyèsí àwọn tí ń hùwà gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí a ti jẹ́ fun yín. Nítorí ọpọlọpọ ń hùwà bí ọ̀tá agbelebu Kristi. Bí mo ti ń sọ fun yín tẹ́lẹ̀ nígbàkúùgbà, bẹ́ẹ̀ ni mo tún ń fi omijé sọ nisinsinyii. Ìparun ni ìgbẹ̀yìn wọn. Ikùn wọn ni ọlọrun wọn. Ohun ìtìjú ni wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga. Afẹ́-ayé ni wọ́n gbé lékàn.
Filp 3:17-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ará, ẹ jùmọ̀ ṣe àfarawé mi, ẹ ṣe àkíyèsí àwọn tí ń rìn bẹ́ẹ̀, àní bí ẹ ti ní wa fún àpẹẹrẹ. Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ń rìn, nípasẹ̀ àwọn ẹni tí mo ti ń wí fún yín nígbàkúgbà, àní, tí mo sì ń sọkún bí mo ti ń wí fún yín nísinsin yìí, pé, ọ̀tá àgbélébùú Kristi ni wọ́n: Ìgbẹ̀yìn wọn ni ìparun, ikùn wọn sì ni Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń ṣògo nínú ìtìjú wọn, àwọn ẹni tí ń tọ́jú ohun ti ayé.