Filp 2:9-18

Filp 2:9-18 Yoruba Bible (YCE)

Nítorí náà ni Ọlọrun ṣe gbé e ga ju ẹnikẹ́ni lọ; ó sì fún un ní orúkọ tí ó ga ju gbogbo orúkọ yòókù lọ, pé ní orúkọ Jesu ni gbogbo ẹ̀dá yóo máa wólẹ̀, lọ́run ati láyé, ati nísàlẹ̀ ilẹ̀; gbogbo ẹ̀dá yóo sì máa jẹ́wọ́ pé, “Jesu Kristi ni Oluwa,” fún ògo Ọlọrun Baba. Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń gbọ́ràn nígbà gbogbo, tí kì í ṣe nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín nìkan, ṣugbọn pàápàá jùlọ ní àkókò yìí tí n kò sí lọ́dọ̀ yín, ẹ máa ṣe iṣẹ́ ìgbàlà yín pẹlu ìbẹ̀rù ati ìwárìrì. Nítorí pé Ọlọrun ní ń fun yín ní agbára, láti fẹ́ ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ati láti lè ṣe ohun tí ó wù ú. Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú tabi iyàn jíjà, kí ẹ lè jẹ́ Ọmọ Ọlọrun, tí kò lẹ́bi tí kò sì ní àléébù, ọmọ Ọlọrun tí ó pé, láàrin àwọn ìran tí ọ̀nà wọn wọ́, tí ìwà wọn sì ti bàjẹ́. Láàrin irú àwọn eniyan wọnyi ni ẹ̀ ń tàn bí ìmọ́lẹ̀ ninu ayé, tí ẹ sì ń polongo ọ̀rọ̀ ìyè. Èyí ni yóo jẹ́ ìṣògo fún mi ní ọjọ́ tí Kristi bá dé, nítorí yóo hàn pé iré-ìje tí mò ń sá kì í ṣe lásán, ati pé aápọn tí mo ti ṣe kò já sí òfo. Ṣugbọn bí a bá fi mí ṣe ohun ìrúbọ ati ohun èèlò ninu ìsìn nítorí igbagbọ yín, ó dùn mọ́ mi, n óo sì máa yọ̀ pẹlu gbogbo yín. Nítorí náà, kí inú yín kí ó máa dùn, kí ẹ sì máa bá mi yọ̀.

Filp 2:9-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí náà, Ọlọ́run ti gbé e ga sí ipele tí ó ga jùlọ, ó sì ti fi orúkọ kan ti ó borí gbogbo orúkọ fún un Pé ni orúkọ Jesu ni kí gbogbo eékún máa wólẹ̀, ní ọ̀run, àti ní orí ilẹ̀ ayé àti ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé, Àti pé kí gbogbo ahọ́n jẹ́wọ́ pé, Jesu Kristi ni Olúwa, fún ògo Ọlọ́run Baba. Nítorí náà ẹ̀yin ará mi, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti ń gbọ́rọ̀ nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà ti mo wà lọ́dọ̀ yín nìkan, ṣùgbọ́n pàápàá nísinsin yìí tí èmi kò sí ni àárín yín, ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì, Nítorí pé Ọlọ́run ni ó n ṣiṣẹ́ nínú yín, láti fẹ́ àti láti ṣiṣẹ́ fún ète rere rẹ̀. Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú àti ìjiyàn. Kí ẹ̀yin lè jẹ́ aláìlẹ́gàn àti oníwà mímọ́, ọmọ Ọlọ́run, aláìlábàwọ́n, láàrín oníwà wíwọ́ àti alárékérekè orílẹ̀-èdè láàrín àwọn ẹni tí a ń rí yín bí ìmọ́lẹ̀ ní ayé. Bí ẹ sì ṣe di ọ̀rọ̀ ìyè mú gírígírí, kí èmi lè ṣògo ni ọjọ́ Kristi pé èmi kò sáré lásán, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì ṣe làálàá lásán. Ṣùgbọ́n, bí a tilẹ̀ ń dà mí bí ọtí-ìrúbọ sórí ẹbọ iṣẹ́ ìsìn ìgbàgbọ́ yín, inú mi dùn, mo sì ń bá gbogbo yín yọ̀ pẹ̀lú. Bákan náà ni kí ẹ̀yin máa yọ̀, kí ẹ sì máa bá mi yọ̀ pẹ̀lú.