Filp 1:7-8
Filp 1:7-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gẹgẹ bi o ti tọ́ fun mi lati rò eyi fun gbogbo nyin, nitoriti ọkàn nyin wà lọdọ mi, niwọn bi o ti ṣepe gbogbo nyin ni iṣe alabapin ore-ọfẹ pẹlu mi ninu idè mi ati ninu idahùn-ẹjọ mi ati ifẹsẹmulẹ ihinrere. Nitori Ọlọrun li ẹlẹri mi, bi mo ti nṣafẹri nyin to gidigidi ninu iyọ́nu Jesu Kristi.

Filp 1:7-8 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀tọ́ ni fún mi láti ní irú èrò yìí nípa gbogbo yín, nítorí mo kó ọ̀rọ̀ yín lékàn. Nítorí pé nígbà tí mo wà ninu ẹ̀wọ̀n ati ìgbà tí mo ní anfaani láti gbèjà ara mi ati láti fi ìdí ọ̀rọ̀ ìyìn rere múlẹ̀, gbogbo yín ni ẹ jẹ́ alájọpín oore-ọ̀fẹ́ Kristi pẹlu mi. Mo fi Ọlọrun ṣe ẹ̀rí pé àárò gbogbo yín ń sọ mí, pẹlu ọkàn ìyọ́nú ti Kristi Jesu.
Filp 1:7-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi láti ro èyí nípa gbogbo yín, nítorí tí mo fi yín sọ́kàn, bí mo tilẹ̀ wà nínú ìdè tàbí ìdáhùn ẹjọ́, àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ìhìnrere, gbogbo yín jẹ́ alábápín oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú mi. Nítorí Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí mi, bí mo ti ń ṣàfẹ́rí yín gidigidi nínú ìfẹ́ Jesu Kristi.