Filp 1:27-30
Filp 1:27-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kìki ki ẹ sá jẹ ki ìwa-aiye nyin ki o mã ri gẹgẹ bi ihinrere Kristi: pe yala bi mo tilẹ wá wò nyin, tabi bi emi kò si, ki emi ki o le mã gburó bi ẹ ti nṣe, pe ẹnyin duro ṣinṣin ninu Ẹmí kan, ẹnyin jùmọ njijakadi nitori igbagbọ́ ihinrere, pẹlu ọkàn kan; Ki ẹ má si jẹ ki awọn ọta dẹruba nyin li ohunkohun: eyiti iṣe àmi ti o daju fun iparun wọn, ṣugbọn ti igbala nyin, ati eyini ni lati ọwọ́ Ọlọrun wá. Nitori niti Kristi, ẹnyin li a ti yọnda fun, kì iṣe lati gbà a gbọ́ nikan, ṣugbọn lati jìya nitori rẹ̀ pẹlu: Ẹ si ni ìja kanna ti ẹnyin ti ri ninu mi, ti ẹnyin si gbọ́ nisisiyi pe o wà ninu mi.
Filp 1:27-30 Yoruba Bible (YCE)
Nǹkankan tí ó ṣe pataki ni pé kí ẹ jẹ́ kí ìwà yín kí ó jẹ́ irú èyí tí ó bá ìyìn rere Kristi mu, tí ó jẹ́ pé bí mo bá wá tí mo ri yín, tabi bí n kò bá lè wá ṣugbọn tí mò ń gbúròó yín, kí n gbọ́ pé ẹ wà pọ̀ ninu ẹ̀mí kan ati ọkàn kan, ati pé gbogbo yín ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹlu igbagbọ ninu iṣẹ́ ìyìn rere. Ẹ má jẹ́ kí ẹ̀rù àwọn alátakò bà yín rárá ninu ohunkohun. Èyí ni yóo jẹ́ ẹ̀rí ìparun wọn, yóo sì jẹ́ ẹ̀rí ìgbàlà yín. Ọlọrun ni yóo ṣe é. Nítorí anfaani ni èyí fun yín, kì í ṣe pé kí ẹ gba Kristi gbọ́ nìkan ni, ṣugbọn pé ẹ̀ ń jìyà fún Kristi. Irú ìyà kan náà tí ẹ rí ninu ìgbé-ayé mi, tí ẹ tún ń gbọ́ pé mò ń jẹ títí di àkókò yìí ni ẹ̀yin náà ń jẹ báyìí.
Filp 1:27-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ohun yówù kó ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ kí ìgbé ayé yín ri gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere Kristi: pé yálà bi mo tilẹ̀ wá wò yín, tàbí bí èmi kò wá, kí èmi kí ó lè máa gbúròó bí ẹ ti ń ṣe, pé ẹ̀yin dúró ṣinṣin nínú Ẹ̀mí kan, ẹ̀yin jùmọ̀ jìjàkadì nítorí ìgbàgbọ́ ìhìnrere, pẹ̀lú ọkàn kan; Kí ẹ má sì jẹ́ ki àwọn ọ̀tá dẹ́rùbà yin ni ohunkóhun: èyí tí í ṣe ààmì tí ó dájú pé a ó pa wọ́n run, ṣùgbọ́n Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ni yóò gbà yin là. Nítorí tí a ti fún yin ni àǹfààní, kì í ṣe láti gba Kristi gbọ́ nìkan, ṣùgbọ́n láti jìyà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú: Ẹ sì máa ja ìjà kan náà, èyí ti ẹ̀yin ti ri, ti ẹ sì ti gbọ́ pé èmi n jà pẹ̀lú.