Filp 1:20-22
Filp 1:20-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gẹgẹ bi ìnàgà ati ireti mi pe ki oju ki o máṣe tì mi li ohunkohun, ṣugbọn pẹlu igboiya gbogbo, bi nigbagbogbo, bẹ̃ nisisiyi pẹlu a o gbé Kristi ga lara mi, ibã ṣe nipa ìye, tabi nipa ikú. Nitori, niti emi, lati wà lãye jẹ Kristi, lati kú jẹ ere. Ṣugbọn bi lati wà lãye ninu ara ba jẹ eso iṣẹ mi, nigbana ohun ti emi o yàn, emi kò mọ.
Filp 1:20-22 Yoruba Bible (YCE)
gẹ́gẹ́ bí igbẹkẹle ati ìrètí mi pé n kò ní rí ohun ìtìjú kan. Ṣugbọn bí mo ti máa ń gbé Kristi ga ninu ara mi pẹlu ìgboyà nígbà gbogbo, bẹ́ẹ̀ gan-an náà ni n óo tún máa gbé e ga nisinsinyii ìbáà jẹ́ pé mo wà láàyè tabi pé mo kú. Nítorí pé Kristi ni mo wà láàyè fún ní tèmi, bí mo bá sì kú, èrè ni ó jẹ́. Bí mo bá wà láàyè ninu ẹran-ara, iṣẹ́ tí ó lérè ni ó jẹ́ fún mi. N kò tilẹ̀ mọ èyí tí ǹ bá yàn.
Filp 1:20-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn àti ìrètí mi pé kí ojú kí ó má ṣe ti mi ní ohunkóhun, ṣùgbọ́n kí èmi kí ó le máa ni ìgboyà ní ìgbà gbogbo àti nísinsin yìí, kí a lè ti ipasẹ̀ mi gbé Kristi ga lára mi, ìbá à ṣe pé mo wà láààyè, tàbí mo kú. Nítorí, ní ti èmi, láti wa láààyè jẹ́ Kristi, láti kú pẹ̀lú sì jẹ́ èrè fún mi. Ṣùgbọ́n bí èmi bá le è ṣe iṣẹ́ ti ó ni àpẹẹrẹ nípa wíwà láààyè nínú ara, ṣùgbọ́n ohun ti èmi ó yàn, èmi kò mọ̀.