Filp 1:15-18
Filp 1:15-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitotọ awọn ẹlomiran tilẹ nfi ija ati ilara wasu Kristi; awọn ẹlomiran si nfi inu rere ṣe e. Awọn kan nfi ìja wasu Kristi, kì iṣe pẹlu õtọ inu, nwọn ngbèro lati fi ipọnju kún ìde mi: Awọn kan ẹwẹ si nfi ifẹ ṣe e, nitoriti nwọn mọ̀ pe a gbe mi dide fun idahun-ẹjọ ihinrere. Njẹ kini? bikoṣepe nibi gbogbo, iba ṣe niti àfẹ̀tànṣe tabi niti otitọ, a sa nwasu Kristi; emi si nyọ̀ nitorina, nitõtọ, emi ó si ma yọ̀.
Filp 1:15-18 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ẹlòmíràn ń waasu Kristi nítorí owú ati nítorí pé wọ́n fẹ́ràn asọ̀. Àwọn ẹlòmíràn sì wà tí wọn ń waasu Kristi pẹlu inú rere. Àwọn kan ń fi ìfẹ́ waasu Kristi nítorí wọ́n mọ̀ pé nítorí ti ọ̀rọ̀ ìyìn rere ni wọ́n ṣe sọ mí sẹ́wọ̀n. Àwọn kan ń sọ̀rọ̀ Kristi nítorí ohun tí wọn óo rí gbà níbẹ̀, kì í ṣe pẹlu inú kan, wọ́n rò pé àwọn lè mú kí ìrora mi ninu ẹ̀wọ̀n pọ̀ sí i. Kí ni àyọrísí gbogbo èyí? Lọ́nà kan tabi lọ́nà mìíràn, ìbáà ṣe pẹlu ẹ̀tàn ni, tabi pẹlu òtítọ́ inú, a sá ń waasu Kristi, èyí ni ó mú inú mi dùn. Inú mi yóo sì máa dùn ni
Filp 1:15-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Òtítọ́ ni pé àwọn ẹlòmíràn tilẹ̀ ń fi ìjà àti ìlara wàásù Kristi, ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn sì ń fi inú rere ṣe é. Àwọn kan ń fi ìjà wàásù Kristi, kì í ṣe pẹ̀lú òtítọ́ inú, wọ́n ń gbèrò láti fi ìpọ́njú kún ìdè mi: Àwọn kan ẹ̀wẹ̀ si ń fi ìfẹ́ ṣe é, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé a gbé mi dìde láti dá ààbò bo iṣẹ́ ìhìnrere. Kí ló tún kù? Kìkì í pé níbi gbogbo, ìbá à ní ìfẹ̀tànṣe tàbí ni ti òtítọ́ a sá à n wàásù Kristi, èmi sì ń yọ̀ nítorí èyí. Nítòótọ́, èmi ó sì máa yọ̀