Filp 1:1-11
Filp 1:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
PAULU ati Timotiu, awọn iranṣẹ Jesu Kristi, si gbogbo awọn enia mimọ́ ninu Kristi Jesu ti o wà ni Filippi, pẹlu awọn biṣopu ati awọn diakoni: Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Oluwa Jesu Kristi. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun mi fun gbogbo iranti nyin ti mo nṣe, Nigbagbogbo ninu gbogbo adura mi fun nyin li emi nfi ayọ̀ bẹ̀bẹ, Nitori ìdapọ nyin ninu ihinrere lati ọjọ kini wá titi fi di isisiyi. Ohun kan yi sa da mi loju, pe ẹniti o ti bẹ̀rẹ iṣẹ rere ninu nyin, yio ṣe aṣepe rẹ̀ titi fi di ọjọ Jesu Kristi: Gẹgẹ bi o ti tọ́ fun mi lati rò eyi fun gbogbo nyin, nitoriti ọkàn nyin wà lọdọ mi, niwọn bi o ti ṣepe gbogbo nyin ni iṣe alabapin ore-ọfẹ pẹlu mi ninu idè mi ati ninu idahùn-ẹjọ mi ati ifẹsẹmulẹ ihinrere. Nitori Ọlọrun li ẹlẹri mi, bi mo ti nṣafẹri nyin to gidigidi ninu iyọ́nu Jesu Kristi. Eyi si ni mo ngbadura fun pe, ki ifẹ nyin ki o le mã pọ si i siwaju ati siwaju ninu imọ̀ ati imoye gbogbo. Ki ẹnyin ki o le dán ohun ti o yàtọ wò; ki ẹ si jasi olododo ati alaijẹ-ohun-ikọsẹ titi fi di ọjọ Jesu Kristi; Lẹhin igbati ẹ ti kun fun eso ododo lati ọdọ Jesu Kristi, fun ogo ati iyìn Ọlọrun.
Filp 1:1-11 Yoruba Bible (YCE)
Èmi Paulu ati Timoti, àwa iranṣẹ Kristi Jesu. À ń kọ ìwé yìí sí gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun tí ó wà ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu, tí wọ́n wà ní Filipi pẹlu gbogbo àwọn alabojuto ati àwọn olùrànlọ́wọ́ wọn. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa wa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu yín. Nígbà gbogbo tí mo bá ranti yín ni mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun mi. Nígbà gbogbo ni mò ń gbadura fún gbogbo yín pẹlu ayọ̀ ninu ọkàn mi. Nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ títí di àkókò yìí ni ẹ ti ń bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀ ninu iṣẹ́ ìyìn rere. Ó dá mi lójú pé ẹni tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere ninu yín yóo ṣe é dé òpin títí di ọjọ́ tí Kristi Jesu yóo dé. Ẹ̀tọ́ ni fún mi láti ní irú èrò yìí nípa gbogbo yín, nítorí mo kó ọ̀rọ̀ yín lékàn. Nítorí pé nígbà tí mo wà ninu ẹ̀wọ̀n ati ìgbà tí mo ní anfaani láti gbèjà ara mi ati láti fi ìdí ọ̀rọ̀ ìyìn rere múlẹ̀, gbogbo yín ni ẹ jẹ́ alájọpín oore-ọ̀fẹ́ Kristi pẹlu mi. Mo fi Ọlọrun ṣe ẹ̀rí pé àárò gbogbo yín ń sọ mí, pẹlu ọkàn ìyọ́nú ti Kristi Jesu. Adura mi ni pé kí ìfẹ́ yín máa gbòòrò sí i, kí ìmọ̀ yín máa pọ̀ sí i, kí ẹ túbọ̀ máa ní làákàyè sí i, kí ẹ lè mọ àwọn ohun tí ó dára jùlọ. Kí ẹ lè jẹ́ aláìlábùkù, kí ẹ sì wà láìsí ohun ìkùnà kan ní ọjọ́ tí Kristi bá dé. Mo tún gbadura pé kí ẹ lè kún fún èso iṣẹ́ òdodo tí ó ti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi wá fún ògo ati ìyìn Ọlọrun.
Filp 1:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Paulu àti Timotiu, àwọn ìránṣẹ́ Jesu Kristi. Sí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ nínú Kristi Jesu tí ó wà ní Filipi, pẹ̀lú àwọn alábojútó àti àwọn díákónì. Oore-ọ̀fẹ́ sí yín, àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Olúwa wa Jesu Kristi. Mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí yín: Nínú gbogbo àdúrà mi fún un yín, èmi ń fi ayọ̀ gbàdúrà, nítorí ìdàpọ̀ yín nínú ìhìnrere láti ọjọ́ kìn-ín-ní wá títí di ìsinsin yìí. Ohun kan yìí sá à dá mi lójú pé, ẹni tí ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere nínú yín, yóò ṣe àṣepé rẹ̀ títí di ọjọ́ náà tí Jesu Kristi yóò dé: Gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi láti ro èyí nípa gbogbo yín, nítorí tí mo fi yín sọ́kàn, bí mo tilẹ̀ wà nínú ìdè tàbí ìdáhùn ẹjọ́, àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ìhìnrere, gbogbo yín jẹ́ alábápín oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú mi. Nítorí Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí mi, bí mo ti ń ṣàfẹ́rí yín gidigidi nínú ìfẹ́ Jesu Kristi. Èyí sì ni àdúrà mi: pé kí ìfẹ́ yín lè máa pọ̀ síwájú àti síwájú sí i nínú ìfẹ́ àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó lè ní òye ohun tí ó dára jùlọ; kí ó sì jásí òdodo àti aláìjẹ́ ohun ìkọ̀sẹ̀ títí di ọjọ́ dídé Jesu Kristi: Lẹ́yìn ìgbà ti ẹ ti kún fún àwọn ìwà òdodo láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, fún ògo àti ìyìn Ọlọ́run.