File 1:4-16

File 1:4-16 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà gbogbo tí mo bá ń ranti rẹ ninu adura ni mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun. Mò ń gbọ́ ìròyìn ìfẹ́ ati igbagbọ tí o ní sí Oluwa Jesu, ati sí gbogbo àwọn onigbagbọ. Adura mi ni pé kí àjọṣepọ̀ tàwa-tìrẹ ninu igbagbọ lè ṣiṣẹ́, láti mú kí òye rẹ pọ̀ sí i nípa gbogbo ohun rere tí a ní ninu Kristi. Nítorí mo láyọ̀ pupọ, mo sì ní ìwúrí lọpọlọpọ nípa ìfẹ́ rẹ. Nítorí ohun tí ò ń ṣe ti tu àwọn onigbagbọ lára, arakunrin mi. Nítorí náà, bí mo tilẹ̀ ní ìgboyà pupọ ninu Kristi láti pàṣẹ ohun tí ó yẹ fún ọ, ṣugbọn nítorí ìfẹ́ tí ó wà láàrin wa, ẹ̀bẹ̀ ni n óo kúkú bẹ̀. Èmi Paulu, ikọ̀ Kristi, tí mo di ẹlẹ́wọ̀n nisinsinyii nítorí ti Kristi Jesu, mò ń bẹ̀ ọ́ nítorí ti ọmọ mi, Onisimu, ọmọ tí mo bí ninu ẹ̀wọ̀n. Nígbà kan rí kò wúlò fún ọ. Ṣugbọn nisinsinyii ó wúlò fún ọ ati fún mi. Òun ni mò ń rán pada sí ọ. Ó wá dàbí ẹni pé mò ń fi ọkàn èmi pàápàá ranṣẹ sí ọ. Ǹ bá dá a dúró, kó máa wà lọ́dọ̀ mi, kí ó lè máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi dípò rẹ lákòókò tí mo wà ninu ẹ̀wọ̀n nítorí iṣẹ́ ìyìn rere. Ṣugbọn n kò fẹ́ dá nǹkankan ṣe láìjẹ́ pé o lọ́wọ́ sí i, n kò fẹ́ kí ó jẹ́ pé túlààsì ni oore tí mo fẹ́ kí o ṣe. Inú rẹ ni mo fẹ́ kí ó ti wá. Bóyá ìdí nìyí tí ó fi sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ fún ìgbà díẹ̀, kí o lè jèrè rẹ̀ ní gbogbo ìgbà; kì í tún ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú mọ́, ṣugbọn ní ipò tí ó ga ju ti ẹrú lọ, bí àyànfẹ́ arakunrin, tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi, ṣugbọn tí ó ṣọ̀wọ́n fún ọ jù mí lọ, gẹ́gẹ́ bí eniyan sí eniyan ati gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ.

File 1:4-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Èmi máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà tí mo bá rántí rẹ nínú àdúrà mi, nítorí mo ń gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ rẹ nínú Jesu Olúwa àti nípa ìfẹ́ rẹ sí àwọn ènìyàn mímọ́. Èmi ń gbàdúrà pé, bí ìwọ ti ń ṣe alábápín nínú ìgbàgbọ́ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, pé kí ìgbàgbọ́ náà lè mú ọkàn wọn dúró gbọingbọin, gẹ́gẹ́ bí wọn ti rí àwọn ọ̀rọ̀ ohun rere tí ó ń bẹ nínú ayé rẹ, èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Kristi wá. Ìfẹ́ rẹ ti fún mi ní ayọ̀ púpọ̀ àti ìgboyà, nítorí ìwọ, arákùnrin ti tu ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ lára. Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú Kristi mo ní ìgboyà púpọ̀ láti pàṣẹ ohun ti ó yẹ kí ó ṣe fún ọ, Síbẹ̀ nítorí ìfẹ́ èmí kúkú bẹ̀ ọ́. Èmi gẹ́gẹ́ bí Paulu, arúgbó, àti nísinsin yìí òǹdè Jesu Kristi. Èmí bẹ̀ ọ́ nítorí ọmọ mi Onesimu, ẹni tí ó di ọmọ nígbà tí mo wà nínú ìdè. Nígbà kan rí, kò wúlò fún ọ, ṣùgbọ́n ní báyìí, ó ti wúlò fún ọ àti fún èmi pàápàá. Èmi rán an nísinsin yìí, àní ẹni ọkàn mi padà sí ọ̀dọ̀ rẹ. Èmi ìbá fẹ́ láti dá a dúró sọ́dọ̀ mi níhìn-ín, kí ó ba à dípò rẹ láti máa ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí mo wà nínú ìdè nítorí ìhìnrere ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ rárá láìgba ìyọ̀ǹda ní ọwọ́ rẹ, kí oore tí ìwọ bá ṣe má ba à jẹ́ ìfipámúniṣe bí kò ṣe ìfìfẹ́ṣe. Bóyá ìdí rẹ̀ tí òun fi yẹra kúrò lọ́dọ̀ rẹ fún ìgbà díẹ̀ ni pé kí ìwọ kí ó lè gbà á padà sọ́dọ̀ títí láé; Kì í wá ṣe bí ẹrú mọ́, ṣùgbọ́n bí ẹni ti ó sàn ju ẹrú lọ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin. Ó ṣọ̀wọ́n fún mi jọjọ, ṣùgbọ́n ó ṣọ̀wọ́n fún ọ jù nípa ti ara àti gẹ́gẹ́ bí arákùnrin nínú Olúwa.