File 1:15-16
File 1:15-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori boya idi rẹ̀ li eyi ti o fi kuro lọdọ rẹ fun igba diẹ, ki iwọ ki o ba le ni i titi lai; Kì iṣe bi ẹrú mọ, ṣugbọn o jù ẹrú lọ, arakunrin olufẹ, papa fun mi, melomelo jubẹ̃lọ fun ọ, nipa ti ara ati nipa ti Oluwa.
File 1:15-16 Yoruba Bible (YCE)
Bóyá ìdí nìyí tí ó fi sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ fún ìgbà díẹ̀, kí o lè jèrè rẹ̀ ní gbogbo ìgbà; kì í tún ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú mọ́, ṣugbọn ní ipò tí ó ga ju ti ẹrú lọ, bí àyànfẹ́ arakunrin, tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi, ṣugbọn tí ó ṣọ̀wọ́n fún ọ jù mí lọ, gẹ́gẹ́ bí eniyan sí eniyan ati gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ.
File 1:15-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bóyá ìdí rẹ̀ tí òun fi yẹra kúrò lọ́dọ̀ rẹ fún ìgbà díẹ̀ ni pé kí ìwọ kí ó lè gbà á padà sọ́dọ̀ títí láé; Kì í wá ṣe bí ẹrú mọ́, ṣùgbọ́n bí ẹni ti ó sàn ju ẹrú lọ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin. Ó ṣọ̀wọ́n fún mi jọjọ, ṣùgbọ́n ó ṣọ̀wọ́n fún ọ jù nípa ti ara àti gẹ́gẹ́ bí arákùnrin nínú Olúwa.