File 1:10-14
File 1:10-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi bẹ̀ ọ fun ọmọ mi, ti mo bí ninu ìde mi, Onesimu: Nigbakan rí ẹniti o jẹ alailere fun ọ, ṣugbọn nisisiyi o lere fun ọ ati fun mi: Ẹniti mo rán pada, ani on tikalarẹ̀, eyini ni olufẹ mi: Ẹniti emi iba fẹ daduro pẹlu mi, ki o le mã ṣe iranṣẹ fun mi nipo rẹ ninu ìde ihinrere: Ṣugbọn li aimọ̀ inu rẹ emi kò fẹ ṣe ohun kan; ki ore rẹ ki o má ba dabi afiyanjuṣe, bikoṣe tifẹtifẹ.
File 1:10-14 Yoruba Bible (YCE)
mò ń bẹ̀ ọ́ nítorí ti ọmọ mi, Onisimu, ọmọ tí mo bí ninu ẹ̀wọ̀n. Nígbà kan rí kò wúlò fún ọ. Ṣugbọn nisinsinyii ó wúlò fún ọ ati fún mi. Òun ni mò ń rán pada sí ọ. Ó wá dàbí ẹni pé mò ń fi ọkàn èmi pàápàá ranṣẹ sí ọ. Ǹ bá dá a dúró, kó máa wà lọ́dọ̀ mi, kí ó lè máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi dípò rẹ lákòókò tí mo wà ninu ẹ̀wọ̀n nítorí iṣẹ́ ìyìn rere. Ṣugbọn n kò fẹ́ dá nǹkankan ṣe láìjẹ́ pé o lọ́wọ́ sí i, n kò fẹ́ kí ó jẹ́ pé túlààsì ni oore tí mo fẹ́ kí o ṣe. Inú rẹ ni mo fẹ́ kí ó ti wá.
File 1:10-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmí bẹ̀ ọ́ nítorí ọmọ mi Onesimu, ẹni tí ó di ọmọ nígbà tí mo wà nínú ìdè. Nígbà kan rí, kò wúlò fún ọ, ṣùgbọ́n ní báyìí, ó ti wúlò fún ọ àti fún èmi pàápàá. Èmi rán an nísinsin yìí, àní ẹni ọkàn mi padà sí ọ̀dọ̀ rẹ. Èmi ìbá fẹ́ láti dá a dúró sọ́dọ̀ mi níhìn-ín, kí ó ba à dípò rẹ láti máa ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí mo wà nínú ìdè nítorí ìhìnrere ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ rárá láìgba ìyọ̀ǹda ní ọwọ́ rẹ, kí oore tí ìwọ bá ṣe má ba à jẹ́ ìfipámúniṣe bí kò ṣe ìfìfẹ́ṣe.