File 1:1-7
File 1:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
PAULU, onde Kristi Jesu, ati Timotiu arakunrin wa, si Filemoni olufẹ ati alabaṣiṣẹ wa ọwọn, Ati si Affia arabinrin wa, ati si Arkippu ọmọ-ogun ẹgbẹ wa, ati si ìjọ inu ile rẹ: Ore-ọfẹ, ati alafia sí nyin, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Jesu Kristi Oluwa. Emi ndupẹ lọwọ Ọlọrun mi nigbagbogbo, emi nṣe iranti rẹ ninu adura mi, Bi mo ti ngbọ́ ti ifẹ rẹ ati igbagbọ́ ti iwọ ni si Jesu Oluwa, ati si gbogbo awọn enia mimọ́; Ki idapọ igbagbọ́ rẹ le lagbara, ni imọ ohun rere gbogbo ti mbẹ ninu nyin si Kristi. Emi sá ni ayọ̀ pupọ ati itunu nitori ifẹ rẹ, nitoriti a tù ọkàn awọn enia mimọ́ lara lati ọwọ́ rẹ wá, arakunrin.
File 1:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Èmi Paulu, ẹlẹ́wọ̀n nítorí ti Kristi Jesu, ati Timoti, arakunrin wa, ni à ń kọ ìwé yìí sí Filemoni, àyànfẹ́ wa ati alábàáṣiṣẹ́ wa, ati sí Afia, arabinrin wa ati sí Akipu: ọmọ-ogun ẹlẹgbẹ́ wa fún Kristi, ati sí ìjọ tí ó wà ninu ilé rẹ̀. Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹlu yín ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa, ati Oluwa Jesu Kristi. Nígbà gbogbo tí mo bá ń ranti rẹ ninu adura ni mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun. Mò ń gbọ́ ìròyìn ìfẹ́ ati igbagbọ tí o ní sí Oluwa Jesu, ati sí gbogbo àwọn onigbagbọ. Adura mi ni pé kí àjọṣepọ̀ tàwa-tìrẹ ninu igbagbọ lè ṣiṣẹ́, láti mú kí òye rẹ pọ̀ sí i nípa gbogbo ohun rere tí a ní ninu Kristi. Nítorí mo láyọ̀ pupọ, mo sì ní ìwúrí lọpọlọpọ nípa ìfẹ́ rẹ. Nítorí ohun tí ò ń ṣe ti tu àwọn onigbagbọ lára, arakunrin mi.
File 1:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi Paulu, ẹni tí a fi sẹ́wọ̀n nítorí pé ó ń wàásù ìhìnrere Jesu Kristi àti Timotiu arákùnrin wa. Sí Filemoni ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n àti alábáṣiṣẹ́ wa, sí Affia arábìnrin wa, sí Arkippu ẹni tó jẹ́ jagunjagun fún àgbélébùú náà àti sí ìjọ àwọn Kristiani tí ó ń pàdé nínú ilé rẹ: Oore-Ọ̀fẹ́ fún un yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Jesu Kristi. Èmi máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà tí mo bá rántí rẹ nínú àdúrà mi, nítorí mo ń gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ rẹ nínú Jesu Olúwa àti nípa ìfẹ́ rẹ sí àwọn ènìyàn mímọ́. Èmi ń gbàdúrà pé, bí ìwọ ti ń ṣe alábápín nínú ìgbàgbọ́ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, pé kí ìgbàgbọ́ náà lè mú ọkàn wọn dúró gbọingbọin, gẹ́gẹ́ bí wọn ti rí àwọn ọ̀rọ̀ ohun rere tí ó ń bẹ nínú ayé rẹ, èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Kristi wá. Ìfẹ́ rẹ ti fún mi ní ayọ̀ púpọ̀ àti ìgboyà, nítorí ìwọ, arákùnrin ti tu ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ lára.