Oba 1:11-18
Oba 1:11-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ni ọjọ ti iwọ duro li apa keji, ni ọjọ ti awọn alejo kó awọn ogun rẹ̀ ni igbèkun lọ, ti awọn ajeji si wọ inu ibode rẹ̀, ti nwọn si ṣẹ keké lori Jerusalemu, ani iwọ wà bi ọkan ninu wọn. Ṣugbọn iwọ kì ba ti ṣiju wo ọjọ arakunrin rẹ ni ọjọ ti on di ajeji; bẹ̃ni iwọ kì ba ti yọ̀ lori awọn ọmọ Juda ni ọjọ iparun wọn; bẹ̃ni iwọ kì ba ti sọ̀rọ irera ni ọjọ wahala. Iwọ kì ba ti wọ inu ibode awọn enia mi lọ li ọjọ idãmú wọn; nitotọ, iwọ kì ba ti ṣiju wo ipọnju wọn li ọjọ idãmú wọn, bẹ̃ni iwọ kì ba ti gbe ọwọ́ le ohun ini wọn li ọ̀jọ idãmú wọn. Bẹ̃ni iwọ kì ba ti duro ni ikorita lati ké awọn tirẹ̀ ti o ti salà kuro; bẹ̃ni iwọ kì ba ti sé awọn tirẹ̀ ti o kù li ọjọ wahala mọ. Nitori ọjọ Oluwa kù si dẹdẹ sori gbogbo awọn keferi: bi iwọ ti ṣe, bẹ̃li a o si ṣe si ọ: ẹsan rẹ yio si yipada sori ara rẹ. Nitori bi ẹnyin ti mu lori oke mimọ́ mi, bẹ̃ni gbogbo awọn keferi yio ma mu titi, nitõtọ, nwọn o mu, nwọn o si gbemì, nwọn o si wà bi ẹnipe nwọn kò ti si. Ṣugbọn igbala yio wà lori oke Sioni, yio si jẹ mimọ́, awọn ara ile Jakobu yio si ni ini wọn. Ile Jakobu yio si jẹ iná, ati ile Josefu ọwọ́-iná, ati ile Esau fun akeku-koriko, nwọn o si ràn ninu wọn, nwọn o si run wọn; kì yio si sí ẹniti yio kù ni ile Esau: nitori Oluwa ti wi i.
Oba 1:11-18 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ tí àwọn ọ̀tá ń kó ọrọ̀ wọn lọ, tí àwọn àjèjì wọ inú ìlú wọn, tí àwọn ọ̀tá sì ń ṣẹ́ gègé lórí Jerusalẹmu, ẹ dúró, ẹ̀ ń wò wọ́n; ẹ sì dàbí ọ̀kan ninu wọn. O kì bá tí fi arakunrin rẹ ṣẹ̀sín ní ọjọ́ ìpọ́njú rẹ̀; o kì bá tí jẹ́ kí inú rẹ dùn, ní ọjọ́ ìparun àwọn eniyan Juda; o kì bá tí fọ́nnu ní ọjọ́ ìbànújẹ́ wọn. O kì bá tí wọ ìlú àwọn eniyan mi ní ọjọ́ ìpọ́njú wọn; o kì bá tí fi wọ́n ṣẹ̀sín ní ọjọ́ àjálù wọn; o kì bá tí kó wọn lẹ́rù ní ọjọ́ ìpọ́njú wọn. O kì bá tí dúró sí oríta, kí o máa mú àwọn tí wọn ń gbìyànjú láti sá àsálà; o kì bá tí fà wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́ ní ọjọ́ ìpọ́njú wọn. “Ọjọ́ ìdájọ́ OLUWA fẹ́rẹ̀ dé sórí àwọn orílẹ̀-èdè; a óo san án fún ọ, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Ohun tí o bá ṣe, yóo pada sí orí ara rẹ. Ẹ̀yin eniyan mi, bí ẹ ti jìyà ní òkè mímọ́ mi, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè náà yóo jìyà; wọn óo jìyà yóo tẹ́ wọn lọ́rùn, wọn yóo sì wà gẹ́gẹ́ bí ẹni pé wọn kò sí rí. “Ṣugbọn ní òkè Sioni ni àwọn tí wọ́n bá sá àsálà yóo máa gbé, yóo sì jẹ́ òkè mímọ́; àwọn ọmọ Jakọbu yóo gba ohun ìní wọn pada. Ilé Jakọbu yóo dàbí iná, ilé Josẹfu yóo dàbí ọ̀wọ́ iná, ilé Esau yóo sì dàbí àgékù koríko. Wọn yóo jó ilé Esau; àwọn ìran Esau yóo jó àjórun láìku ẹnìkan; nítorí pé OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.
Oba 1:11-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ tí ìwọ dúró ní apá kan, ní ọjọ́ tí àlejò kó ogún rẹ lọ, tí àwọn àjèjì sì wọ ibodè rẹ tí wọ́n sì sẹ́ kèké lórí Jerusalẹmu, ìwọ náà wà bí ọ̀kan nínú wọn. Ìwọ kì bá tí fi ojú kéré arákùnrin rẹ, ní àkókò ìbànújẹ́ rẹ̀ ìwọ kì bá tí yọ̀ lórí àwọn ọmọ Juda, ní ọjọ́ ìparun wọn ìwọ kì bá tí gbéraga púpọ̀ ní ọjọ́ wàhálà wọn. Ìwọ kì bá tí wọ inú ibodè àwọn ènìyàn mi lọ, ní ọjọ́ àjálù wọn. Ìwọ kì bá tí fojú kó wọn mọ́lẹ̀ nínú ìdààmú wọn, ní ọjọ́ àjálù wọn. Ìwọ kì bá tí jí ẹrù wọn kó, ní ọjọ́ ìpọ́njú wọn. Ìwọ kì bá tí dúró ní ìkóríta ọ̀nà láti ké àwọn tirẹ̀ tó ti sálà kúrò. Ìwọ kì bá tí fa àwọn tó ṣẹ́kù nínú wọn lélẹ̀ ní ọjọ́ wàhálà wọn. “Nítorí ọjọ́ OLúWA súnmọ́ etílé lórí gbogbo àwọn kèfèrí. Bí ìwọ ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí ìwọ náà; ẹ̀san rẹ yóò sì yípadà sí orí ara rẹ. Gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀ ṣe mu lórí òkè mímọ́ mi bẹ́ẹ̀ ni gbogbo kèfèrí yóò máa mu títí Wọn yóò mu wọn yóò sì mu àmutẹ́rùn wọn yóò sì wà bí ẹni pé wọn kò wà rí Ṣùgbọ́n ìgbàlà yóò wà lórí òkè Sioni Wọn yóò sì jẹ́ mímọ́ àti ilé Jakọbu yóò sì ní ìní wọn Ilé Jakọbu yóò sì jẹ́ iná àti ilé Josẹfu ọwọ́ iná ilé Esau yóò jẹ àgékù koríko wọn yóò fi iná sí i, wọn yóò jo run. Kì yóò sí ẹni tí yóò kù ní ilé Esau.” Nítorí OLúWA ti sọ̀rọ̀.