Oba 1:1-9 - Compare All Versions

Oba 1:1-9 YBCV (Bibeli Mimọ)

IRAN ti Obadiah. Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi niti Edomu; Awa ti gbọ́ ihìn kan lati ọdọ Oluwa wá, a si ti rán ikọ̀ kan si ãrin awọn keferi, Ẹ dide, ẹ si jẹ ki a dide ogun si i. Kiyesi i, mo ti sọ iwọ di kekere larin awọn keferi: iwọ di gigàn lọpọlọpọ. Irera aiya rẹ ti tàn ọ jẹ, iwọ ti ngbe inu pàlapála apáta, ibugbe ẹniti o ga: ti o nwi li ọkàn rẹ̀ pe, Tani yio mu mi sọkalẹ? Bi iwọ tilẹ gbe ara rẹ ga bi idì, ati bi iwọ tilẹ tẹ́ itẹ rẹ sãrin awọn irawọ, lati ibẹ li emi o ti sọ̀ ọ kalẹ, ni Oluwa wi. Bi awọn olè tọ̀ ọ wá, bi awọn ọlọṣà li oru, (bawo li a ti ke ọ kuro!) nwọn kì yio ha jale titi nwọn fi ni to? bi awọn aka-eso-ajara wá sọdọ rẹ, nwọn kì yio ha fi ẽṣẹ́ diẹ silẹ? Bawo li a ti ṣawari awọn nkan Esau! bawo li a ti wá awọn ohun ikọkọ rẹ̀ jade! Gbogbo awọn ẹni imulẹ rẹ ti mu ọ de opin ilẹ rẹ: awọn ti nwọn ti wà li alafia pẹlu rẹ ti tàn ọ jẹ, nwọn si bori rẹ; awọn ti o jẹ onjẹ rẹ ti fi ọgbẹ́ si abẹ rẹ: oye kò si ninu rẹ̀. Oluwa wipe, li ọjọ na ki emi o run awọn ọlọgbọn kuro ni Edomu, ati imoye kuro li oke Esau? Awọn alagbara rẹ yio si bẹ̀ru, iwọ Temani, nitori ki a le ke olukuluku ti ori oke Esau kuro nitori ipania.

Oba 1:1-9 YCE (Yoruba Bible)

Ìran tí Ọbadaya rí nìyí, OLUWA Ọlọrun sọ nípa Edomu pé: A ti gbọ́ ìròyìn láti ọ̀dọ̀ OLUWA, ó sì ti rán iranṣẹ rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè pé: “Ẹ múra, ẹ jẹ́ kí á lọ bá Edomu jagun!” Ó sọ fún Edomu pé, “Wò ó, n óo sọ ọ́ di yẹpẹrẹ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù; gbogbo ayé pátá ni yóo máa fi ọ́ ṣẹ̀sín. Ìgbéraga rẹ ti tàn ọ́ jẹ, ìwọ tí ò ń gbé inú pàlàpálá òkúta, tí ibùgbé rẹ wà lórí òkè gíga, tí o sì ń wí ninu ọkàn rẹ pé, ‘Ta ni ó lè fà mí lulẹ̀?’ Bí o tilẹ̀ fò lọ sókè bí ẹyẹ idì, tí ó tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí ààrin àwọn ìràwọ̀, láti òkè náà ni n óo ti fà ọ́ lulẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Bí àwọn olè bá wá bá ọ lóru, tí àwọn ọlọ́ṣà bá wá ká ọ mọ́lé lọ́gànjọ́, ṣé wọn kò ní hàn ọ́ léèmọ̀? Ṣebí ohun tí wọ́n bá fẹ́ ninu ẹrù rẹ ni wọn óo kó? Bí àwọn tí wọn ń kórè àjàrà bá wá sọ́dọ̀ rẹ, ṣebí wọn a máa fi díẹ̀ sílẹ̀? Ogun ti kó Esau, gbogbo ìṣúra rẹ̀ ni wọ́n ti kó tán! Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ọ dá majẹmu ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti lé ọ títí dé ààlà ilẹ̀ rẹ; àwọn tí ẹ jọ ń gbé ní alaafia tẹ́lẹ̀ ti di ọ̀tá rẹ; àwọn ọ̀rẹ́ tí o gbẹ́kẹ̀lé ti dẹ tàkúté sílẹ̀ dè ọ́, o kò sì mọ̀. “Ní ọjọ́ náà, ni n óo pa àwọn ọlọ́gbọ́n run ní Edomu, òye wọn yóo sì di òfo ní òkè Esau. Ìwọ ìlú Temani, ìbẹ̀rùbojo yóo dé bá àwọn akọni rẹ, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní òkè Esau ni a óo sì fi idà pa.

Oba 1:1-9 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Ìran ti Obadiah. Èyí ni OLúWA Olódùmarè wí nípa Edomu. Àwa ti gbọ́ ohùn kan láti ọ̀dọ̀ OLúWA wá, a sì ti rán ikọ̀ kan sí gbogbo kèfèrí láti sọ pé, “Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a dìde ogun sí i.” “Kíyèsi i, Èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrín àwọn kèfèrí; ìwọ yóò sì di gígàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Ìgbéraga àyà rẹ ti tàn ọ́ jẹ, ìwọ tí ń gbé inú pálapàla àpáta, tí o sì kọ́ ibùgbé rẹ sí ibi gíga, ìwọ wí nínú ọkàn rẹ pé, ‘Ta ni yóò mú mi sọ̀kalẹ̀?’ Bí ìwọ tilẹ̀ gbé ara rẹ ga bí ẹyẹ idì, bí ìwọ tilẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ rẹ sí àárín àwọn ìràwọ̀, láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti sọ̀ ọ kalẹ̀,” ni OLúWA wí. “Bí àwọn olè tọ̀ ọ́ wá, bí àwọn ọlọ́ṣà ní òru, Háà! Irú ìparun wo ló dúró dè ọ́, wọn kò ha jalè tó bí wọ́n ti fẹ́? Bí àwọn tí ń ká èso àjàrà tọ̀ ọ́ wá, wọn kò ha ni fi èso àjàrà díẹ̀ sílẹ̀? Báwo ni a ṣe ṣe àwárí nǹkan Esau, tí a sì wá ohun ìní ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ jáde. Gbogbo àwọn ẹni ìmùlẹ̀ rẹ ti mú ọ dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti borí rẹ; àwọn tó jẹ oúnjẹ rẹ dẹ pàkúté dè ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò ní ní òye rẹ̀.” OLúWA wí pé, “Ní ọjọ́ náà, Èmi kì yóò ha pa àwọn ọlọ́gbọ́n Edomu run, àti àwọn amòye run kúrò ní òkè Esau? A ó ṣe ẹ̀rù ba àwọn jagunjagun rẹ, ìwọ Temani, gbogbo àwọn tó wà ní orí òkè Esau ní a ó gé kúrò nínú ìpànìyàn náà.