Num 9:1-14
Num 9:1-14 Yoruba Bible (YCE)
Ní oṣù kinni, ọdún keji tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní Ijipti, OLUWA sọ fún Mose ninu aṣálẹ̀ Sinai pé, “Kí àwọn ọmọ Israẹli máa ṣe Àjọ̀dún ìrékọjá ní àkókò rẹ̀. Ní ọjọ́ kẹrinla oṣù yìí, láti àṣáálẹ́ ni àwọn ọmọ Israẹli yóo ti máa ṣe Àjọ̀dún ìrékọjá gẹ́gẹ́ bí òfin ati ìlànà rẹ̀.” Mose bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọ́n ṣe Àjọ̀dún ìrékọjá. Wọn sì ṣe é ní àṣáálẹ́ ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni ní aṣálẹ̀ Sinai. Àwọn eniyan náà ṣe gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fun wọn. Ṣugbọn àwọn kan wà tí wọn kò lè bá wọn ṣe ọdún náà nítorí pé wọ́n jẹ́ aláìmọ́ nípa fífi ọwọ́ kan òkú. Wọ́n wá sọ́dọ̀ Mose ati Aaroni, wọ́n sì sọ fún wọn pé, “Nítòótọ́, a ti di aláìmọ́ nítorí pé a fi ọwọ́ kan òkú, ṣugbọn kí ló dé tí a kò fi lè mú ọrẹ ẹbọ wa wá fún OLUWA gẹ́gẹ́ bí àwọn arakunrin wa?” Mose bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ dúró di ìgbà tí mo bá gbọ́ àṣẹ tí OLUWA yóo pa nípa yín.” OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, nígbà tí ọ̀kan ninu yín tabi àwọn ọmọ yín bá di aláìmọ́ nítorí pé ó fi ọwọ́ kan òkú; tabi ó wà ní ìrìn àjò, ṣugbọn tí ọkàn rẹ̀ sì fẹ́ ṣe Àjọ̀dún ìrékọjá. Anfaani wà fun yín pé kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe é ní ọjọ́ kẹrinla oṣù keji. Kí ó ṣe é pẹlu burẹdi tí a kò fi ìwúkàrà sí ati ewébẹ̀ kíkorò. Ẹ kò gbọdọ̀ fi àjẹkù kankan sílẹ̀ di ọjọ́ keji, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọ́ ọ̀kankan ninu egungun ẹran tí ẹ bá fi rú ẹbọ náà. Ẹ óo ṣe ọdún Àjọ̀dún Ìrékọjá náà gẹ́gẹ́ bí òfin ati ìlànà rẹ̀. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ́, tí kò lọ sí ìrìn àjò, ṣugbọn tí kò ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá ni a ó yọ kúrò láàrin àwọn eniyan mi, nítorí kò mú ọrẹ ẹbọ wá fún OLUWA ní àkókò rẹ̀. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ níláti jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. “Bí àlejò kan bá wà ní ààrin yín tí ó sì fẹ́ ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá, yóo ṣe é gẹ́gẹ́ bí òfin ati ìlànà rẹ̀. Òfin ati ìlànà kan náà ni ó wà fún gbogbo yín, ati onílé ati àlejò.”
Num 9:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sọ fún Mose nínú aginjù Sinai ní oṣù kìn-ín-ní ọdún kejì lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti wí pé; “Mú kí àwọn ọmọ Israẹli máa pa àjọ ìrékọjá mọ́ ní àsìkò rẹ̀. Ẹ ṣe é ní àsìkò rẹ̀ gan an ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀.” Mose sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n máa pa àjọ ìrékọjá mọ́. Wọ́n sì ṣe àjọ ìrékọjá ní aginjù Sinai ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pàṣẹ fún Mose. Àwọn díẹ̀ nínú wọn kò lè ṣe àjọ Ìrékọjá lọ́jọ́ náà nítorí pé wọ́n di aláìmọ́ nítorí òkú ènìyàn. Nítorí èyí wọ́n wá sọ́dọ̀ Mose àti Aaroni lọ́jọ́ náà. Wọ́n sọ fún Mose pé, “A di aláìmọ́ nípa òkú ènìyàn, ṣùgbọ́n kí ló dé tí a kò fi ní í le è fi ọrẹ wa fún OLúWA pẹ̀lú àwọn ará Israẹli yòókù ní àsìkò tí a ti yàn.” Mose sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ dúró kí n ba lè mọ ohun tí OLúWA yóò pàṣẹ nípa yín.” Nígbà náà ni OLúWA sọ fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ará Israẹli: ‘Bí ẹnìkan nínú yín tàbí nínú ìran yín bá di aláìmọ́ nípa òkú ènìyàn tàbí bí ó bá lọ sí ìrìnàjò síbẹ̀ yóò pa àjọ Ìrékọjá OLúWA mọ́. Wọn yóò ṣe tiwọn ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì. Wọn yóò jẹ ẹran náà, pẹ̀lú àkàrà aláìwú àti ewúro. Wọn kò gbọdọ̀ ṣẹ́ ọ̀kankan kù di àárọ̀, wọn kò sì gbọdọ̀ ṣẹ́ eegun rẹ̀. Wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀lé gbogbo ìlànà fún ṣíṣe àjọ Ìrékọjá. Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan tó wà ní mímọ́ tí kò sì lọ sí ìrìnàjò bá kọ̀ láti pa àjọ Ìrékọjá mọ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀ nítorí pé kò mú ọrẹ OLúWA wá ní àsìkò tí ó yẹ. Ẹni náà yóò sì ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. “ ‘Bí àlejò tí ń gbé láàrín yín bá fẹ́ ṣe Àjọ Ìrékọjá OLúWA, ó gbọdọ̀ pa á mọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àti òfin rẹ̀. Ìlànà kan náà ni kí ẹ ní fún àlejò àti àwọn ọmọ bíbí ilẹ̀ yín.’ ”
Num 9:1-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si sọ fun Mose ni ijù Sinai, li oṣù kini ọdún keji ti nwọn ti ilẹ Egipti jade wá, wipe, Ki awọn ọmọ Israeli ki o si ma pa ajọ irekọja mọ́ li akokò rẹ̀. Li ọjọ́ kẹrinla oṣù yi, li aṣalẹ, ni ki ẹnyin ki o ma ṣe e li akokò rẹ̀: gẹgẹ bi aṣẹ rẹ̀ gbogbo, ati gẹgẹ bi ìlana rẹ̀ gbogbo, ni ki ẹnyin ki o pa a mọ́. Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli ki nwọn ki o ma pa ajọ irekọja mọ́: Nwọn si ṣe ajọ irekọja li ọjọ́ kẹrinla, oṣù kini, li aṣalẹ ni ijù Sinai: gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun Mose, bẹ̃li awọn ọmọ Israeli ṣe. Awọn ọkunrin kan wà ti nwọn ti ipa okú ọkunrin kan di alaimọ́, nwọn kò si le ṣe ajọ irekọja li ọjọ́ na: nwọn si wá siwaju Mose ati siwaju Aaroni li ọjọ́ na: Awọn ọkunrin na si wi fun u pe, Awa ti ipa okú ọkunrin kan di alaimọ́: nitori kili a o ṣe fàsẹhin ti awa ki o le mú ọrẹ-ẹbọ OLUWA wá li akokò rẹ̀ pẹlu awọn ọmọ Israeli? Mose si wi fun wọn pe, Ẹ duro na; ki emi ki o le gbọ́ aṣẹ ti OLUWA yio pa niti nyin. OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi ẹnikẹni ninu nyin, tabi ninu iran nyin, ba ti ipa okú di alaimọ́, tabi bi o ba wà li ọ̀na àjo jijìn rére, sibẹ̀ on o pa ajọ irekọja mọ́ fun OLUWA. Li ọjọ́ kẹrinla oṣù keji li aṣalẹ ni ki nwọn ki o pa a mọ́; ki nwọn si fi àkara alaiwu jẹ ẹ ati ewebẹ kikorò: Ki nwọn ki o máṣe kùsilẹ ninu rẹ̀ titi di owurọ̀, bẹ̃ni nwọn kò gbọdọ fọ́ egungun rẹ̀ kan: gẹgẹ bi gbogbo ìlana irekọja ni ki nwọn ki o ṣe e. Ṣugbọn ọkunrin na ti o mọ́ ti kò si sí li ọ̀na àjo, ti o si fàsẹhin lati pa irekọja mọ́, ani ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀: nitoriti kò mú ọrẹ-ẹbọ OLUWA wá li akokò rẹ̀, ọkunrin na yio rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀. Bi alejò kan ba si nṣe atipo lọdọ nyin, ti o si nfẹ́ pa irekọja mọ́ fun OLUWA; gẹgẹ bi ìlana irekọja, ati gẹgẹ bi aṣẹ rẹ̀, ni ki o ṣe bẹ̃: ìlana kan ni ki ẹnyin ki o ní, ati fun alejò, ati fun ibilẹ.