Num 8:14-16
Num 8:14-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bẹ̃ni ki iwọ ki o yà awọn ọmọ Lefi sọ̀tọ kuro lãrin awọn ọmọ Israeli: awọn ọmọ Lefi yio si jẹ́ ti emi. Lẹhin eyinì li awọn ọmọ Lefi yio ma wọ̀ inu ile lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ: ki iwọ ki o si wẹ̀ wọn mọ́, ki o si mú wọn wá li ọrẹ fifì. Nitoripe patapata li a fi wọn fun mi ninu awọn ọmọ Israeli; ni ipò gbogbo awọn ti o ṣí inu, ani gbogbo akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ni mo gbà wọn fun ara mi.
Num 8:14-16 Yoruba Bible (YCE)
Bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe ya àwọn ọmọ Lefi sọ́tọ̀ láàrin àwọn ọmọ Israẹli, wọn óo sì jẹ́ tèmi. Lẹ́yìn tí o bá ti wẹ̀ wọ́n mọ́, tí o sì ti yà wọ́n sọ́tọ̀ bí ẹbọ fífì sí OLUWA, ni àwọn ọmọ Lefi tó lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ. Mo ti gbà wọ́n dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì di tèmi patapata.
Num 8:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Báyìí ni ìwọ yóò ṣe ya ọmọ Lefi sọ́tọ̀, kúrò láàrín àwọn ọmọ Israẹli yòókù, àwọn ọmọ Lefi yóò sì jẹ́ tèmi. “Lẹ́yìn tí ó ti wẹ àwọn ọmọ Lefi mọ́, tí ó sì ti gbé wọn kalẹ̀ bí ẹbọ fífì nígbà náà ni kí wọn ó lọ máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé. Nítorí pé àwọn ni ó jẹ́ ti Èmi pátápátá nínú àwọn ọmọ Israẹli. Mo ti gbà wọ́n fún ara mi dípò àwọn àkọ́bí àní àkọ́bí ọkùnrin gbogbo Israẹli.