Num 7:1-89
Num 7:1-89 Bibeli Mimọ (YBCV)
OSI ṣe li ọjọ́ na ti Mose gbé agọ́ na ró tán, ti o si ta oróro si i ti o si yà a simimọ́, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati pẹpẹ na ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ti o si ta oróro si wọn, ti o si yà wọn simimọ́; Ni awọn ijoye Israeli, awọn olori ile baba wọn, awọn olori ẹ̀ya wọnni, ti iṣe olori awọn ti a kà, mú ọrẹ wá: Nwọn si mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá siwaju OLUWA, kẹkẹ́-ẹrù mẹfa ti a bò, ati akọmalu mejila; kẹkẹ́-ẹrù kan fun ijoye meji, ati akọmalu kan fun ọkọkan: nwọn si mú wọn wá siwaju agọ́ ajọ. OLUWA si sọ fun Mose pe, Gbà a lọwọ wọn, ki nwọn ki o le jẹ́ ati fi ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ; ki iwọ ki o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi, fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin rẹ̀. Mose si gbà kẹkẹ́-ẹrù wọnni, ati akọmalu, o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi. Kẹkẹ́-ẹrù meji ati akọmalu mẹrin, li o fi fun awọn ọmọ Gerṣoni, gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin wọn: Ati kẹkẹ́-ẹrù mẹrin ati akọmalu mẹjọ li o fi fun awọn ọmọ Merari, gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin wọn, li ọwọ́ Itamari ọmọ Aaroni alufa. Ṣugbọn kò fi fun awọn ọmọ Kohati: nitoripe iṣẹ-ìsin ibi-mimọ́ ni ti wọn; li ohun ti nwọn o ma fi ejika rù. Awọn olori si mú ọrẹ wá fun ìyasimimọ́ pẹpẹ li ọjọ́ ti a ta oróro si i, ani awọn olori mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá siwaju pẹpẹ na. OLUWA si wi fun Mose pe, Ki nwọn ki o ma mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá, olukuluku olori li ọjọ́ tirẹ̀ fun ìyasimimọ̀ pẹpẹ. Ẹniti o si mú ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ wá li ọjọ́ kini ni Naṣoni ọmọ Amminadabu, ti ẹ̀ya Juda. Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ si jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ; Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Naṣoni ọmọ Amminadabu. Li ọjọ́ keji ni Netaneeli ọmọ Suari, olori ti Issakari mú ọrẹ wá: On múwa fun ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ: Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Netaneeli ọmọ Suari. Li ọjọ́ kẹta Eliabu ọmọ Heloni, olori awọn ọmọ Sebuluni: Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ; Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Eliabu ọmọ Heloni. Li ọjọ́ kẹrin Elisuri ọmọ Ṣedeuri, olori awọn ọmọ Reubeni; Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ̀ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò fun ẹbọ ohunjijẹ; Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Elisuri ọmọ Ṣedeuri. Li ọjọ́ karun Ṣelumieli ọmọ Suriṣuddai, olori awọn ọmọ Simeoni: Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò fun ẹbọ ohunjijẹ; Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ Ṣelumieli ọmọ Ṣuriṣaddai. Li ọjọ́ kẹfa Eliasafu ọmọ Deueli, olori awọn ọmọ Gadi: Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò fun ẹbọ ohunjijẹ; Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; Akọ ewure kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ Eliasafu ọmọ Deueli. Li ọjọ́ keje Eliṣama ọmọ Ammihudu, olori awọn ọmọ Efraimu: Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ; Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ Eliṣama ọmọ Ammihudu. Li ọjọ́ kẹjọ Gamalieli ọmọ Pedasuri, olori awọn ọmọ Manasse: Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ; Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Gamalieli ọmọ Pedasuri. Li ọjọ́ kẹsan Abidani ọmọ Gideoni, olori awọn ọmọ Benjamini: Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ; Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Abidani ọmọ Gideoni. Li ọjọ́ kẹwá ni Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai, olori awọn ọmọ Dani: Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ìwọn ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ: Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai. Li ọjọ́kọkanla Pagieli ọmọ Okrani, olori awọn ọmọ Aṣeri: Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ìwọn ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ; Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Pagieli ọmọ Okrani. Li ọjọ́ kejila Ahira ọmọ Enani, olori awọn ọmọ Naftali: Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ̀ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ; Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari; Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun; Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Ahira ọmọ Enani. Eyi ni ìyasimimọ́ pẹpẹ, li ọjọ́ ti a ta oróro si i, lati ọwọ́ awọn olori Israeli wá: awopọkọ fadakà mejila, awokòto fadakà mejila, ṣibi wurà mejila: Awopọkọ fadakà kọkan jẹ́ ãdoje ṣekeli: awokòto kọkan jẹ́ ãdọrin: gbogbo ohun-èlo fadakà jẹ́ egbejila ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; Ṣibi wurà jẹ́ mejila, nwọn kún fun turari, ṣibi kọkan jẹ́ ṣekeli mẹwa, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; gbogbo wurà agọ́ na jẹ́ ọgọfa ṣekeli. Gbogbo akọmalu fun ẹbọ sisun jẹ́ ẹgbọrọ akọmalu mejila, àgbo mejila, akọ ọdọ-agutan ọlọdún kan mejila, pẹlu ẹbọ ohunjijẹ wọn: ati akọ ewurẹ fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, mejila. Ati gbogbo akọmalu fun ẹbọ ti ẹbọ alafia jẹ́ akọmalu mẹrinlelogun, àgbo ọgọta, obukọ ọgọta, akọ ọdọ-agutan ọlọdún kan ọgọta. Eyi ni ìyasimimọ́ pẹpẹ, lẹhin igbati a ta oróro si i. Nigbati Mose si wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ lati bá a (Ọlọrun) sọ̀rọ, nigbana li o gbọ́ ohùn ti nfọ̀ si i lati ori itẹ́-ãnu nì wá ti mbẹ lori apoti ẹrí, lati agbedemeji awọn kerubu meji nì wá: o si bá a sọ̀rọ.
Num 7:1-89 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ tí Mose gbé Àgọ́ Àjọ dúró, tí ó sì ta òróró sí i tòun ti gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀, ati pẹpẹ pẹlu gbogbo ohun èlò rẹ̀, àwọn olórí àwọn ẹ̀yà Israẹli, tí wọ́n jẹ́ olórí ní ìdílé wọn, tí wọ́n sì wà pẹlu Mose nígbà tí ó ka àwọn eniyan Israẹli, mú ọrẹ ẹbọ wá siwaju OLUWA. Ọkọ̀ ẹrù mẹfa ati akọ mààlúù mejila. Ọkọ̀ ẹrù kọ̀ọ̀kan fún olórí meji meji, ati akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan fún olórí kọ̀ọ̀kan. Wọ́n mú àwọn ẹbọ wọnyi wá sí ẹnu ọ̀nà ibi mímọ́. OLUWA sọ fún Mose pé kí ó gba àwọn ẹbọ náà lọ́wọ́ wọn fún lílò ninu Àgọ́ Àjọ, kí ó sì pín wọn fún olukuluku àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìsìn olukuluku wọn ti rí. Mose bá gba àwọn ọkọ̀ ẹrù ati àwọn akọ mààlúù náà, ó kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi. Ó fún àwọn ọmọ Geriṣoni ní ọkọ̀ ẹrù meji ati akọ mààlúù mẹrin, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìsìn wọn. Ó fún àwọn ọmọ Merari ní ọkọ̀ ẹrù mẹrin ati akọ mààlúù mẹjọ, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìsìn wọn, lábẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni alufaa. Ṣugbọn àwọn ọmọ Kohati ni Mose kò fún ní nǹkankan, nítorí pé àwọn ohun mímọ́ tí wọ́n máa ń fi èjìká rù ni iṣẹ́ ìsìn wọn jẹ mọ́. Àwọn olórí náà rú ẹbọ fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ ní ọjọ́ tí wọ́n ta òróró sí i, láti yà á sí mímọ́. Wọ́n mú ẹbọ wọn wá siwaju pẹpẹ. OLUWA sọ fún Mose pé, “Kí olukuluku olórí mú ọrẹ ẹbọ tirẹ̀ fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ wá ní ọjọ́ tirẹ̀.” Ní ọjọ́ kinni, Naṣoni ọmọ Aminadabu, olórí ẹ̀yà Juda mú ẹbọ tirẹ̀ wá. Ọrẹ ẹbọ rẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli, ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, fún ẹbọ ohun jíjẹ. Àwo kòtò tí wọ́n fi wúrà ṣe kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari; akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan, ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun; ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ó kó àwọn nǹkan wọnyi kalẹ̀ fún ẹbọ alaafia: akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan. Wọ́n jẹ́ ọrẹ ẹbọ Naṣoni, ọmọ Aminadabu. Ní ọjọ́ keji ni Netaneli ọmọ Suari olórí ẹ̀yà Isakari mú ọrẹ tirẹ̀ wá. Ọrẹ ẹbọ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ jẹ́ aadọrin ṣekeli, ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, fún ẹbọ ohun jíjẹ; ṣíbí wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari; akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò kan, ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun; òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ó sì mú akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan wá fún ẹbọ alaafia. Wọ́n jẹ́ ọrẹ Netaneli ọmọ Suari. Ní ọjọ́ kẹta Eliabu ọmọ Heloni, olórí ẹ̀yà Sebuluni mú ọrẹ tirẹ̀ wá. Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní Àgọ́ Àjọ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ. Ṣíbí wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá tí ó sì kún fún turari. Akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun. Òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ó sì mú akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan wá fún ẹbọ alaafia. Èyí ni ọrẹ Eliabu ọmọ Heloni. Ní ọjọ́ kẹrin Elisuri ọmọ Ṣedeuri, olórí ẹ̀yà Reubẹni mú ọrẹ tirẹ̀ wá. Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli, ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ, ṣíbí wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá tí ó sì kún fún turari. Akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ati ọ̀dọ́ àgbò ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun, ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ó sì mú akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati akọ ọ̀dọ́ aguntan marun-un ọlọ́dún kan wá fún ẹbọ alaafia. Ọrẹ ti Elisuri ọmọ Ṣedeuri nìyí. Ní ọjọ́ karun-un, Ṣelumieli ọmọ Suriṣadai, olórí ẹ̀yà Simeoni mú ọrẹ tirẹ̀ wa. Ọrẹ rẹ̀ ni àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ. Ara ọrẹ rẹ̀ tún ni: àwo kòtò kan tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari, akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun, ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Lẹ́yìn náà, Ṣelumieli, ọmọ Suriṣadai tún ko akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un, ati akọ ọ̀dọ́ aguntan marun-un ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan kalẹ̀ fún ẹbọ alaafia. Ní ọjọ́ kẹfa ni Eliasafu, ọmọ Deueli, olórí àwọn ẹ̀yà Gadi, mú ọrẹ tirẹ̀ wá. Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin (70) ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, fún ẹbọ ohun jíjẹ. Ara ọrẹ rẹ̀ tún ni: àwo kòtò kan tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari, akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun; ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Lẹ́yìn náà Eliasafu, ọmọ Deueli, tún ko akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un, ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan kalẹ̀ fún ẹbọ alaafia. Ní ọjọ́ keje ni Eliṣama ọmọ Amihudu, olórí àwọn ẹ̀yà Efuraimu mú ọrẹ tirẹ̀ wá. Ọrẹ tirẹ̀ ni àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli ati abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ. Ara ọrẹ rẹ̀ tún ni àwo kòtò kan tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari. Akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun, ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Eliṣama, ọmọ Amihudu, kó akọ mààlúù meji, ati àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan sílẹ̀ fún ẹbọ alaafia. Ní ọjọ́ kẹjọ ni Gamalieli ọmọ Pedasuri, olórí àwọn ẹ̀yà Manase mú ọrẹ ẹbọ tirẹ̀ wá. Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, fún ẹbọ ohun jíjẹ. Ara ọrẹ rẹ̀ tún ni àwo kòtò kan tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari, akọ mààlúù kékeré kan, ati àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan, ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun, ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Gamalieli ọmọ Pedasuri, kó àwọn akọ mààlúù meji ati àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan sílẹ̀ fún ẹbọ alaafia. Ní ọjọ́ kẹsan-an ni Abidani ọmọ Gideoni, olórí àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini mú ọrẹ tirẹ̀ wá. Ọrẹ tirẹ̀ ni àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọ́n ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, fún ẹbọ ohun jíjẹ. Ara ọrẹ rẹ̀ tún ni: àwo kòtò kan, tí wọ́n fi wúrà ṣe tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari. Akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò, ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun, ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Abidani ọmọ Gideoni, kó akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un, ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan sílẹ̀ fún ẹbọ alaafia. Ní ọjọ́ kẹwaa ni Ahieseri ọmọ Amiṣadai, olórí àwọn ẹ̀yà Dani mú ọrẹ tirẹ̀ wá. Ọrẹ tirẹ̀ ni àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ. Ara àwọn ọrẹ rẹ̀ tún ni: àwo kòtò kan tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari. Akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan, ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun, ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ahieseri ọmọ Amiṣadai, kó akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati akọ ọ̀dọ́ aguntan marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan wá fún ẹbọ alaafia. Ní ọjọ́ kọkanla ni Pagieli ọmọ Okirani, olórí àwọn ẹ̀yà Aṣeri mú ọrẹ tirẹ̀ wá. Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ẹbọ ohun jíjẹ. Ara àwọn ọrẹ rẹ̀ tún ni àwo kòtò kan tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá tí ó sì kún fún turari; akọ mààlúù kékeré kan ati àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun, ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Pagieli ọmọ Okirani, kó akọ mààlúù meji ati àgbò marun-un kalẹ̀, pẹlu òbúkọ marun-un, ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, fún ẹbọ alaafia. Ní ọjọ́ kejila ni Ahira ọmọ Enani, olórí àwọn ẹ̀yà Nafutali, mú ọrẹ tirẹ̀ wá. Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, pẹlu abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ẹbọ ohun jíjẹ. Ara àwọn ọrẹ rẹ̀ tún ni: àwo kòtò kan, tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari; akọ mààlúù kékeré kan ati àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun; ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ahira, ọmọ Enani, kó akọ mààlúù meji ati àgbò marun-un, òbúkọ marun-un, ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan wá fún ẹbọ alaafia. Ní àpapọ̀, àwọn nǹkan ọrẹ tí àwọn olórí mú wá fún yíya pẹpẹ sí mímọ́ ní ọjọ́ tí a fi àmì òróró yà á sí mímọ́ ni: abọ́ fadaka mejila, àwo fadaka mejila, àwo kòtò tí wọ́n fi wúrà ṣe mejila, ìwọ̀n àwo fadaka kọ̀ọ̀kan jẹ́ aadoje (130) ṣekeli; ìwọ̀n gbogbo àwọn abọ́ fadaka náà jẹ́ ẹgbaa ṣekeli ó lé irinwo (2,400). Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n wọ́n. Ìwọ̀n ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn àwo kòtò mejeejila tí wọ́n kún fún turari jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá mẹ́wàá. Ìwọ̀n ṣekeli tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n wọ́n. Ìwọ̀n àwọn àwo kòtò tí wọ́n fi wúrà ṣe jẹ́ ọgọfa (120) ṣekeli. Gbogbo mààlúù tí wọ́n mú wá fún ọrẹ ẹbọ sísun jẹ́ mejila ati àgbò mejila, ọ̀dọ́ àgbò mejila ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ. Wọ́n tún mú òbúkọ mejila wá fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Àwọn nǹkan tí wọ́n kó kalẹ̀ fún ẹbọ alaafia ni: akọ mààlúù mẹrinlelogun pẹlu ọgọta àgbò; ọgọta òbúkọ, ọgọta ọ̀dọ́ àgbò ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan. Wọ́n kó gbogbo wọn wá fún ọrẹ ẹbọ fún yíya pẹpẹ sí mímọ́, lẹ́yìn tí wọ́n ta òróró sí i. Nígbà tí Mose wọ inú àgọ́ ìpàdé lọ láti bá OLUWA sọ̀rọ̀, ó gbọ́ ohùn kan tí ń bá a sọ̀rọ̀ láti orí ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí, láàrin àwọn kerubu mejeeji. Ẹni náà bá Mose sọ̀rọ̀.
Num 7:1-89 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Mose ti parí gbígbé àgọ́ dúró, ó ta òróró sí i, ó sì yà á sí mímọ́ pẹ̀lú gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, Ó tún ta òróró sí pẹpẹ, ó sì yà á sí mímọ́ pẹ̀lú gbogbo ohun èlò rẹ̀. Nígbà náà ni àwọn olórí Israẹli, àwọn ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, àwọn alábojútó àwọn tí a kà náà mú ọrẹ wá. Wọ́n mú ọrẹ wọn wá síwájú OLúWA: kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́fà ti abo, àti akọ màlúù kan láti ọ̀dọ̀ olórí kọ̀ọ̀kan àti kẹ̀kẹ́ ẹrù kan láti ọ̀dọ̀ olórí méjì. Wọ́n sì kó wọn wá sí iwájú àgọ́. OLúWA sọ fún Mose pé: “Gba gbogbo nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ wọn, kí wọ́n ba à lè wúlò fún iṣẹ́ inú àgọ́ ìpàdé. Kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan bá ṣe nílò rẹ̀.” Mose sì kó àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù àti akọ màlúù náà fún àwọn ọmọ Lefi. Ó fún àwọn ọmọ Gerṣoni ní kẹ̀kẹ́ méjì àti akọ màlúù mẹ́rin, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn ṣe jẹ mọ́. Ó fún àwọn ọmọ Merari ní kẹ̀kẹ́ mẹ́rin àti akọ màlúù mẹ́jọ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn ṣe jẹ mọ́. Gbogbo wọn wà lábẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà. Ṣùgbọ́n Mose kò fún àwọn ọmọ Kohati ní nǹkan kan nítorí pé èjìká wọn ni wọn yóò fi ru àwọn ohun mímọ́ èyí tí ó jẹ́ ojúṣe tiwọn. Nígbà tí a ta òróró sórí pẹpẹ. Àwọn olórí mú àwọn ọrẹ wọn wá fún ìyàsímímọ́ rẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá síwájú pẹpẹ. Nítorí tí OLúWA ti sọ fún Mose pé, “Olórí kọ̀ọ̀kan ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ni yóò máa mú ọrẹ tirẹ̀ wá fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ.” Ẹni tí ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kìn-ín-ní Nahiṣoni ọmọ Amminadabu láti inú ẹ̀yà Juda. Ọrẹ rẹ̀ jẹ́: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò ti fàdákà tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́ àwo kọ̀ọ̀kan kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ; Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí; Ọ̀dọ́ akọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun, Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, Akọ màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Wọ̀nyí ni ọrẹ Nahiṣoni ọmọ Amminadabu. Ní ọjọ́ kejì ni Netaneli ọmọ Ṣuari olórí àwọn ọmọ Isakari mú ọrẹ tirẹ̀ wá. Ọrẹ tí ó kó wá ní: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí á fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ; Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí, Ọ̀dọ́ akọ màlúù kan, àgbò kan, àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun; Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Netaneli ọmọ Ṣuari. Eliabu ọmọ Heloni, olórí àwọn ọmọ Sebuluni ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹta. Àwọn ọrẹ rẹ̀ ni: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) àti ṣékélì fàdákà, àwokòtò kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí; Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun; Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn o fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Eliabu ọmọ Heloni. Elisuri ọmọ Ṣedeuri olórí àwọn ọmọ Reubeni ni ó mú ọrẹ wá ní ọjọ́ kẹrin. Ọrẹ rẹ̀ ni: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ; Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí, Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun; Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Elisuri ọmọ Ṣedeuri. Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai, olórí àwọn ọmọ Simeoni ni ó mú ọrẹ wá ní ọjọ́ karùn-ún. Ọrẹ tí ó kó wá ni: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ; Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí; Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun; Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai. Eliasafu ọmọ Deueli olórí àwọn ọmọ Gadi ní ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹfà. Ọrẹ rẹ̀ ni: àwo fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò bí ẹbọ ohun jíjẹ; àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí; akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun; akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Eliasafu ọmọ Deueli. Eliṣama ọmọ Ammihudu, olórí àwọn ọmọ Efraimu ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ keje. Ọrẹ rẹ̀ ni: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ; àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí; akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun; akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Eliṣama ọmọ Ammihudu. Gamalieli ọmọ Pedasuri, olórí àwọn ọmọ Manase ni ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹjọ. Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ; àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí; akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun; akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Gamalieli ọmọ Pedasuri. Abidani ọmọ Gideoni, olórí àwọn ọmọ Benjamini ni ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹsànán. Ọrẹ rẹ̀ ni: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ; àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí; akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun; akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Abidani ọmọ Gideoni. Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai, olórí àwọn ọmọ Dani ni ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹwàá. Ọrẹ rẹ̀ ni: àwo sílífà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ; àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí; akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun; akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; àti fún ẹbọ ti ẹbọ àlàáfíà, akọ màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn-ún, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn márùn-ún ọlọ́dún kan. Èyí ni ọrẹ ẹbọ tí Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai. Pagieli ọmọ Okanri, olórí àwọn ọmọ Aṣeri ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kọkànlá. Ọrẹ rẹ̀ ni: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ; àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí; akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun; akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Pagieli ọmọ Okanri. Ahira ọmọ Enani, olórí àwọn Naftali ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kejìlá. Ọrẹ rẹ̀ ni: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì, àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ; àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí; akọ ọ̀dọ́ màlúù kan àgbò kan, àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun; akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Ahira ọmọ Enani. Wọ̀nyí ni ọrẹ tí àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli mú wá fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ nígbà tí wọ́n ta òróró sí i lórí: àwo fàdákà méjìlá, àwokòtò méjìlá, àwo wúrà méjìlá. Àwo fàdákà kọ̀ọ̀kan wọn àádóje (130) ṣékélì, àwokòtò kọ̀ọ̀kan sì wọn àádọ́rin (70). Àpapọ̀ gbogbo àwo fàdákà jẹ́ egbèjìlá ṣékélì (2,400) gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwo wúrà méjìlá tí tùràrí kún inú wọn ṣékélì mẹ́wàá mẹ́wàá gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́. Àpapọ̀ ìwọ̀n gbogbo àwo wúrà jẹ́ ọgọ́fà ṣékélì (120). Àpapọ̀ iye ẹran fún ẹbọ sísun jẹ́ akọ ọ̀dọ́ màlúù méjìlá, àgbò méjìlá, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan méjìlá pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ. Akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ méjìlá. Àpapọ̀ iye ẹran fún ọrẹ àlàáfíà jẹ́ màlúù mẹ́rìnlélógún (24), ọgọ́ta (60) àgbò, ọgọ́ta (60) akọ ewúrẹ́ àti ọgọ́ta (60) akọ ọ̀dọ́ màlúù ọlọ́dún kan. Wọ̀nyí ni ọrẹ ìyàsímímọ́ pẹpẹ lẹ́yìn tí a ta òróró sí i. Nígbà tí Mose wọ inú àgọ́ ìpàdé láti bá OLúWA sọ̀rọ̀, OLúWA sì sọ̀rọ̀ sí i láti àárín àwọn kérúbù méjì láti orí ìtẹ́ àánú tí ó bo àpótí ẹ̀rí, ohùn náà sì bá Mose sọ̀rọ̀.