Num 6:1-5
Num 6:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ọkunrin kan tabi obinrin kan ba yà ara wọn sapakan lati ṣe ileri ti Nasiri, lati yà ara wọn si OLUWA: Ki o yà ara rẹ̀ kuro ninu ọti-waini tabi ọti lile; ki o má si ṣe mu ọti-waini kikan, tabi ọti lile ti o kan, ki o má si ṣe mu ọti eso-àjara kan, bẹ̃ni kò gbọdọ jẹ eso-àjara tutù tabi gbigbẹ. Ni gbogbo ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀ ni ki o gbọdọ jẹ ohun kan ti a fi eso-àjara ṣe, lati kóro rẹ̀ titi dé ẽpo rẹ̀. Ni gbogbo ọjọ́ ileri ìyasapakan rẹ̀, ki abẹ kan máṣe kàn a li ori: titi ọjọ́ wọnni yio fi pé, ninu eyiti o yà ara rẹ̀ si OLUWA, ki o jẹ́ mimọ́, ki o si jẹ ki ìdi irun ori rẹ̀ ki o ma dàgba.
Num 6:1-5 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA sọ fún Mose kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Nígbà tí ọkunrin tabi obinrin kan bá ṣe ìlérí láti di Nasiri, tí ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún OLUWA, yóo jáwọ́ kúrò ninu ọtí waini mímu, ati ọtí líle. Kò gbọdọ̀ mu ọtí kíkan tí a fi waini tabi ọtí líle ṣe. Kò gbọdọ̀ mu ọtí èso àjàrà, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ jẹ èso àjàrà tútù tabi gbígbẹ. Ní gbogbo ìgbà tí ó bá jẹ́ Nasiri, kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí a fi èso àjàrà ṣe, kì báà jẹ́ kóró tabi èèpo rẹ̀. “Kò gbọdọ̀ gé irun orí rẹ̀ tabi kí ó fá a títí tí ọjọ́ tí ó fi ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún OLUWA yóo fi pé, kí ó jẹ́ mímọ́, kí ó sì jẹ́ kí ìdì irun orí rẹ̀ máa dàgbà.
Num 6:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sọ fún Mose pé: “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé: ‘Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ pàtàkì, ẹ̀jẹ́ ìyara-ẹni-sọ́tọ̀ sí OLúWA nípa àìgé irun orí (Nasiri): Irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbọdọ̀ yàgò fún wáìnì tàbí ọtí líle, ọtí wáìnì kíkan àti àwọn ohun mímu mìíràn tó bá kan. Kò gbọdọ̀ mu èso àjàrà tàbí kí ó jẹ èso àjàrà tútù tàbí gbígbẹ. Níwọ́n ìgbà tí ó sì jẹ́ Nasiri, ní kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí a fi èso àjàrà ṣe, ìbá à ṣe kóró tàbí èèpo rẹ̀. “ ‘Ní gbogbo ìgbà ẹ̀jẹ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ yìí, kí abẹ kankan má ṣe kàn án ní orí. Ó gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ títí tí àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí OLúWA yóò fi pé; ó gbọdọ̀ jẹ́ kí irun orí rẹ̀ gùn.