Num 5:6-7
Num 5:6-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Nigbati ọkunrin kan tabi obinrin kan ba dá ẹ̀ṣẹkẹṣẹ ti enia ida, ti o ṣe irekọja si OLUWA, ti oluwarẹ̀ si jẹ̀bi; Nigbana ni ki nwọn ki o jẹwọ ẹ̀ṣẹ ti nwọn ṣẹ̀: ki o si san ẹsan ẹ̀ṣẹ rẹ̀ li oju-owo, ki o si fi idamarun rẹ̀ lé e, ki o si fi i fun ẹniti on jẹbi rẹ̀.
Num 5:6-7 Yoruba Bible (YCE)
“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé nígbà tí ẹnikẹ́ni, bá dẹ́ṣẹ̀, tí ó bá rú òfin Ọlọ́run, tí olúwarẹ̀ sì jẹ̀bi, kí báà ṣe ọkunrin tabi obinrin, olúwarẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ó san ìtanràn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ó sì fi ìdámárùn-ún iye owó náà lé e fún ẹni tí ó ṣẹ̀.
Num 5:6-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli: ‘Nígbà tí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan bá ṣẹ̀ ara wọn lọ́nà kan tàbí òmíràn, tí wọ́n sì ṣe àìṣòótọ́ sí OLúWA, ẹni náà jẹ̀bi. Ó gbọdọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀. Ó gbọdọ̀ san ẹ̀san rẹ̀ ní ojú owó, kí ó sì fi ìdámárùn-ún rẹ̀ lé e, kí ó sì fi fún ẹni tí Òun jẹ̀bi rẹ̀.