Num 4:1-49

Num 4:1-49 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA si sọ fun Mose ati Aaroni pe, Kà iye awọn ọmọ Kohati kuro ninu awọn ọmọ Lefi, nipa idile wọn, ile baba wọn, Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin, lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ. Eyi ni yio ṣe iṣẹ-ìsin awọn ọmọ Kohati ninu agọ́ ajọ, niti ohun mimọ́ julọ wọnni: Nigbati ibudó ba si ṣí siwaju, Aaroni o wá, ati awọn ọmọ rẹ̀, nwọn o si bọ́ aṣọ-ikele rẹ̀ silẹ, nwọn o si fi i bò apoti ẹrí; Nwọn o fi awọ seali bò o, nwọn o si nà aṣọ kìki alaró bò o, nwọn o si tẹ̀ ọpá nì bọ̀ ọ. Ati lori tabili àkara ifihàn nì, ki nwọn ki o nà aṣọ alaró kan si, ki nwọn ki o si fi awopọkọ sori rẹ̀, ati ṣibi ati awokòto, ati ìgo ohun didà: ati àkara ìgbagbogbo nì ki o wà lori rẹ̀: Ki nwọn ki o si nà aṣọ ododó bò wọn, ki nwọn ki o si fi awọ seali bò o, ki nwọn ki o si tẹ̀ ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ. Ki nwọn ki o si mú aṣọ alaró kan, ki nwọn ki o si fi bò ọpá-fitila nì, ati fitila rẹ̀, ati alumagaji rẹ̀, ati awo alumagaji rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo oróro rẹ̀, eyiti nwọn fi nṣe iṣẹ rẹ̀. Ki nwọn ki o si fi on ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀ sinu awọ seali, ki nwọn ki o si gbé e lé ori igi. Ati lori pẹpẹ wurà ni ki nwọn ki o nà aṣọ alaró kan si, nwọn o si fi awọ seali bò o, nwọn o si tẹ̀ ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ. Ki nwọn ki o si kó gbogbo ohunèlo ìsin, ti nwọn fi nṣe iṣẹ-ìsin ninu ibi-mimọ́, ki nwọn ki o si fi wọn sinu aṣọ alaró kan, ki nwọn ki o si fi awọ seali bò wọn, ki nwon ki o si fi wọn kà ori igi. Ki nwọn ki o si kó ẽru kuro lori pẹpẹ, ki nwọn ki o si nà aṣọ elesè-aluko kan bò o. Ki nwọn ki o si fi gbogbo ohun-èlo rẹ̀ ti nwọn fi ṣe iṣẹ-ìsin rẹ̀ sori rẹ̀, awo iná, ati kọkọrọ ẹran, ati ọkọ́-ẽru, ati awokòto, ati gbogbo ohun-èlo pẹpẹ na; ki nwọn ki o si nà awọ seali sori rẹ̀, ki nwọn ki o si tẹ ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ. Nigbati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ ba pari ati bò ibi-mimọ́ na tán, ati gbogbo ohun-èlo ibi-mimọ́ na, nigbati ibudó yio ba ṣí siwaju; lẹhin eyinì, li awọn ọmọ Kohati yio wá lati gbé e: ṣugbọn nwọn kò gbọdọ fọwọkàn ohun mimọ́ kan, ki nwọn ki o má ba kú. Wọnyi li ẹrù awọn ọmọ Kohati ninu agọ́ ajọ. Ohun itọju Eleasari ọmọ Aaroni alufa si ni oróro fitila, ati turari didùn, ati ẹbọ ohunjijẹ ìgbagbogbo, ati oróro itasori, ati itọju agọ́ na gbogbo, ati ti ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, ninu ibi-mimọ́ nì, ati ohun-èlo rẹ̀ na. OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, Ẹ máṣe ke ẹ̀ya idile awọn ọmọ Kohati kuro lãrin awọn ọmọ Lefi: Ṣugbọn bayi ni ki ẹ ṣe fun wọn, ki nwọn ki o le yè, ki nwọn ki o má ba kú, nigbati nwọn ba sunmọ ohun mimọ́ julọ: ki Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ wọnú ilé, ki nwọn si yàn wọn olukuluku si iṣẹ rẹ̀ ati si ẹrù rẹ̀; Ṣugbọn nwọn kò gbọdọ wọle lọ lati wò ohun mimọ́ ni iṣẹju kan, ki nwọn ki o má ba kú. OLUWA si sọ fun Mose pe, Kà iye awọn ọmọ Gerṣoni pẹlu, gẹgẹ bi ile baba wọn, nipa idile wọn; Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ titi di ẹni ãdọta ọdún ni ki o kaye wọn; gbogbo awọn ti o wọnu-ile lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin, lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ. Eyi ni iṣẹ-ìsin idile awọn ọmọ Gerṣoni, lati sìn ati lati rù ẹrù: Awọn ni yio si ma rù aṣọ-ikele agọ́, ati agọ́ ajọ, ibori rẹ̀, ati ibori awọ seali ti mbẹ lori rẹ̀, ati aṣọ-tita fun ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ; Ati aṣọ-isorọ̀ ti agbalá, ati aṣọ-tita fun ẹnu-ọ̀na agbalá, ti mbẹ lẹba agọ́ ati lẹba pẹpẹ yiká, ati okùn wọn, ati gbogbo ohun-èlo iṣẹ-ìsin wọn, ati ohun gbogbo ti a ṣe fun wọn; bẹ̃ni nwọn o ma sìn. Nipa aṣẹ Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ̀ ni ki gbogbo iṣẹ-ìsin awọn ọmọ Gerṣoni jẹ́, ni gbogbo ẹrù wọn, ati ni gbogbo iṣẹ-ìsin wọn: ki ẹnyin si yàn wọn si itọju gbogbo ẹrù wọn. Eyi ni iṣẹ-ìsin idile awọn ọmọ Gerṣoni ninu agọ́ ajọ: ki itọju wọn ki o si wà li ọwọ́ Itamari ọmọ Aaroni alufa. Ati awọn ọmọ Merari, ki iwọ ki o kà wọn gẹgẹ bi idile wọn, nipa ile baba wọn; Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún ni ki iwọ ki o kà wọn, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ́. Eyi si ni itọju ẹrù wọn, gẹgẹ bi gbogbo iṣẹ-ìsin wọn ninu agọ́ ajo; awọn apáko agọ́, ati ọpá-idabu rẹ̀, ati opó rẹ̀, ati ìhò-ìtẹbọ rẹ̀, Ati opó agbalá yiká, ati ihò-ìtẹbọ wọn, ati ẽkàn wọn, ati okùn wọn, pẹlu ohun-èlo wọn gbogbo, ati pẹlu ohun-ìsin wọn gbogbo: li orukọ li orukọ ni ki ẹnyin ki o kà ohun-èlo ti iṣe itọju ẹrù wọn. Eyi ni iṣẹ-ìsin idile awọn ọmọ Merari, gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin wọn gbogbo, ninu agọ́ ajọ, labẹ Itamari ọmọ Aaroni alufa. Mose ati Aaroni ati awọn olori ijọ awọn enia si kà awọn ọmọ Kohati nipa idile wọn, ati gẹgẹ bi ile baba wọn, Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na fun iṣẹ ninu agọ́ ajọ: Awọn ti a si kà ninu wọn nipa idile wọn jẹ́ ẹgbẹrinla o din ãdọta. Wọnyi li awọn ti a kà ni idile awọn ọmọ Kohati, gbogbo awọn ti o le ṣe iṣẹ-ìsin ninu agọ́ ajọ, ti Mose ati Aaroni kà, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nipa ọwọ́ Mose. Awọn ti a si kà ninu awọn ọmọ Gerṣoni, nipa idile wọn, ati gẹgẹ bi ile baba wọn, Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na, fun iṣẹ ninu agọ́ ajọ, Ani awọn ti a kà ninu wọn, nipa idile wọn, gẹgẹ bi ile baba wọn, jẹ́ ẹgbẹtala o le ọgbọ̀n. Wọnyi li awọn ti a kà ni idile awọn ọmọ Gerṣoni, gbogbo awọn ti o ṣe iṣẹ-ìsin ninu agọ́ ajọ, ti Mose ati Aaroni kà gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA. Awọn ti a si kà ni idile awọn ọmọ Merari, nipa idile wọn, gẹgẹ bi ile baba wọn, Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin na, fun iṣẹ ninu agọ́ ajọ, Ani awọn ti a kà ninu wọn nipa idile wọn jẹ́ ẹgbẹrindilogun. Wọnyi li awọn ti a kà ninu idile awọn ọmọ Merari, ti Mose ati Aaroni kà gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nipa ọwọ́ Mose. Gbogbo awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Lefi, ti Mose ati Aaroni ati awọn olori Israeli kà, nipa idile wọn, ati gẹgẹ bi ile baba wọn, Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wá lati ṣe iṣẹ-ìsin, ati iṣẹ ẹrù ninu agọ́ ajọ, Ani awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgbẹtalelẹgbarin o din ogun. Gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA li a kà wọn nipa ọwọ́ Mose, olukuluku nipa iṣẹ-ìsin rẹ̀, ati gẹgẹ bi ẹrù rẹ̀: bẹ̃li a ti ọwọ́ rẹ̀ kà wọn, bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

Num 4:1-49 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé: “Ẹ ka iye àwọn ọmọ Kohati láàrin àwọn ọmọ Lefi, ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. Kí ẹ ka àwọn ọkunrin wọn, láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ. Àwọn ni yóo máa ṣe ìtọ́jú àwọn ohun mímọ́ jùlọ ninu Àgọ́ Àjọ. “Nígbà tí ẹ bá fẹ́ kó kúrò ní ibùdó kan, Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo wá láti ṣí aṣọ ìbòjú tí ó wà níwájú Àpótí majẹmu, wọn yóo sì fi bo Àpótí náà. Lẹ́yìn èyí, wọn óo fi awọ dídán bò ó, wọn óo tẹ́ aṣọ aláwọ̀ aró lé e, wọn yóo sì ti ọ̀pá tí a fi ń gbé e bọ̀ ọ́. “Wọn yóo da aṣọ aláwọ̀ aró bo tabili tí burẹdi ìfihàn máa ń wà lórí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọn yóo kó àwọn nǹkan wọnyi lé e lórí: àwọn àwo turari, àwọn àwokòtò, ati àwọn ìgò fún ọtí ìrúbọ. Burẹdi ìfihàn sì gbọdọ̀ wà lórí rẹ̀ nígbà gbogbo. Lẹ́yìn náà, wọn yóo da aṣọ pupa ati awọ dídán bò ó. Wọn yóo sì ti igi tí a fi ń gbé e bọ̀ ọ́. “Wọn yóo fi aṣọ aláwọ̀ aró bo ọ̀pá fìtílà ati àwọn fìtílà rẹ̀ ati àwọn ohun tí à ń lò pẹlu rẹ̀ ati gbogbo ohun èlò òróró. Wọn yóo sì fi awọ dídán dì wọ́n, wọn yóo sì gbé wọn ka orí igi tí a óo fi gbé wọn. “Lẹ́yìn èyí, wọn óo da aṣọ aláwọ̀ aró bo pẹpẹ wúrà, wọn óo fi awọ ewúrẹ́ tí ń dán bò ó, wọn óo sì ti igi tí a fi ń gbé e bọ̀ ọ́. Wọn yóo di àwọn ohun èlò ìsìn yòókù sinu aṣọ aláwọ̀ aró kan, wọn yóo sì fi awọ ewúrẹ́ tí ń dán bò wọ́n, wọn óo gbé wọn ka orí igi tí a óo fi gbé wọn. Wọn óo kó eérú kúrò lórí pẹpẹ, wọn óo fi aṣọ elése àlùkò bò ó. Wọn óo kó gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀ sórí rẹ̀, àwọn àwo turari, àmúga tí a fi ń mú ẹran, ọkọ́ tí a fi ń kó eérú, àwo kòtò ati gbogbo ohun èlò tí ó jẹ mọ́ pẹpẹ náà, wọn óo fi awọ ewúrẹ́ bò wọ́n, wọn óo sì ti ọ̀pá tí a fi ń gbé e bọ̀ ọ́. Nígbà tí ó bá tó àkókò láti tẹ̀síwájú, àwọn ìdílé Kohati yóo wá láti kó àwọn ohun èlò ibi mímọ́ lẹ́yìn tí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ bá ti bò wọ́n tán. Wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan àwọn nǹkan mímọ́ náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kàn án yóo kú. “Eleasari ọmọ Aaroni Alufaa ni yóo ṣe ìtọ́jú òróró fìtílà, ati turari olóòórùn dídùn, ẹbọ ohun jíjẹ ati òróró ìyàsímímọ́, ati gbogbo Àgọ́ náà. Yóo máa ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́ ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ ati àwọn ohun èlò ibẹ̀.” OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé, “Ẹ má jẹ́ kí ìdílé Kohati parun láàrin ẹ̀yà Lefi, ohun tí ẹ óo ṣe sí wọn nìyí kí wọ́n má baà kú: nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ àwọn ohun mímọ́ jùlọ, Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo wọ inú ibi mímọ́ lọ, wọn yóo sì sọ ohun tí olukuluku wọn yóo ṣe fún wọn, ati ẹrù tí olukuluku wọn yóo gbé. Àwọn ìdílé Kohati kò gbọdọ̀ wọ inú ibi mímọ́ láti yọjú wo àwọn ohun mímọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá yọjú wò wọ́n yóo kú.” OLUWA sọ fún Mose pé, “Ka iye àwọn ọmọ Geriṣoni ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn: ka àwọn ọkunrin wọn láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ. Iṣẹ́ ìsìn ti àwọn ọmọ Geriṣoni nìyí: Àwọn ni yóo máa ru àwọn aṣọ ìkélé tí a fi ṣe ibi mímọ́, ati Àgọ́ Àjọ pẹlu àwọn ìbòrí rẹ̀, ati awọ ewúrẹ́ tí ń dán tí wọn fi bò ó, ati aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Aṣọ ìkélé ti àgbàlá tí ó yí ibi mímọ́ ati pẹpẹ ká, aṣọ ìkélé fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá, ati okùn wọn, ati gbogbo àwọn ohun tí wọn ń lò pẹlu wọn. Àwọn ni wọn óo máa ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ tí ó bá jẹ mọ́ àwọn nǹkan wọnyi. Kí Mose yan àwọn ọmọ Geriṣoni sí ìtọ́jú àwọn ẹrù, kí ó sì rí i pé wọ́n ṣe gbogbo ohun tí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ bá pa láṣẹ fún wọn nípa iṣẹ́ wọn. Iṣẹ́ àwọn ọmọ Geriṣoni ninu Àgọ́ Àjọ nìyí, Itamari ọmọ Aaroni alufaa ni yóo jẹ́ alabojuto wọn.” OLUWA sọ fún Mose pé, “Ka iye àwọn ọmọ Merari ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. Kí o ka àwọn ọkunrin wọn láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ. Àwọn ọmọ Merari ni yóo máa ru àwọn igi férémù Àgọ́, àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀ ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọn òpó àyíká àgbàlá ati ìtẹ́lẹ̀ wọn, àwọn èèkàn àgọ́, okùn wọn, ati gbogbo ohun tí wọn ń lò pẹlu wọn. Olukuluku yóo sì mọ ẹrù tirẹ̀. Iṣẹ́ àwọn ọmọ Merari ninu Àgọ́ Àjọ nìyí. Itamari ọmọ Aaroni alufaa ni yóo jẹ́ alabojuto wọn.” Mose, Aaroni ati àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli ka àwọn ọmọ Kohati ní ìdílé-ìdílé gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. Láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé ẹni aadọta ọdún, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ. Iye wọ́n jẹ́ ẹgbẹrinla ó dín aadọta (2,750). Iye àwọn tí Mose ati Aaroni kà ninu àwọn ọmọ Kohati nìyí, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún wọn. Iye àwọn ọmọ Geriṣoni ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn, láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ jẹ́ ẹgbẹtala ó lé ọgbọ̀n (2,630). Èyí ni iye àwọn tí Mose ati Aaroni kà ninu àwọn ọmọ Geriṣoni tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún wọn. Àwọn tí a kà ninu àwọn ọmọ Merari, ní ìdílé-ìdílé gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn, láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta ọdún, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ jẹ́ ẹgbẹrindinlogun (3,200). Èyí ni iye àwọn tí Mose ati Aaroni kà ninu àwọn ọmọ Merari gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún wọn. Gbogbo àwọn tí Mose, Aaroni ati àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli kà ninu àwọn ọmọ Lefi ní ìdílé-ìdílé gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn, láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta ọdún, gbogbo àwọn tí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ ìsìn ati iṣẹ́ ẹrù rírù ninu Àgọ́ Àjọ jẹ́ ẹgbaarin ó lé ẹgbẹta ó dín ogún (8,580). Mose ka àwọn eniyan náà, ó sì yan iṣẹ́ fún olukuluku wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún un.

Num 4:1-49 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA sọ fún Mose àti Aaroni pé: “Ka iye àwọn ọmọ Kohati láàrín àwọn ọmọ Lefi nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn. Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé. “Wọ̀nyí ni iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Kohati nínú àgọ́ àjọ, láti tọ́jú àwọn ohun èlò mímọ́ jùlọ. Nígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀síwájú, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò wọ inú rẹ̀, wọn yóò sí aṣọ ìbòrí rẹ̀, wọn yóò sì fi bo àpótí ẹ̀rí. Wọn yóò sì fi awọ ewúrẹ́ bò ó, lórí awọ ewúrẹ́ yìí ni wọn ó tẹ̀ bọ ààyè rẹ̀. “Lórí tábìlì àkàrà ìfihàn ni kí wọn ó na aṣọ aláró kan sí, kí wọn kí ó sì fi àwopọ̀kọ́ sórí rẹ̀, àti ṣíbí àti àwokòtò àti ìgò fún ọrẹ ohun mímu; àti àkàrà ìgbà gbogbo ní kí ó wà lórí rẹ̀. Lórí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọn yóò da, wọn ó tún fi awọ ewúrẹ́ bò ó, wọn ó sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀. “Kí wọn kí ó sì mú aṣọ aláwọ̀ aláró kan, kí wọn kí ó sì fi bo ọ̀pá fìtílà àti fìtílà rẹ̀, àti alumagaji rẹ̀, àti àwo alumagaji rẹ̀, àti gbogbo ohun èlò òróró rẹ̀, èyí tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀. Kí wọn ó fi awọ ẹran yí fìtílà àti gbogbo ohun èlò rẹ, kí wọn kí ó sì gbé e lé orí férémù tí wọn yóò fi gbé e. “Ní orí pẹpẹ wúrà ni kí wọn ó tẹ́ aṣọ aláró kan sí, wọn yóò sì fi awọ seali bò ó, kí wọ́n sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀. “Kí wọn kó gbogbo ohun èlò tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ ìsìn ní ibi mímọ́, kí wọn ó fi aṣọ aláwọ̀ búlúù yìí, kí wọn ó sì fi awọ seali bò ó, kí wọn ó sì fi gbé wọn ka orí férémù. “Kí wọn ó kó eérú kúrò lórí pẹpẹ idẹ, kí wọn ó sì tẹ́ aṣọ aláwọ̀ àlùkò lé e lórí. Nígbà náà ni kí wọn ó kó gbogbo ohun èlò fún iṣẹ́ ìsìn níbi pẹpẹ, títí dórí àwo iná, fọ́ọ̀kì ẹran, ọkọ́ eérú àti àwokòtò. Kí wọn ó fi awọ ewúrẹ́ bo gbogbo rẹ̀, kí wọn ó sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀. “Lẹ́yìn tí Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti parí bíbo ibi mímọ́ àti gbogbo ohun èlò ibi mímọ́, nígbà tí àgọ́ bá sì ṣetán láti tẹ̀síwájú, kí àwọn ọmọ Kohati bọ́ síwájú láti gbé e, ṣùgbọ́n wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ohun mímọ́ kankan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ wọn ó kú. Àwọn ọmọ Kohati ni yóò gbé gbogbo ohun tó wà nínú àgọ́ ìpàdé. “Iṣẹ́ Eleasari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ni ṣíṣe àbojútó òróró fìtílà, tùràrí dídùn, ẹbọ ohun jíjẹ ìgbà gbogbo àti òróró ìtasórí: Kí ó jẹ́ alábojútó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ àgọ́ àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò ibi mímọ́.” OLúWA sọ fún Mose àti Aaroni pé, “Rí i pé a kò gé ẹ̀yà Kohati kúrò lára àwọn ọmọ Lefi: Nítorí kí wọ́n lè yè, kí wọ́n má ba à kú nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ tòsí àwọn ohun mímọ́ jùlọ: Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni kí ó wọ ibi mímọ́ láti pín iṣẹ́ oníkálùkù àti àwọn ohun tí wọn yóò gbé. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Kohati kò gbọdọ̀ wọlé láti wo àwọn ohun mímọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ ìṣẹ́jú kan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò kú.” OLúWA sọ fún Mose pé: “Tún ka iye àwọn ọmọ Gerṣoni nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn. Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. “Èyí ni iṣẹ́ ìsìn ìdílé àwọn ọmọ Gerṣoni, bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ àti ní ẹrù rírù: Àwọn ni yóò máa ru àwọn aṣọ títa ti àgọ́, ti àgọ́ ìpàdé àti ìbòrí rẹ̀, àti awọ ewúrẹ́ tí a fi bò ó, aṣọ títa ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, Aṣọ títa ti àgbàlá tó yí àgọ́ àti pẹpẹ ká, aṣọ títa ti ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé sí àgbàlá, okùn àti àwọn ohun èlò iṣẹ́ ìsìn, àti ohun gbogbo tí à ń lò fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn ó máa sìn. Àwọn ọmọ Gerṣoni ni yóò ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ pẹ̀lú àwọn nǹkan wọ̀nyí. Gbogbo iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Gerṣoni yálà ni iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ní ẹrù rírù ni, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóò máa darí wọn; ìwọ ni kí o sì yàn ẹrù tí oníkálùkù yóò rù fún un. Èyí ni iṣẹ́ ìdílé àwọn Gerṣoni ni àgọ́ ìpàdé Itamari, ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ni yóò sì jẹ alábojútó iṣẹ́ wọn. “Ka iye àwọn ọmọ Merari nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn. Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. Iṣẹ́ tí wọn yóò sì máa ṣe nínú àgọ́ ìpàdé nìyìí: gbígbẹ́ àwọn férémù àgọ́, pákó ìdábùú rẹ̀, òpó àti ihò òpó rẹ̀, Pẹ̀lú gbogbo òpó tó yí àgbàlá ká àti ohun èlò tó jẹ mọ́ lílò wọn kí o sì yan ohun tí oníkálùkù yóò rù fún un; Èyí ni iṣẹ́ ìsìn ìdílé àwọn ọmọ Merari, bí wọn yóò ti máa ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé lábẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà.” Mose àti Aaroni pẹ̀lú àwọn olórí ìjọ ènìyàn ka àwọn ọmọ Kohati nípa ìdílé àti ilé baba wọn. Gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ ìpàdé. Iye wọn nípa ìdílé jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlá ó-dínàádọ́ta (2,750). Èyí ni àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Kohati tó ń ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé; tí Mose àti Aaroni kà gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pa á láṣẹ fún Mose. Wọ́n ka àwọn ọmọ Gerṣoni nípa ìdílé àti ilé baba wọn. Gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta, gbogbo àwọn tó lè ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. Iye wọn nípa ìdílé àti ilé baba wọn jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá ó-lé-ọgbọ̀n (2,630). Èyí jẹ́ àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Gerṣoni, àwọn tó ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. Mose àti Aaroni ṣe bí àṣẹ OLúWA. Wọ́n ka àwọn ọmọ Merari nípa ìdílé àti ilé baba wọn. Gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, àwọn tó ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. Iye wọn nípa ìdílé àti ilé baba wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rìndínlógún (3,200). Èyí ni àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Merari. Mose àti Aaroni kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLúWA láti ẹnu Mose. Gbogbo àwọn tí a kà nínú àwọn ọmọ Lefi, ti Mose àti Aaroni àti àwọn olórí Israẹli kà, nípa ìdílé wọn àti gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. Gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn tó sì ń ru àwọn ẹrù inú Àgọ́ Ìpàdé. Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá lé lẹ́gbàarin ó dín ogún (8,580). Wọ́n yan iṣẹ́ àti àwọn ohun tí ẹni kọ̀ọ̀kan yóò máa gbé fún un gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pàṣẹ láti ẹnu Mose.