Num 4:1-3 - Compare All Versions
Num 4:1-3 YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si sọ fun Mose ati Aaroni pe, Kà iye awọn ọmọ Kohati kuro ninu awọn ọmọ Lefi, nipa idile wọn, ile baba wọn, Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin, lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ.
Pín
Num 4 YBCVNum 4:1-3 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLúWA sọ fún Mose àti Aaroni pé, “Ka iye àwọn ọmọ Kohati láàrín àwọn ọmọ Lefi nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn. Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé.
Pín
Num 4 BMYONum 4:1-3 YCE (Yoruba Bible)
OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé: “Ẹ ka iye àwọn ọmọ Kohati láàrin àwọn ọmọ Lefi, ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. Kí ẹ ka àwọn ọkunrin wọn, láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ.
Pín
Num 4 YCE