Num 35:1-8
Num 35:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si sọ fun Mose ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko, wipe, Paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o fi ilu fun awọn ọmọ Lefi ninu ipín ilẹ-iní wọn, lati ma gbé; ki ẹnyin ki o si fi ẹbẹba-ilu fun awọn ọmọ Lefi ni ilu wọnni yi wọn ká. Ki nwọn ki o ní ilu lati ma gbé; ati ẹbẹba-ilu wọn fun ohunọ̀sin wọn, ati fun ohun-iní wọn, ati fun gbogbo ẹran wọn. Ati ẹbẹba-ilu, ti ẹnyin o fi fun awọn ọmọ Lefi, lati odi ilu lọ sẹhin rẹ̀ ki o jẹ́ ẹgbẹrun igbọnwọ yiká. Ki ẹnyin ki o si wọ̀n lati ẹhin ode ilu na lọ ni ìha ìla-õrùn ẹgba igbọnwọ, ati ni ìha gusù ẹgba igbọnwọ, ati ni ìha ìwọ-õrùn ẹgba igbọnwọ, ati ni ìha ariwa ẹgba igbọnwọ; ki ilu na ki o si wà lãrin. Eyi ni yio si ma ṣe ẹbẹba-ilu fun wọn. Ati ninu ilu ti ẹnyin o fi fun awọn ọmọ Lefi, mẹfa o jẹ́ ilu àbo, ti ẹnyin o yàn fun aṣi-enia-pa, ki o le ma salọ sibẹ̀: ki ẹnyin ki o si fi ilu mejilelogoji kún wọn. Gbogbo ilu ti ẹnyin o fi fun awọn ọmọ Lefi ki o jẹ́ mejidilãdọta: wọnyi ni ki ẹnyin fi fun wọn pẹlu ẹbẹba wọn. Ati ilu ti ẹnyin o fi fun wọn, ki o jẹ́ ninu ilẹ-iní awọn ọmọ Israeli, lọwọ ẹniti o ní pupọ̀ lí ẹnyin o gbà pupọ̀; ṣugbọn lọwọ ẹniti o ní diẹ li ẹnyin o gbà diẹ: ki olukuluku ki o fi ninu ilu rẹ̀ fun awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ilẹ-iní rẹ̀ ti o ní.
Num 35:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní ìhà ìlà oòrùn Jọdani ní òdìkejì Jẹriko, OLUWA sọ fún Mose pé, “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé ninu ilẹ̀ ìní wọn, kí wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi ní àwọn ìlú tí wọn yóo máa gbé, kí wọ́n sì fún wọn ní ilẹ̀ pápá yíká àwọn ìlú wọnyi. Àwọn ìlú náà yóo jẹ́ ti àwọn ọmọ Lefi, wọn óo máa gbébẹ̀. Ilẹ̀ tí ó yí àwọn ìlú náà ká yóo wà fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ati mààlúù wọn. Kí ilẹ̀ pápá tí yóo yí àwọn ìlú tí ẹ óo fún àwọn ọmọ Lefi ká jẹ́ ẹgbẹrun igbọnwọ láti ibi odi ìlú wọn siwaju. Lẹ́yìn odi ìlú kọ̀ọ̀kan, kí ẹ wọn ẹgbaa igbọnwọ ní ìhà kọ̀ọ̀kan ní ìhà ìlà oòrùn, ati ìhà gúsù, ati ìhà ìwọ̀ oòrùn, ati ìhà àríwá; kí ìlú wà ní ààrin. Ilẹ̀ tí ẹ wọ̀n yìí ni yóo jẹ́ ibùjẹ fún àwọn ẹran ọ̀sìn. Ninu àwọn ìlú tí ẹ óo fún àwọn ọmọ Lefi, mẹfa ninu wọn yóo jẹ́ ìlú ààbò tí ẹni tí ó bá ṣèèṣì paniyan lè sá lọ. Lẹ́yìn ìlú mẹfa yìí, ẹ óo tún fún wọn ní ìlú mejilelogoji pẹlu ilẹ̀ tí ó yí wọn ká. Gbogbo ìlú tí ẹ óo fún wọn yóo jẹ́ mejidinlaadọta pẹlu ilẹ̀ pápá tí ó yí wọn ká. Bí ilẹ̀ ìní olukuluku ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli bá ti tóbi tó, bẹ́ẹ̀ ni iye ìlú tí wọn yóo fi sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Lefi yóo pọ̀ tó.”
Num 35:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní Jordani tí ó rékọjá láti Jeriko, OLúWA sọ fún Mose pé, “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli láti fún àwọn Lefi ní ilẹ̀ láti gbé lára ogún tí àwọn ọmọ Israẹli yóò jogún. Kí ẹ sì fún wọn ní ilẹ̀ lára pápá oko tútù, káàkiri ìlú. Nígbà náà, wọn yóò ní ìlú tí wọn yóò gbé àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún ẹran ọ̀sìn, ọ̀wọ́ ẹran pẹ̀lú gbogbo ìní wọn. “Ilẹ̀ pápá oko tútù káàkiri ìlú tí ẹ ó fi fún àwọn ọmọ Lefi, wíwọ̀n rẹ̀ yóò jẹ́ ẹgbàá ìgbọ̀nwọ́ (1,500) ẹsẹ̀ bàtà láti ògiri ìlú náà. Lẹ́yìn náà, wọn ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) ẹsẹ̀ bàtà lápá ibi ìhà ìlà-oòrùn ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) ẹsẹ̀ bàtà ní ìhà gúúsù, ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, àríwá. Pẹ̀lú ìlú ní àárín. Wọn yóò ní agbègbè yìí gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ pápá oko tútù fún ìlú náà. “Mẹ́fà lára ìlú tí ẹ fún àwọn ọmọ Lefi yóò jẹ́ ìlú ibi ìsásí, tí ẹni tí ó bá pa ènìyàn yóò sá sí. Ní àfikún, ẹ fún wọn ní méjìlélógójì (42) ìlú sí i. Ní gbogbo rẹ̀, kí ẹ fún àwọn ọmọ Lefi ní méjì-dínláàádọ́ta (48) ìlú lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn. Ìlú tí ẹ fún àwọn ọmọ Lefi láti ara ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli jogún, olúkúlùkù kí ó fi nínú ìlú rẹ̀ fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní rẹ̀ tí ó ní. Gba púpọ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní púpọ̀ àti díẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní díẹ̀.”