Num 30:1-16

Num 30:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

MOSE si sọ fun awọn olori awọn ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli, wipe, Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ. Bi ọkunrin kan ba jẹ́ ẹjẹ́ fun OLUWA, tabi ti o ba bura lati fi dè ara rẹ̀ ni ìde, ki on ki o máṣe bà ọ̀rọ rẹ̀ jẹ; ki on ki o ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ti ẹnu rẹ̀ jade. Bi obinrin kan pẹlu ba si jẹ́ ẹjẹ́ fun OLUWA, ti o si dè ara rẹ̀ ni ìde, ni ile baba rẹ̀ ni ìgba ewe rẹ̀; Ti baba rẹ̀ si gbọ́ ẹjẹ́ rẹ̀, ati ìde rẹ̀ ti o fi dè ara rẹ̀, ti baba rẹ̀ ba si pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si i; njẹ ki gbogbo ẹjẹ́ rẹ̀ ki o duro, ati gbogbo ìde ti o fi dè ara rẹ̀ yio si duro. Ṣugbọn bi baba rẹ̀ ba kọ̀ fun u li ọjọ́ na ti o gbọ́; kò sí ọkan ninu ẹjẹ́ rẹ̀, tabi ninu ìde ti o fi dè ara rẹ̀, ti yio duro: OLUWA yio si darijì i, nitoriti baba rẹ̀ kọ̀ fun u. Bi o ba si kúku li ọkọ, nigbati o jẹ́ ẹjẹ́, tabi ti o sọ̀rọ kan lati ẹnu rẹ̀ jade, ninu eyiti o fi dè ara rẹ̀ ni ìde; Ti ọkọ rẹ̀ si gbọ́, ti o si pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si i li ọjọ́ na ti o gbọ́; njẹ ẹjẹ́ rẹ̀ yio duro, ìde ti o fi dè ara rẹ̀ yio si duro. Ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba kọ̀ fun u li ọjọ́ na ti o gbọ́; njẹ on o mu ẹjẹ́ rẹ̀ ti o jẹ́ ati ohun ti o ti ẹnu rẹ̀ jade, eyiti o fi dè ara rẹ̀ dasan: OLUWA yio si darijì i. Ṣugbọn gbogbo ẹjẹ́ opó, ati ti obinrin ti a kọ̀silẹ, ti nwọn fi dè ara wọn, yio wà lọrùn rẹ̀. Bi o ba si jẹjẹ́ ni ile ọkọ rẹ̀, tabi ti o si fi ibura dè ara rẹ̀ ni ìde, Ti ọkọ rẹ̀ si gbọ́, ti o si pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si i, ti kò si kọ̀ fun u: njẹ gbogbo ẹjẹ́ rẹ̀ ni yio duro, ati gbogbo ìde ti o fi dè ara rẹ̀ yio si duro. Ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba sọ wọn dasan patapata li ọjọ́ na ti o gbọ́; njẹ ohunkohun ti o ti ẹnu rẹ̀ jade nipasẹ̀ ẹjẹ́ rẹ̀, tabi nipasẹ̀ ìde ọkàn rẹ̀, ki yio duro: ọkọ rẹ̀ ti sọ wọn dasan; OLUWA yio si darijì i. Gbogbo ẹjẹ́ ati ibura ìde lati fi pọ́n ara loju, ọkọ rẹ̀ li o le mu u duro, o si le sọ ọ dasan. Ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si i patapata lati ọjọ́ dé ọjọ́; njẹ o fi mu gbogbo ẹjẹ́ rẹ̀ duro, tabi gbogbo ìde rẹ̀ ti mbẹ lara rẹ̀; o mu wọn duro, nitoriti o pa ẹnu rẹ̀ mọ si i li ọjọ́ na ti o gbọ́. Ṣugbọn bi o ba sọ wọn dasan, lẹhin igbati o gbọ́; njẹ on ni yio rù ẹ̀ṣẹ obinrin na. Wọnyi ni ìlana ti OLUWA palaṣẹ fun Mose, lãrin ọkunrin ati aya rẹ̀, lãrin baba ati ọmọbinrin rẹ̀, ti iṣe ewe ninu ile baba rẹ̀.

Num 30:1-16 Yoruba Bible (YCE)

Mose sọ fún àwọn olórí àwọn ẹ̀yà Israẹli àwọn ohun tí OLUWA pa láṣẹ: Bí ọmọkunrin kan bá bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ tabi tí ó ṣe ìlérí láti yẹra fún ohunkohun, kò gbọdọ̀ yẹ ọ̀rọ̀ rẹ̀, bí ó ti wí ni ó gbọdọ̀ ṣe. Bí ọdọmọbinrin kan, tí ń gbé ilé baba rẹ̀ bá bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ tabi tí ó ṣe ìlérí láti yẹra fún ohunkohun, ó gbọdọ̀ ṣe bí ó ti wí, àfi bí baba rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà ati ìlérí tí ó ṣe. Bí baba rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà ati ìlérí tí ó ṣe, nígbà tí ó gbọ́ ọ, ọdọmọbinrin náà kò ní san ẹ̀jẹ́ náà, OLUWA yóo dáríjì í nítorí pé baba rẹ̀ ni kò gbà á láàyè láti san ẹ̀jẹ́ rẹ̀. Bí ọmọbinrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́, bóyá ó ti ọkàn rẹ̀ wá tabi kò ti ọkàn rẹ̀ wá, tí ó sì lọ ilé ọkọ lẹ́yìn ẹ̀jẹ́ tí ó jẹ́, ó níláti ṣe gbogbo ohun tí ó ti jẹ́jẹ̀ẹ́, àfi bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà ní ọjọ́ tí ó gbọ́ ọ. Bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà, ọmọbinrin náà kò ní san ẹ̀jẹ́ náà. OLUWA yóo dáríjì í nítorí pé ọkọ rẹ̀ ni kò gbà á láàyè láti san ẹ̀jẹ́ rẹ̀. Obinrin tí ó bá jẹ́ opó ati obinrin tí ó ti kọ ọkọ rẹ̀ gbọdọ̀ san ẹ̀jẹ́ wọn. Wọ́n sì gbọdọ̀ yẹra fún ohun gbogbo tí wọn bá ṣe ìlérí láti yẹra fún. Bí obinrin tí ó ní ọkọ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ tabi tí ó bá ṣe ìlérí láti yẹra fún ohunkohun, ó gbọdọ̀ san ẹ̀jẹ́ rẹ̀, àfi bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí i nígbà tí ó gbọ́. Bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà, obinrin náà kò ní san ẹ̀jẹ́ náà. OLUWA yóo dáríjì í nítorí pé ọkọ rẹ̀ ni kò gbà á láàyè láti san ẹ̀jẹ́ rẹ̀. Ọkọ rẹ̀ ní àṣẹ láti gbà á láàyè láti san ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tabi kí ó kọ̀ fún un láti san án. Ṣugbọn bí ọkọ rẹ̀ kò bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà ní ọjọ́ tí ó gbọ́, ó níláti san gbogbo ẹ̀jẹ́ rẹ̀ nítorí pé ọkọ rẹ̀ kò lòdì sí i. Ṣugbọn bí ọkọ rẹ̀ bá lòdì sí ẹ̀jẹ́ náà lẹ́yìn èyí, ọkọ náà ni yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ obinrin náà nítorí pé kò jẹ́ kí ó san ẹ̀jẹ́ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ìlànà tí OLUWA pa láṣẹ fún Mose láàrin ọkọ ati aya ati láàrin baba ati ọmọ rẹ̀ obinrin, tí ń gbé ninu ilé rẹ̀.

Num 30:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Mose sì sọ fún olórí àwọn ẹ̀yà ọmọ Israẹli pé: “Èyí ni ohun tí OLúWA pàṣẹ: Nígbà tí ọkùnrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí OLúWA tàbí búra láti fi de ara rẹ̀ ní ìdè kí òun má bà ba ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ kí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sọ. “Nígbà tí ọmọbìnrin kan bá sì wà ní ilé baba rẹ̀ tó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLúWA tàbí búra láti fi de ara rẹ̀ tí baba rẹ̀ bá sì gbọ́ ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí ìdè rẹ̀ tí kò sì sọ nǹkan kan sí i, kí gbogbo ẹ̀jẹ́ rẹ̀ kí ó dúró àti gbogbo ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ yóò sì dúró. Ṣùgbọ́n tí baba rẹ̀ bá kọ̀ fun un ní ọjọ́ tí ó gbọ́, kò sí ọ̀kan nínú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí nínú ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ tí yóò dúró; OLúWA yóò sì tú u sílẹ̀ nítorí baba rẹ̀ kọ̀ fún un. “Tí ó bá sì ní ọkọ lẹ́yìn ìgbà tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ tàbí lẹ́yìn ìgbà tí ó sọ ọ̀rọ̀ kan láti ẹnu rẹ̀ jáde nínú èyí tí ó fi de ara rẹ̀ ní ìdè, Tí ọkọ rẹ̀ sì gbọ́ nípa èyí ṣùgbọ́n tí kò sọ nǹkan kan, nígbà náà ni ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ tó dúró. Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ bá kọ̀ nígbà tí ó gbọ́, ǹjẹ́ òun yóò mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ́ àti ohun tí ó ti ti ẹnu rẹ̀ jáde, èyí tí ó fi de ara rẹ̀ dasán, OLúWA yóò sì dáríjì í. “Ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ́ kí ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè kí ìdè tí opó tàbí obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀ bá ṣe yóò wà lórí rẹ̀. “Bí obìnrin tí ó ń gbé pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ tàbí de ara rẹ̀ ní ìdè lábẹ́ ìbúra, tí ọkọ rẹ̀ bá sì gbọ́, ṣùgbọ́n tí kò sọ̀rọ̀, tí kò sì kọ̀, nígbà náà ni ẹ̀jẹ́ rẹ̀ yóò dúró. Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ bá sọ wọ́n dasán, nígbà tí ó gbọ́, nígbà náà kò sí ẹ̀jẹ́ tàbí ìdè tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde tí yóò dúró, ọkọ rẹ̀ ti sọ wọ́n dasán, OLúWA yóò tú u sílẹ̀. Ọkọ rẹ̀ lè ṣe ìwádìí tàbí sọ ọ́ dasán ẹ̀jẹ́ tàbí ìbúra ìdè tí ó ti ṣe láti fi de ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ kò bá sọ nǹkan kan sí í nípa rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́, nígbà náà ni ó ṣe ìwádìí nípa ẹ̀jẹ́ àti ìbúra ìdè tí ó dè é. Kí ọkùnrin náà ṣe ìwádìí lórí rẹ̀ láìsọ nípa rẹ̀ si nígbà tí ó gbọ́ nípa rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, bí ọkùnrin náà bá sọ ọ́ dasán, ní àkókò kan lẹ́yìn tí ó ti gbọ́ wọn, nígbà náà ó jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà.” Èyí ni ìlànà tí OLúWA fún Mose nípa ìbátan láàrín ọkùnrin àti obìnrin àti láàrín baba àti ọ̀dọ́mọbìnrin rẹ̀ tí ó sì ń gbé ní ilé rẹ̀.