Num 3:1-39
Num 3:1-39 Bibeli Mimọ (YBCV)
WỌNYI si li awọn iran Aaroni ati Mose li ọjọ́ ti OLUWA bá Mose sọ̀rọ li òke Sinai. Wọnyi si li orukọ awọn ọmọ Aaroni; Nadabu akọ́bi, ati Abihu, Eleasari, ati Itamari. Wọnyi li orukọ awọn ọmọ Aaroni, awọn alufa ti a ta oróro si wọn li ori, ẹniti o yàsọtọ lati ma ṣe iranṣẹ ni ipò iṣẹ alufa. Nadabu ati Abihu si kú niwaju OLUWA, nigbati nwọn rubọ iná àjeji niwaju OLUWA ni ijù Sinai, nwọn kò si lí ọmọ: ati Eleasari ati Itamari nṣe iṣẹ alufa niwaju Aaroni baba wọn. OLUWA si sọ fun Mose pe, Mú ẹ̀ya Lefi sunmọtosi, ki o si mú wọn wá siwaju Aaroni alufa, ki nwọn le ma ṣe iranṣẹ fun u. Ki nwọn ki o ma pa aṣẹ rẹ̀ mọ́, ati aṣẹ gbogbo ajọ niwaju agọ́ ajọ, lati ṣe iṣẹ-ìsin agọ́. Ki nwọn ki o si ma pa gbogbo ohun-èlo agọ́ ajọ mọ́, ati aṣẹ awọn ọmọ Israeli, lati ṣe iṣẹ-ìsin agọ́. Ki iwọ ki o si fi awọn ọmọ Lefi fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀: patapata li a fi wọn fun u ninu awọn ọmọ Israeli. Ki iwọ ki o si yàn Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, ki nwọn ki o si ma duro si iṣẹalufa wọn: alejò ti o ba si sunmọtosi pipa ni ki a pa a. OLUWA si sọ fun Mose pe, Ati emi, kiyesi i, emi ti gbà awọn ọmọ Lefi kuro lãrin awọn ọmọ Israeli ni ipò gbogbo akọ́bi ti o ṣí inu ninu awọn ọmọ Israeli; nitorina ti emi li awọn ọmọ Lefi iṣe: Nitoripe ti emi ni gbogbo akọ́bi; nitoripe li ọjọ́ na ti mo kọlù gbogbo akọ́bi ni ilẹ Egipti, ni mo yà gbogbo akọ́bi sọ̀tọ fun ara mi ni Israeli, ati enia ati ẹran: ti emi ni nwọn o ma ṣe: Emi li OLUWA. OLUWA si sọ fun Mose ni ijù Sinai pe, Kaye awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ile baba wọn, nipa idile wọn: gbogbo ọkunrin lati ẹni oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, ni ki iwọ ki o kà wọn. Mose si kà wọn gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA, bi a ti paṣẹ fun u. Wọnyi si ni awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi orukọ wọn; Gerṣoni, ati Kohati, ati Merari. Wọnyi si ni orukọ awọn ọmọ Gerṣoni gẹgẹ bi idile wọn; Libni ati Ṣimei. Ati awọn ọmọ Kohati gẹgẹ bi idile wọn: Amramu, ati Ishari, Hebroni, ati Usieli. Ati awọn ọmọ Merari gẹgẹ bi idile wọn; Mali, ati Muṣi. Wọnyi ni awọn idile Lefi gẹgẹ bi ile baba wọn. Ti Gerṣoni ni idile awọn ọmọ Libni, ati idile awọn ọmọ Ṣimei; wọnyi ni idile awọn ọmọ Gerṣoni. Awọn ti a kà ninu wọn, gẹgẹ bi iye gbogbo awọn ọkunrin, lati ẹni oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, ani iye awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgbata o le ẹdẹgbẹjọ. Awọn idile awọn ọmọ Gerṣoni ni ki o dó lẹhin agọ́ ni ìha ìwọ-õrùn. Ati Eliasafu ọmọ Laeli ni ki o ṣe olori ile baba awọn ọmọ Gerṣoni. Ati itọju awọn ọmọ Gerṣoni ninu agọ́ ajọ ni, Agọ́, ibori rẹ̀, ati aṣọ-isorọ̀ ti ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, Ati aṣọ isorọ̀ ti agbalá, ati aṣọtita ti ẹnu-ọ̀na agbalá, ti mbẹ lẹba agọ́, ati lẹba pẹpẹ yiká, ati okùn rẹ̀ fun gbogbo iṣẹ-ìsin rẹ̀. Ati ti Kohati ni idile awọn ọmọ Amramu, ati idile ti awọn ọmọ Ishari, ati idile ti awọn ọmọ Hebroni, ati idile ti awọn ọmọ Usieli: wọnyi ni idile awọn ọmọ Kohati. Gẹgẹ bi iye gbogbo awọn ọkunrin lati ẹni oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, nwọn jẹ́ ẹgba mẹrin o le ẹgbẹta, ti nṣe itọju ibi-mimọ́. Awọn idile ti awọn ọmọ Kohati ni ki o pagọ́ lẹba agọ́ si ìha gusù. Ati Elisafani ọmọ Usieli ni ki o ṣe olori ile baba awọn idile awọn ọmọ Kohati. Apoti, ati tabeli, ati ọpá-fitila, ati pẹpẹ wọnni, ati ohun-èlo ibi-mimọ́, eyiti nwọn fi nṣe iṣẹ alufa, ati aṣọ-tita, ati gbogbo ohun-èlo iṣẹ-ìsin rẹ̀, ni yio jẹ́ ohun itọju wọn. Eleasari ọmọ Aaroni alufa ni yio si ṣe olori awọn olori awọn ọmọ Lefi, on ni yio si ma ṣe itọju awọn ti nṣe itọju ibi-mimọ́. Ti Merari ni idile awọn ọmọ Mali, ati idile awọn ọmọ Musi: wọnyi ni idile Merari. Ati awọn ti a kà ninu wọn, gẹgẹ bi iye gbogbo awọn ọkunrin, lati ọmọ oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, nwọn jẹ́ ọgbọkanlelọgbọ̀n. Ati Surieli ọmọ Abihaili ni ki o ṣe olori ile baba awọn idile Merari; ki nwọn ki o dó ni ìhà agọ́ si ìhà ariwa. Iṣẹ itọju awọn ọmọ Merari yio si jẹ́ apáko agọ́, ati ọpá-idabu rẹ̀, ati opó rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo ìsin rẹ̀; Ati opó agbalá yiká, ati ihò-ìtẹbọ wọn, ati ẽkàn wọn, ati okùn wọn. Ṣugbọn awọn ti o pagọ́ niwaju agọ́ na, si ìha ìla-õrùn, ani niwaju agọ́ ajọ si ìha ìla-õrùn ni, ki o jẹ́ Mose, ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, ti nwọn nṣe itọju ibi-mimọ́, fun itọju awọn ọmọ Israeli; alejò ti o ba si sunmọtosi pipa li a o pa a. Gbogbo awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Lefi, ti Mose ati Aaroni kà nipa aṣẹ OLUWA, gẹgẹ bi idile wọn, gbogbo awọn ọkunrin lati ọmọ oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, nwọn jẹ́ ẹgba mọkanla
Num 3:1-39 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn wọnyi ni ìdílé Aaroni ati ti Mose, nígbà tí OLUWA bá Mose sọ̀rọ̀ ní orí òkè Sinai. Orúkọ àwọn ọmọ Aaroni lọkunrin nìwọ̀nyí: Nadabu ni àkọ́bí, lẹ́yìn rẹ̀ ni Abihu, Eleasari ati Itamari. Àwọn ni ó ta òróró sí lórí, láti yà wọ́n sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ alufaa. Nadabu ati Abihu kú nígbà tí wọ́n fi iná tí a kò yà sí mímọ́ rúbọ sí OLUWA ninu aṣálẹ̀ Sinai. Wọn kò bímọ. Nítorí náà Eleasari ati Itamari ní ń ṣe iṣẹ́ alufaa ní ìgbà ayé Aaroni, baba wọn. OLUWA sọ fún Mose pé, “Mú ẹ̀yà Lefi wá siwaju Aaroni alufaa, kí wọ́n sì máa ṣe iranṣẹ fún un. Àwọn ni yóo máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn alufaa ati fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli níwájú Àgọ́ Àjọ bí àwọn alufaa tí ń ṣe iṣẹ́ níbi mímọ́. Àwọn ọmọ Lefi yóo máa ṣe ìtọ́jú gbogbo ohun èlò Àgọ́ Àjọ, wọn óo sì máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún gbogbo ọmọ Israẹli bí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ níbi mímọ́. Fi àwọn ọmọ Lefi fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀. Àwọn nìkan ni wọn óo jẹ́ iranṣẹ fún wọn láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Yan Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ibi mímọ́, pípa ni kí ẹ pa á.” OLUWA sọ fún Mose pé, “Mo ti yan àwọn ọmọ Lefi láàrin àwọn eniyan Israẹli dípò àwọn àkọ́bí ọmọ Israẹli. Tèmi ni àwọn ọmọ Lefi, nítorí tèmi ni gbogbo àwọn àkọ́bí. Nígbà tí mo pa gbogbo àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti ni mo ya gbogbo àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Israẹli sọ́tọ̀; kì báà ṣe ti eniyan tabi ti ẹranko, tèmi ni gbogbo wọn. Èmi ni OLUWA.” OLUWA sọ fún Mose ninu aṣálẹ̀ Sinai, ó ní, “Ka iye àwọn ọmọkunrin Lefi gẹ́gẹ́ bí ìdílé baba wọn. Bẹ̀rẹ̀ láti ọmọ oṣù kan lọ sókè.” Mose sì kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. Lefi ní ọmọkunrin mẹta: Geriṣoni, Kohati ati Merari, wọ́n sì jẹ́ olórí àwọn ìdílé wọn. Orúkọ àwọn ọmọ Geriṣoni ni Libini ati Ṣimei. Orúkọ àwọn ọmọ Kohati ni Amramu, Iṣari, Heburoni ati Usieli. Orúkọ àwọn ọmọ Merari ni Mahili ati Muṣi. Àwọn ìdílé Lefi nìwọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. Geriṣoni ni baba ńlá àwọn ọmọ Libini ati àwọn ọmọ Ṣimei. Gbogbo àwọn ọkunrin tí a kà ninu wọn, láti ọmọ oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaarin ó dín ẹẹdẹgbẹta (7,500). Àwọn ọmọ Geriṣoni yóo pàgọ́ tiwọn sẹ́yìn Àgọ́ Àjọ ní ìhà ìwọ̀ oòrùn. Eliasafu ọmọ Laeli ni yóo jẹ́ olórí wọn. Àwọn ni yóo máa ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́ ati Àgọ́ Àjọ, aṣọ ìbòrí rẹ̀, ati aṣọ tí wọ́n ń ta sí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé rẹ̀; aṣọ tí wọ́n ń ta sí àgbàlá, aṣọ tí wọ́n ń ta sí ẹnu ọ̀nà àbáwọ àgbàlá tí ó yí ibi mímọ́ ati pẹpẹ ká, ati okùn, ati gbogbo nǹkan tí wọ́n ń lò pẹlu rẹ̀. Kohati ni baba ńlá àwọn ọmọ Amramu ati àwọn ọmọ Iṣari, àwọn ọmọ Heburoni ati àwọn ọmọ Usieli. Gbogbo àwọn ọkunrin tí a kà ninu wọn láti ọmọ oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaarin ó lé ẹgbẹta (8,600). Àwọn ni wọ́n ń ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́. Àwọn ọmọ Kohati yóo pàgọ́ tiwọn sí ẹ̀gbẹ́ Àgọ́ Àjọ ní ìhà gúsù. Elisafani ọmọ Usieli ni yóo jẹ́ olórí wọn. Àwọn ni yóo máa ṣe ìtọ́jú Àpótí majẹmu ati tabili, ọ̀pá fìtílà ati àwọn pẹpẹ, ati àwọn ohun èlò ní ibi mímọ́, tí àwọn alufaa máa ń lò fún iṣẹ́ ìsìn; ati aṣọ ìbòjú, ati gbogbo iṣẹ́ tí ó jẹ mọ́ ti àwọn ohun èlò wọnyi. Eleasari ọmọ Aaroni alufaa ni yóo máa ṣe alákòóso àwọn olórí àwọn ọmọ Lefi, òun ni yóo sì máa ṣe àkóso àwọn tí ń ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́. Merari ni baba ńlá àwọn ọmọ Mahili, ati ti àwọn ọmọ Muṣi. Gbogbo àwọn ọkunrin tí a kà ninu wọn láti ọmọ oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaata lé igba (6,200). Surieli ọmọ Abihaili ni yóo jẹ́ olórí wọn. Kí wọ́n pàgọ́ tiwọn sí ìhà àríwá Àgọ́ Àjọ. Àwọn ni yóo máa ṣe ìtọ́jú àwọn igi àkànpọ̀ ibi mímọ́, ati àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀ pẹlu àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀, ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, ati gbogbo iṣẹ́ tí ó jẹ mọ́ wọn; ati gbogbo òpó àgbàlá yíká, pẹlu àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn, èèkàn wọn, ati okùn wọn. Mose pẹlu Aaroni ati àwọn ọmọ wọn yóo pa àgọ́ tiwọn sí ìhà ìlà oòrùn, níwájú Àgọ́ Àjọ. Àwọn ni yóo máa ṣe iṣẹ́ ìsìn fún àwọn ọmọ Israẹli ní ibi mímọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ibi mímọ́, pípa ni kí wọ́n pa á. Gbogbo àwọn ọmọ Lefi lọkunrin, láti ọmọ oṣù kan sókè tí Mose kà ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA jẹ́ ẹgbaa mọkanla (22,000).
Num 3:1-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìwọ̀nyí ni ìdílé Aaroni àti Mose ní ìgbà tí OLúWA bá Mose sọ̀rọ̀ ní òkè Sinai. Orúkọ àwọn ọmọ Aaroni nìwọ̀nyí, Nadabu ni àkọ́bí, Abihu, Eleasari àti Itamari. Orúkọ àwọn ọmọ Aaroni ni ìwọ̀nyí, àwọn àlùfáà tí a fi òróró yàn, àwọn tí a fi joyè àlùfáà láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà. Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu ti kú níwájú OLúWA nígbà tí wọ́n rú iná àjèjì níwájú OLúWA nínú ijù Sinai, àwọn méjèèjì kò sì ní ọmọ. Báyìí Eleasari àti Itamari ló ṣiṣẹ́ àlùfáà nígbà ayé Aaroni baba wọn. OLúWA sọ fún Mose pé, “Kó ẹ̀yà Lefi wá, kí o sì fà wọ́n fún Aaroni àlùfáà láti máa ràn án lọ́wọ́. Wọn yóò máa ṣiṣẹ́ fún un àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn ní àgọ́ ìpàdé bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú àgọ́. Wọn yóò máa tọ́jú gbogbo ohun èlò inú àgọ́ ìpàdé, wọn yóò sì máa ṣe ojúṣe àwọn ọmọ Israẹli nípa ṣíṣe iṣẹ́ nínú àgọ́. Fi ẹ̀yà Lefi jì Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn nìkan ni a fi fún Aaroni nínú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli. Kí o sì yan Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ láti máa ṣiṣẹ́ àlùfáà; àlejò tó bá súnmọ́ ibi mímọ́ pípa ni kí ẹ pa á.” OLúWA tún sọ fún Mose pé, “Báyìí èmi fúnra mi ti mú ẹ̀yà Lefi láàrín àwọn ọmọ Israẹli dípò gbogbo àkọ́bí ọkùnrin àwọn ọmọbìnrin Israẹli. Ti èmi ni àwọn ọmọ Lefi, nítorí pé ti èmi ni gbogbo àkọ́bí. Ní ọjọ́ tí mo pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Ejibiti ni mo ti ya gbogbo àkọ́bí sọ́tọ̀ ní Israẹli yálà ti ènìyàn tàbí ti ẹranko. Gbogbo wọn gbọdọ̀ jẹ́ ti èmi. Èmi ni OLúWA.” Nígbà náà ni OLúWA sọ fún Mose ní aginjù Sinai pé, “Ka àwọn ọmọ Lefi nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn kí o ka gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ oṣù kan sókè” Mose sì kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLúWA ti pa á láṣẹ fún un. Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari. Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Gerṣoni: Libni àti Ṣimei. Àwọn ìdílé Kohati ni: Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli. Àwọn ìdílé Merari ni: Mahili àti Muṣi. Wọ̀nyí ni ìdílé Lefi gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. Ti Gerṣoni ni ìdílé Libni àti Ṣimei; àwọn ni ìdílé Gerṣoni. Iye àwọn ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ oṣù kan ó lé, jẹ́ ẹgbàata ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (7,500). Àwọn ìdílé Gerṣoni yóò pa ibùdó sí ìhà ìwọ̀-oòrùn lẹ́yìn àgọ́. Olórí àwọn ìdílé Gerṣoni ni Eliasafu ọmọ Láélì. Iṣẹ́ àwọn ìdílé Gerṣoni nínú àgọ́ ìpàdé ni pé àwọn yóò máa tọ́jú àgọ́, ìbòrí àgọ́, aṣọ títa ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, aṣọ títa ti àgbàlá, aṣọ títa ti ẹnu-ọ̀nà àgbàlá tó yí àgọ́ àti pẹpẹ ká, àwọn okùn rẹ̀ àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ lílò wọn. Ti Kohati ní ìdílé Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli, wọ̀nyí ni ìran Kohati. Iye gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ oṣù kan ó lé jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rin ó-lé-ẹgbẹ̀ta (8,600), tí yóò máa ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́. Àwọn ìdílé Kohati yóò pa ibùdó wọn sí ìhà gúúsù ní ẹ̀gbẹ́ àgọ́. Olórí àwọn ìdílé Kohati ni Elisafani ọmọ Usieli. Àwọn ni yóò máa tọ́jú àpótí ẹ̀rí, tábìlì, ọ̀pá fìtílà, àwọn pẹpẹ, gbogbo ohun èlò ibi mímọ́ tí à ń lò fún iṣẹ́ ìsìn, aṣọ títa àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ lílò wọn. Eleasari ọmọ Aaroni àlùfáà ni alákòóso gbogbo àwọn olórí ìdílé Lefi. Òun ni wọ́n yàn lórí gbogbo àwọn tí yóò máa tọ́jú ibi mímọ́. Ti Merari ni ìran Mahili àti Muṣi, àwọn ni ìran Merari. Iye gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ oṣù kan ó lé, èyí tí wọ́n kà jẹ́ igba mọ́kànlélọ́gbọ̀n (6,200). Olórí àwọn ìdílé ìran Merari ni Ṣurieli ọmọ Abihaili. Wọn yóò pa ibùdó wọn sí ìhà àríwá àgọ́. Àwọn ìran Merari ni a yàn fún títọ́jú àwọn férémù àgọ́, ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, òpó rẹ̀, ihò òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò tó jẹ mọ́ lílò wọn; Iṣẹ́ wọn tún ni títọ́jú àwọn òpó tó yí àgbàlá ká, ihò òpó rẹ̀, èèkàn àti okùn wọn. Mose àti Aaroni pẹ̀lú àwọn ọmọ yóò pa àgọ́ ní ìdojúkọ ìwọ̀-oòrùn níwájú àgọ́ ìpàdé. Iṣẹ́ wọn ni láti máa mójútó iṣẹ́ ìsìn ibi mímọ́ àti láti máa ṣiṣẹ́ ìsìn fún àwọn ọmọ Israẹli. Àlejò tó bá súnmọ́ ibi mímọ́ yàtọ̀ sí àwọn tí a yàn, pípa ni kí ẹ pa á. Àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Lefi tí a kà gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pa á láṣẹ fún Mose àti Aaroni gẹ́gẹ́ bí ìran wọn, pẹ̀lú gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ oṣù kan ó lé jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlá (22,000).