Skip to content
Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

Num 28:2YBCV(Bibeli Mimọ)

Fi aṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Ọrẹ-ẹbọ mi, ati àkara mi fun ẹbọ mi ti a fi iná ṣe, fun õrùn didùn si mi, ni ki ẹnyin ma kiyesi lati mú fun mi wá li akokò wọn.

Num 28:2BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

“Fún àwọn ọmọ Israẹli ní òfin yìí kí o sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ rí i wí pé ẹ gbé e wá sí iwájú mi ní àkókò tí a ti yàn, oúnjẹ ọrẹ ẹbọ mi tí a fi iná ṣe sí mi, gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí mi.’

Num 28:2YCE(Yoruba Bible)

pé kí ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọn máa mú ọrẹ wá fún ohun ìrúbọ sí òun OLUWA ní àkókò rẹ̀, ati àwọn nǹkan tí wọn yóo máa fi rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn.