Num 25:1-18

Num 25:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)

ISRAELI si joko ni Ṣittimu, awọn enia na si bẹ̀rẹsi iṣe panṣaga pẹlu awọn ọmọbinrin Moabu: Nwọn si pe awọn enia na si ẹbọ oriṣa wọn; awọn enia na si jẹ, nwọn si tẹriba fun oriṣa wọn. Israeli si dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Baali-peoru: ibinu OLUWA si rú si Israeli. OLUWA si sọ fun Mose pe, Mú gbogbo awọn olori awọn enia na, ki o si so wọn rọ̀ si õrùn niwaju OLUWA, ki imuna ibinu OLUWA ki o le yipada kuro lọdọ Israeli. Mose si wi fun awọn onidajọ Israeli pe, Ki olukuluku nyin ki o pa awọn enia rẹ̀ ti o dàpọ mọ́ Baali-peoru. Si kiyesi i, ọkan ninu awọn ọmọ Israeli wá o si mú obinrin Midiani kan tọ̀ awọn arakunrin rẹ̀ wá li oju Mose, ati li oju gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ti nsọkun ni ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. Nigbati Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni alufa ri i, o dide lãrin ijọ, o si mú ọ̀kọ kan li ọwọ́ rẹ̀; O si tọ̀ ọkunrin Israeli na lọ ninu agọ́, o si fi gún awọn mejeji li agunyọ, ọkunrin Israeli na, ati obinrin na ni inu rẹ̀. Àrun si da lãrin awọn ọmọ Israeli. Awọn ti o si kú ninu àrun na jẹ́ ẹgba mejila. OLUWA si sọ fun Mose pe, Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni alufa ti yi ibinu mi pada kuro lara awọn ọmọ Israeli, nipa itara rẹ̀ nitori mi lãrin wọn, ki emi ki o máṣe run awọn ọmọ Israeli ninu owú mi. Nitorina wipe, Kiyesi i, emi fi majẹmu alafia mi fun u. Yio jẹ́ tirẹ̀ ati ti irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀, ani majẹmu iṣẹ-alufa titi-aiye; nitoriti o ṣe itara fun Ọlọrun rẹ̀, o si ṣètutu fun awọn ọmọ Israeli. Njẹ orukọ ọkunrin Israeli na ti a pa, ani ti a pa pẹlu obinrin Midiani na, a ma jẹ́ Simri, ọmọ Salu, olori ile kan ninu awọn ọmọ Simeoni. Orukọ obinrin Midiani na ti a pa a si ma jẹ́ Kosbi, ọmọbinrin Suru; ti iṣe olori awọn enia kan, ati ti ile kan ni Midiani. OLUWA si sọ fun Mose pe, Yọ awọn ara Midiani lẹnu, ki o si kọlù wọn. Nitoriti nwọn fi ẹ̀tan wọn yọ nyin lẹnu, eyiti nwọn tàn nyin niti ọ̀ran Peori, ati niti ọ̀ran Kosbi, ọmọ ijoye Midiani kan, arabinrin wọn, ẹniti a pa li ọjọ́ àrun nì niti ọ̀ran Peori.

Num 25:1-18 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli pàgọ́ sí àfonífojì Ṣitimu, àwọn ọkunrin wọn ń bá àwọn ọmọbinrin Moabu tí wọ́n wà níbẹ̀ ṣe àgbèrè. Àwọn obinrin wọnyi a sì máa pè wọ́n lọ síbi àsè ìbọ̀rìṣà. Wọn a máa jẹ oúnjẹ wọn, wọn a sì ma bá wọn bọ oriṣa wọn. Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe da ara wọn pọ̀ mọ́ oriṣa Baali tí ó wà ní Peori, ibinu OLUWA sì ru sí wọn. OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Mú gbogbo àwọn olórí Israẹli, kí o so wọ́n kọ́ sórí igi ninu oòrùn títí tí wọn óo fi kú níwájú OLUWA. Nígbà náà ni n kò tó ni bínú sí àwọn eniyan náà mọ́.” Mose sì wí fún àwọn onídàájọ́ Israẹli pé, “Olukuluku yín gbọdọ̀ pa àwọn eniyan rẹ̀ tí ó lọ sin oriṣa Baali tí ó wà ní Peori.” Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli mú ọmọbinrin Midiani wọlé lójú Mose ati gbogbo àwọn eniyan, níbi tí wọ́n ti ń sọkún lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ níwájú OLUWA. Nígbà tí Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, alufaa, rí i, ó dìde láàrin àwọn eniyan, ó sì mú ọ̀kọ̀ kan, ó tọ ọkunrin náà lọ ninu àgọ́ rẹ̀, ó sì fi ọ̀kọ̀ náà gún òun ati obinrin náà ní àgúnyọ. Àjàkálẹ̀ àrùn sì dúró láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn tí wọ́n kú ninu àjàkálẹ̀ àrùn náà jẹ́ ẹgbaa mejila (24,000). OLUWA sọ fún Mose pé, “N kò ní bínú sí Israẹli mọ nítorí ohun tí Finehasi ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, alufaa, ṣe. Ó kọ̀ láti gba ìbọ̀rìṣà láàyè, nítorí náà ni n kò ṣe ní fi ibinu pa àwọn ọmọ Israẹli run. Nítorí náà, sọ fún un pé mo bá a dá majẹmu alaafia. Majẹmu náà ni pé mo ti yan òun ati arọmọdọmọ rẹ̀ láti máa ṣe alufaa ní Israẹli títí lae nítorí pé ó ní ìtara fún Ọlọrun rẹ̀, ó sì ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan Israẹli.” Orúkọ ọmọ Israẹli tí ó pa pẹlu ọmọbinrin Midiani ni Simiri, ọmọ Salu, olórí ilé kan ninu ẹ̀yà Simeoni. Orúkọ ọmọbinrin Midiani náà ni Kosibi, ọmọ Suri, baálé ilé kan ní ilẹ̀ Midiani. OLUWA sọ fún Mose pé, “Kọlu àwọn ará Midiani, kí o sì pa wọ́n run nítorí ibi tí wọ́n ṣe, ati títàn tí wọ́n tàn yín ní Peori, ati nítorí ọ̀rọ̀ Kosibi, ọmọ baálé kan ní ilẹ̀ Midiani, arabinrin wọn, tí a pa nígbà àjàkálẹ̀ àrùn ti Peori.”

Num 25:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí àwọn Israẹli dúró ní Ṣittimu, àwọn ènìyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àgbèrè pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin Moabu, tí ó pè wọ́n sí ibi ẹbọ òrìṣà wọn. Àwọn ènìyàn náà jẹun wọ́n sì foríbalẹ̀ níwájú òrìṣà wọn. Báyìí ni Israẹli ṣe darapọ̀ mọ́ wọn tí wọ́n sì jọ ń sin Baali-Peori. Ìbínú OLúWA sì ru sí wọn. OLúWA sọ fún Mose pé; “Mú gbogbo àwọn olórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, pa wọ́n kí o sì fi wọ́n kọ́ sórí igi ní gbangba nínú oòrùn níwájú OLúWA, kí ìbínú OLúWA lè kúrò ní ọ̀dọ̀ Israẹli.” Mose sọ fún àwọn onídàájọ́ Israẹli, “Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ pa arákùnrin rẹ̀ èyí tí ó darapọ̀ ní fífi orí balẹ̀ fún Baali-Peori.” Nítòótọ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin Israẹli sì mú obìnrin Midiani wá síwájú ojú Mose àti gbogbo ìjọ ti Israẹli wọ́n sì ń sọkún ní àbáwọlé àgọ́ ìpàdé. Nígbà tí Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, àlùfáà, rí èyí, ó fi ìjọ sílẹ̀, pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. Ó sì tẹ̀lé arákùnrin Israẹli yìí lọ sínú àgọ́. Ó sì fi ọ̀kọ̀ gún àwọn méjèèjì ní àgúnyọ láti ara ọkùnrin Israẹli àti sí ara obìnrin náà. Nígbà náà ni àjàkálẹ̀-ààrùn lórí àwọn ọmọ Israẹli sì dúró; ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó kú nínú àjàkálẹ̀-ààrùn náà jẹ́ ẹgbàá-méjìlá. (24,000). OLúWA sì tún sọ fún Mose pé, “Finehasi ọmọ Eleasari ọmọ Aaroni, àlùfáà, ti yí ìbínú mi padà kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli: nítorí tí ó ní ìtara bí èmi náà ti ní ìtara fún iyì mi láàrín wọn, kí ó lè jẹ́ pé èmi ló pa wọ́n run nínú ìtara mi sí wọn. Nítorí náà sọ fún un pé èmi ṣe májẹ̀mú àlàáfíà mi pẹ̀lú rẹ̀. Òun àti irú-ọmọ rẹ̀ yóò ní májẹ̀mú láéláé fún iṣẹ́ àlùfáà, nítorí pé ó ní ìtara fún Ọlọ́run rẹ̀ láti fi yẹ́ Ọlọ́run sí, ó sì ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli.” Orúkọ ọmọ Israẹli tí a pa pẹ̀lú obìnrin Midiani náà ni Simri, ọmọ Salu, olórí ilé kan nínú àwọn ọmọ Simeoni. Orúkọ ọmọbìnrin Midiani náà tí a pa ní Kosbi ọmọbìnrin Suri, tí ṣe olóyè àwọn ẹ̀yà kan nínú ìdílé kan ní Midiani. OLúWA sì tún sọ fún Mose pé, “Ka àwọn ará Midiani sí ọ̀tá, kí o sì pa wọ́n, nítorí pé wọ́n ṣe sí yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá nígbà tí wọ́n tàn yín nípa ìṣẹ̀lẹ̀ Peori, àti arábìnrin wọn Kosbi ọmọbìnrin ìjòyè Midiani kan, obìnrin tí a pa nígbà tí àjàkálẹ̀-ààrùn ṣẹlẹ̀ nítorí Peori.”