Num 24:2-17

Num 24:2-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

Balaamu si gbé oju rẹ̀ soke o si ri Israeli dó gẹgẹ bi ẹ̀ya wọn; ẹmi Ọlọrun si wá sara rẹ̀. O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaamu ọmọ Beori nwi, ọkunrin ti oju rẹ̀ sí nwi: Ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun nwi, ti o nri iran Olodumare, ti o nṣubu lọ, ti oju rẹ̀ ṣí. Jakobu, agọ́ rẹ wọnyi ti dara tó, ati ibugbé rẹ iwọ Israeli! Bi afonifoji ni nwọn tẹ́ lọ bẹrẹ, bi ọgbà lẹba odònla, bi igi aloe ti OLUWA gbìn, ati bi igi kedari lẹba omi. Omi o ṣàn jade lati inu agbè rẹ̀ wá, irú rẹ̀ yio si wà ninu omi pupọ̀, ọba rẹ̀ yio si ga jù Agagi lọ, ijọba rẹ̀ li a o si gbeleke. Ọlọrun mú u lati Egipti jade wá; o ní agbara bi ti agbanrere: on o jẹ awọn orilẹ-ède ti iṣe ọtá rẹ̀ run, yio si fọ́ egungun wọn, yio si fi ọfà rẹ̀ ta wọn li atapoyọ. O ba, o dubulẹ bi kiniun, ati bi abo-kiniun: tani yio lé e dide? Ibukún ni fun ẹniti o sure fun ọ, ifibú si ni ẹniti o fi ọ bú. Ibinu Balaki si rú si Balaamu, o si fi ọwọ́ lù ọwọ́ pọ̀: Balaki si wi fun Balaamu pe, Emi pè ọ lati fi awọn ọtá mi bú, si kiyesi i iwọ si súre fun wọn patapata ni ìgba mẹta yi. Njẹ nisisiyi sálọ si ibujoko rẹ: emi ti rò lati sọ ọ di ẹni nla; ṣugbọn kiyesi i, OLUWA fà ọ sẹhin kuro ninu ọlá. Balaamu si wi fun Balaki pe, Emi kò ti sọ fun awọn onṣẹ rẹ pẹlu ti iwọ rán si mi pe, Bi Balaki tilẹ fẹ́ lati fi ile rẹ̀ ti o kún fun fadakà ati wurá fun mi, emi kò le rekọja ọ̀rọ OLUWA, lati ṣe rere tabi buburu lati inu ara mi wá; ṣugbọn eyiti OLUWA wi, eyina li emi o sọ? Njẹ nisisiyi si kiyesi i, emi nlọ sọdọ awọn enia mi: wá, emi o si sọ fun ọ ohun ti awọn enia yi yio ṣe si awọn enia rẹ li ẹhin-ọla. O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaamu ọmọ Beori nwi, ọkunrin ti oju rẹ̀ ṣí nwi: Ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun nwi, ti o si mọ̀ imọ̀ Ọga-Ogo, ti o ri iran Olodumare, ti o nṣubu lọ, ti oju rẹ̀ si ṣí: Emi ri i, ṣugbọn ki iṣe nisisiyi: emi si wò o, ṣugbọn kò sunmọtosi: irawọ kan yio ti inu Jakobu jade wá, ọpa-alade kan yio si ti inu Israeli dide, yio si kọlù awọn igun Moabu, yio si ṣẹ́ gbogbo awọn ọmọ irọkẹ̀kẹ.

Num 24:2-17 Yoruba Bible (YCE)

ó sì rí i bí àwọn ọmọ Israẹli ti pa àgọ́ wọn, olukuluku ẹ̀yà ni ààyè tirẹ̀. Ẹ̀mí Ọlọrun sì bà lé e, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní, “Ọ̀rọ̀ Balaamu ọmọ Beori nìyí, ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ríran dájúdájú; ìran ẹni tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, mo sì lajú sílẹ̀ kedere rí ìran láti ọ̀dọ̀ Olodumare. Nítòótọ́ ó ṣubú, ṣugbọn ojú rẹ̀ wà ní ṣíṣí sílẹ̀. Báwo ni àgọ́ rẹ ti dára tó ìwọ Jakọbu, ati ibùdó rẹ ìwọ Israẹli! Ó dàbí àfonífojì tí ó tẹ́ lọ bẹẹrẹ, bí ọgbà tí ó wà lẹ́bàá odò. Ó dàbí àwọn igi aloe tí OLUWA gbìn, ati bí igi kedari tí ó wà lẹ́bàá odò. Òjò yóo rọ̀ fún Israẹli ní àkókò rẹ̀, omi yóo jáde láti inú agbè rẹ̀; àwọn ohun ọ̀gbìn rẹ̀ yóo sì rí omi mu. Ọba wọn yóo lókìkí ju Agagi lọ, ìjọba rẹ̀ ni a óo sì gbéga. Ọlọrun kó wọn ti Ijipti wá, ó jà fún wọn gẹ́gẹ́ bí àgbáǹréré. Wọn yóo pa àwọn ọ̀tá wọn run, wọn óo wó egungun wọn, wọn óo sì fi ọfà pa wọ́n. Ó dùbúlẹ̀, ó ba bíi kinniun, bí abo kinniun tí ó sùn, ta ló lè jí i dìde? Ibukun ni fún ẹni tí ó bá súre fún Israẹli, ẹni tí ó bá sì gbé Israẹli ṣépè, olúwarẹ̀ gbé!” Balaki bá bínú sí Balaamu gidigidi, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi ọwọ́ lu ọwọ́. Ó sì sọ fún Balaamu pé: “Mo pè ọ́ pé kí o wá gbé àwọn ọ̀tá mi ṣépè, ṣugbọn dípò kí o gbé wọ́n ṣépè, o súre fún wọn ní ìgbà mẹta! Nítorí náà máa lọ sí ilé rẹ. Mo ti pinnu láti sọ ọ́ di eniyan pataki tẹ́lẹ̀ ni, ṣugbọn OLUWA ti dí ọ lọ́nà.” Balaamu bá dáhùn pé: “Ṣebí mo ti sọ fún àwọn oníṣẹ́ tí o rán wá pé, bí o tilẹ̀ fún mi ní ààfin rẹ, tí ó sì kún fún fadaka ati wúrà, sibẹsibẹ, n kò ní agbára láti ṣe ohunkohun ju ohun tí OLUWA bá sọ lọ. N kò lè dá ṣe rere tabi burúkú ní agbára mi, ohun tí OLUWA bá sọ ni n óo sọ.” Balaamu tún sọ fún Balaki pé, “Èmi ń lọ sí ilé mi, ṣugbọn jẹ́ kí n kìlọ̀ fún ọ nípa ohun tí àwọn eniyan wọnyi yóo ṣe sí àwọn eniyan rẹ ní ẹ̀yìn ọ̀la.” Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, pé, “Ọ̀rọ̀ Balaamu ọmọ Beori nìyí, ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ríran dájúdájú. Ìran ẹni tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun, tí ó ní ìmọ̀ ẹni tí ó ga jùlọ, tí ó sì ń rí ìran láti ọ̀dọ̀ Olodumare. Nítòótọ́ ó ṣubú, ṣugbọn ojú rẹ̀ kò wà ní dídì. Mo wo ọjọ́ iwájú rẹ, mo sì rí ẹ̀yìn ọ̀la rẹ. Ìràwọ̀ kan yóo jáde wá láàrin àwọn ọmọ Jakọbu, ọ̀pá àṣẹ yóo ti ààrin àwọn ọmọ Israẹli jáde wá; yóo run àwọn àgbààgbà Moabu, yóo sì wó àwọn ará Seti palẹ̀.

Num 24:2-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí Balaamu wo ìta ó sì rí Israẹli tí wọ́n pàgọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà sórí rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe rẹ̀: “Ó wí pé Balaamu ọmọ Beori, òwe ẹni tí ojú rẹ̀ mọ́lẹ̀, Òwe ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè, ẹni tí ó dojúbolẹ̀, tí ojú rẹ̀ sì là: “Àgọ́ rẹ ti dára tó, ìwọ Jakọbu, àti ibùgbé rẹ, ìwọ Israẹli! “Gẹ́gẹ́ bí Àfonífojì tí ó tàn jáde, gẹ́gẹ́ bí ọgbà tí ó wà ní ẹ̀bá odò ńlá, gẹ́gẹ́ bí igi aloe tí OLúWA gbìn, gẹ́gẹ́ bí igi kedari tí ó wà lẹ́bàá odò. Omi yóò sàn láti inú garawa: èso wọn yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi. “Ọba wọn yóò ga ju Agagi lọ; ìjọba wọn yóò di gbígbéga. “Ọlọ́run mú wọn jáde láti Ejibiti wá; wọ́n ní agbára gẹ́gẹ́ bí i ti àgbáǹréré. Wọ́n jẹ orílẹ̀-èdè tí ń ṣe ọ̀tá rẹ̀ run, wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí túútúú; wọ́n ó sì fi ọfà wọn ta wọ́n ní àtapòyọ. Ó tẹríba ó sì dùbúlẹ̀ bí kìnnìún, bí abo kìnnìún: ta ni ó gbọdọ̀ jí wọn? “Ìbùkún ni fún ẹni tí ó bùkún fún ọ, kí ìfibú jẹ́ ti ẹni tí ó fi ọ́ bú!” Nígbà náà ni ìbínú Balaki sì dé sí Balaamu. Ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́ ó wí pé, “Mo pè ọ́ láti bú àwọn ọ̀tá mi ṣùgbọ́n o tún bùkún fún wọn nígbà mẹ́ta yìí. Nísinsin yìí sálọ sí ibùjókòó rẹ! Èmi ti rò láti sọ ọ́ di ẹni ńlá, ṣùgbọ́n OLúWA tí fà ọ́ sẹ́yìn láti gba èrè yìí.” Balaamu dá Balaki lóhùn, “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí o rán sí mi wí pé, ‘Kódà bí Balaki bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, èmi kò le ṣe ohunkóhun lọ́wọ́ ara mi, yálà búburú tàbí rere, láti kọjá òfin OLúWA: ohun tí OLúWA bá wí ni èmi ó sọ’? Nísinsin yìí mò ń padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó kìlọ̀ fún ọ nítorí nǹkan tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò ṣe sí àwọn ènìyàn rẹ ní ọjọ́ iwájú.” Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe: “Òwe Balaamu ọmọ Beori, òwe ẹni tí ojú rẹ̀ ríran kedere, Ẹni tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń wí, tí ó sì mọ ìmọ̀ Ọ̀gá-ògo, tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè, ẹni tí ó dọ̀bálẹ̀, tí ojú rẹ̀ sì ṣí: “Mo rí i, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìsinsin yìí, Mo kíyèsi, ṣùgbọ́n kò súnmọ́. Ìràwọ̀ kan yóò jáde láti ọ̀dọ̀ Jakọbu; yóò yọ jáde láti Israẹli. Yóò tẹ̀ fọ́ orí Moabu, yóò sì fọ́ agbárí gbogbo ọmọ Seti.