Num 24:10-11
Num 24:10-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ibinu Balaki si rú si Balaamu, o si fi ọwọ́ lù ọwọ́ pọ̀: Balaki si wi fun Balaamu pe, Emi pè ọ lati fi awọn ọtá mi bú, si kiyesi i iwọ si súre fun wọn patapata ni ìgba mẹta yi. Njẹ nisisiyi sálọ si ibujoko rẹ: emi ti rò lati sọ ọ di ẹni nla; ṣugbọn kiyesi i, OLUWA fà ọ sẹhin kuro ninu ọlá.
Num 24:10-11 Yoruba Bible (YCE)
Balaki bá bínú sí Balaamu gidigidi, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi ọwọ́ lu ọwọ́. Ó sì sọ fún Balaamu pé: “Mo pè ọ́ pé kí o wá gbé àwọn ọ̀tá mi ṣépè, ṣugbọn dípò kí o gbé wọ́n ṣépè, o súre fún wọn ní ìgbà mẹta! Nítorí náà máa lọ sí ilé rẹ. Mo ti pinnu láti sọ ọ́ di eniyan pataki tẹ́lẹ̀ ni, ṣugbọn OLUWA ti dí ọ lọ́nà.”
Num 24:10-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni ìbínú Balaki sì dé sí Balaamu. Ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́ ó wí pé, “Mo pè ọ́ láti bú àwọn ọ̀tá mi ṣùgbọ́n o tún bùkún fún wọn nígbà mẹ́ta yìí. Nísinsin yìí sálọ sí ibùjókòó rẹ! Èmi ti rò láti sọ ọ́ di ẹni ńlá, ṣùgbọ́n OLúWA tí fà ọ́ sẹ́yìn láti gba èrè yìí.”