Num 23:1-30

Num 23:1-30 Bibeli Mimọ (YBCV)

BALAAMU si wi fun Balaki pe, Mọ pẹpẹ meje fun mi nihin, ki o si pèse akọ-malu meje, ati àgbo meje fun mi nihin. Balaki si ṣe bi Balaamu ti wi; ati Balaki ati Balaamu fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan. Balaamu si wi fun Balaki pe, Duro tì ẹbọ sisun rẹ, emi o si lọ; bọya OLUWA yio wá pade mi: ohunkohun ti o si fihàn mi emi o wi fun ọ. O si lọ si ibi giga kan. Ọlọrun si pade Balaamu: o si wi fun u pe, Emi ti pèse pẹpẹ meje silẹ, mo si ti fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan. OLUWA si fi ọ̀rọ si Balaamu li ẹnu, o si wipe, Pada tọ̀ Balaki lọ, bayi ni ki iwọ ki o si sọ. O si pada tọ̀ ọ lọ, si kiyesi i, on duro tì ẹbọ sisun rẹ̀, on ati gbogbo awọn ijoye Moabu. O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaki ọba Moabu mú mi lati Aramu wá, lati òke-nla ìla-õrún wá, wipe, Wá, fi Jakobu bú fun mi, si wá, ki o fi Israeli ré. Emi o ti ṣe fibú, ẹniti Ọlọrun kò fibú? tabi emi o si ti ṣe firé, ẹniti OLUWA kò firé? Nitoripe lati ori apata wọnni ni mo ri i, ati lati òke wọnni ni mo wò o: kiyesi i, awọn enia yi yio dágbé, a ki yio si kà wọn kún awọn orilẹ-ède. Tali o le kà erupẹ Jakobu, ati iye idamẹrin Israeli? Jẹ ki emi ki o kú ikú olododo, ki igbẹhin mi ki o si dabi tirẹ̀! Balaki si wi fun Balaamu pe, Kini iwọ nṣe si mi yi? mo mú ọ wá lati fi awọn ọtá mi bú, si kiyesi i, iwọ si sure fun wọn patapata. On si dahùn o si wipe, Emi ha le ṣe aiṣọra lati sọ eyiti OLUWA fi si mi li ẹnu bi? Balaki si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, bá mi lọ si ibomiran, lati ibiti iwọ o le ri wọn; kìki apakan wọn ni iwọ o ri, iwọ ki yio si ri gbogbo wọn tán; ki o si fi wọn bú fun mi lati ibẹ̀ lọ. O si mú u wá si igbẹ Sofimu sori òke Pisga, o si mọ pẹpẹ meje, o si fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan. On si wi fun Balaki pe, Duro nihin tì ẹbọ sisun rẹ, emi o si lọ ipade OLUWA lọhùn yi. OLUWA si pade Balaamu, o si fi ọ̀rọ si i li ẹnu, wipe, Tun pada tọ̀ Balaki lọ, ki o si wi bayi. O si tọ̀ ọ wá, kiyesi i, o duro tì ẹbọ sisun rẹ̀, ati awọn ijoye Moabu pẹlu rẹ̀. Balaki si bi i pe, Kini OLUWA sọ? O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Dide, Balaki, ki o si gbọ́; ki o si fetisi mi, iwọ ọmọ Sipporu: Ọlọrun ki iṣe enia ti yio fi ṣeké; bẹ̃ni ki iṣe ọmọ enia ti yio fi ronupiwada: a ma wi, ki o má si ṣe bi? tabi a ma sọ̀rọ ki o má mu u ṣẹ? Kiyesi i, emi gbà aṣẹ ati sure: on si ti sure, emi kò si le yì i. On kò ri ẹ̀ṣẹ ninu Jakobu, bẹ̃ni kò ri ibi ninu Israeli: OLUWA Ọlọrun rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ihó-ayọ ọba si mbẹ ninu wọn. Ọlọrun mú wọn lati Egipti jade wá; o ní agbara bi ti agbanrere. Nitõtọ kò sí ìfaiya si Jakobu, bẹ̃ni kò sí afọṣẹ si Israeli: nisisiyi li a o ma wi niti Jakobu ati niti Israeli, Ohun ti Ọlọrun ṣe! Kiyesi i, awọn enia na yio dide bi abokiniun, yio si gbé ara rẹ̀ soke bi kiniun: on ki yio dubulẹ titi yio fi jẹ ohun ọdẹ, titi yio si fi mu ninu ẹ̀jẹ ohun pipa. Balaki si wi fun Balaamu pe, Kuku má fi wọn bú, bẹ̃ni ki o máṣe sure fun wọn rára. Ṣugbọn Balaamu dahún, o si wi fun Balaki pe, Emi kò ha ti wi fun ọ pe, Gbogbo eyiti OLUWA ba sọ, on ni emi o ṣe? Balaki si wi fun Balaamu pe, Wá, emi bẹ̀ ọ, emi o mú ọ lọ si ibomiran; bọya yio wù Ọlọrun ki iwọ ki o fi wọn bú fun mi lati ibẹ̀ lọ. Balaki si mú Balaamu wá sori òke Peoru, ti o kọjusi aginjù. Balaamu si wi fun Balaki pe, Mọ pẹpẹ meje fun mi nihin, ki o si pèse akọmalu meje ati àgbo meje fun mi nihin. Balaki si ṣe bi Balaamu ti wi, o si fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan.

Num 23:1-30 Yoruba Bible (YCE)

Balaamu sọ fún Balaki pé, “Tẹ́ pẹpẹ meje sí ibí yìí fún mi kí o sì pèsè akọ mààlúù meje ati àgbò meje.” Balaki ṣe gẹ́gẹ́ bí Balaamu ti wí, àwọn mejeeji sì fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan. Balaamu bá sọ fún Balaki pé, “Dúró níhìn-ín, lẹ́bàá ẹbọ sísun rẹ, n óo máa lọ bóyá OLUWA yóo wá pàdé mi. Ohunkohun tí ó bá fihàn mí, n óo sọ fún ọ.” Ó bá lọ sórí òkè kan. Ọlọrun lọ bá a níbẹ̀, Balaamu sì sọ fún Ọlọrun pé, “Mo ti tẹ́ pẹpẹ meje, mo sì ti fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.” OLUWA bá rán Balaamu pada sí Balaki, ó sọ ohun tí yóo sọ fún un. Nígbà tí ó pada dé, ó bá Balaki ati àwọn àgbààgbà Moabu, wọ́n dúró ti àwọn ẹbọ sísun náà. Balaamu bá bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní: “Láti Aramu, Balaki mú mi wá, ọba Moabu mú mi wá láti àwọn òkè ìlà oòrùn. Ó sọ pé, ‘Wá ba mi ṣépè lé Jakọbu, kí o sì fi Israẹli ré.’ Ẹni tí OLUWA kò gbé ṣépè, báwo ni mo ṣe lè ṣépè lé e? Ẹni tí OLUWA kò ṣépè lé, báwo ni mo ṣe lè gbé e ṣépè? Mo rí wọn láti òkè gíga, mò ń wò wọ́n láti orí àwọn òkè. Wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ń dá gbé; wọn kò da ara wọn pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Ta ló lè ka àwọn ọmọ Jakọbu tí ó pọ̀ bí iyanrìn? Tabi kí ó ka idamẹrin àwọn ọmọ Israẹli? Jẹ́ kí n kú ikú olódodo, kí ìgbẹ̀yìn mi sì dàbí tirẹ̀.” Nígbà náà ni Balaki sọ fún Balaamu pé, “Kí ni ò ń ṣe sí mi yìí? Mo mú ọ wá láti ṣépè lé àwọn ọ̀tá mi, ṣugbọn ò ń súre fún wọn.” Ó sì dáhùn pé, “Ohun tí OLUWA bá sọ fún mi ni mo gbọdọ̀ sọ.” Balaki sọ fún Balaamu pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn. Apákan wọn ni o óo rí, o kò ní rí gbogbo wọn, níbẹ̀ ni o óo ti bá mi ṣépè lé wọn.” Ó bá mú un lọ sórí òkè Pisiga ní pápá Sofimu. Ó tún tẹ́ pẹpẹ meje, ó sì fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan. Balaamu sọ fún Balaki pé, “Dúró ti ẹbọ sísun rẹ, n óo lọ pàdé OLUWA lọ́hùn-ún.” OLUWA rán Balaamu pada sí Balaki pẹlu ohun tí yóo sọ. Nígbà tí ó pada dé ó bá Balaki ati àwọn àgbààgbà Moabu, wọ́n dúró ti ẹbọ sísun náà, Balaki sì bèèrè ohun tí OLUWA sọ lọ́wọ́ rẹ̀. Balaamu bá bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní: “Balaki, dìde, wá gbọ́, fetí sí mi, ọmọ Sipori; Ọlọrun kò jọ eniyan tí máa ń purọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe eniyan tí máa ń yí ọkàn pada. Ohun tí ó bá ti sọ ni yóo ṣe, bí ó bá sì sọ̀rọ̀ yóo rí bẹ́ẹ̀. OLUWA ti sọ fún mi pé kí n bukun wọn, Ọlọrun pàápàá ti bukun wọn, èmi kò lè mú ibukun náà kúrò. Kò rí ìparun ninu Jakọbu, bẹ́ẹ̀ ni kò rí ìpọ́njú níwájú Israẹli. OLUWA Ọlọrun wọn wà pẹlu wọn, Òun sì ni ọba wọn. OLUWA mú wọn jáde láti Ijipti wá, Ó sì ń jà fún wọn bí àgbáǹréré. Kò sí òògùn kan tí ó lè ran Jakọbu, bẹ́ẹ̀ ni àfọ̀ṣẹ kan kò lè ran Israẹli. Wò ó! Àwọn eniyan yóo máa wí nípa Israẹli pé, ‘Wo ohun tí Ọlọrun ṣe!’ Wo orílẹ̀-èdè Israẹli! Ó dìde dúró bí abo kinniun, ó sì gbé ara rẹ̀ sókè bíi kinniun. Kò ní sinmi títí yóo fi jẹ ẹran tí ó pa tán, tí yóo sì fi mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tán.” Balaki sì sọ fún Balaamu pé, “Níwọ̀n ìgbà tí o ti kọ̀, tí o kò ṣépè lé wọ́n, má súre fún wọn.” Balaamu dá a lóhùn pé, “Ǹjẹ́ n kò tí sọ fún ọ pé ohun tí OLUWA bá sọ fún mi ni mo gbọdọ̀ sọ?” Balaki sọ fún Balaamu pé, “N óo mú ọ lọ sí ibòmíràn bóyá Ọlọrun yóo gbà pé kí o bá mi ṣépè lé àwọn eniyan náà níbẹ̀.” Ó bá mú Balaamu lọ sórí òkè Peori tí ó kọjú sí aṣálẹ̀. Balaamu sọ fún Balaki pé, “Kọ́ pẹpẹ ìrúbọ meje kí o sì mú akọ mààlúù meje ati àgbò meje wá.” Balaki ṣe ohun tí Balaamu sọ, ó sì fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

Num 23:1-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

Balaamu wí fún Balaki pé, “Kọ́ pẹpẹ méje fún mi níbí, kí o sì mú akọ màlúù méje àti àgbò méje wá fún mi.” Balaki ṣe bí Balaamu ti sọ, àwọn méjèèjì fi akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan. Nígbà náà Balaamu sọ fún Balaki pé, “Dúró ti ẹbọ sísun rẹ kí èmi sì lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan. Bóyá OLúWA yóò farahàn mí. Ohunkóhun tí ó bá fihàn mí, èmi yóò wí fún ọ.” Nígbà náà ó sì lọ sí ibi gíga. Ọlọ́run sì pàdé rẹ̀, Balaamu sì sọ pé, “Mo tí ṣe pẹpẹ méje, lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan mo ti fi akọ màlúù àti àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ.” OLúWA sì fi ọ̀rọ̀ sí ẹnu Balaamu ó wí pé, “Padà sí ọ̀dọ̀ Balaki kí o sì jẹ́ iṣẹ́ yìí fún un.” Ó sì padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì ba tí ó dúró ti ẹbọ sísun rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìjòyè Moabu. Nígbà náà ni Balaamu sọ ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ jáde wí pé, “Balaki mú mi láti Aramu wá, ọba Moabu láti òkè ìlà-oòrùn wá Ó wí pé, ‘Wá fi Jakọbu bú fún mi; wá, kí o sì jẹ́rìí sí Israẹli.’ Báwo ní èmi ó ṣe fi bú àwọn tí Ọlọ́run kò fi bú? Báwo ni èmi ó ṣe bá wọn wí àwọn tí OLúWA kò bá wí? Láti ṣóńṣó ibi gíga orí àpáta ni mo ti rí wọn, láti orí ibi gíga ni mo ti ń wò wọ́n. Mo rí àwọn ènìyàn tí ń gbé lọ́tọ̀ wọn kò sì ka ará wọn kún ara àwọn orílẹ̀-èdè. Ta ni ó lè ka eruku Jakọbu tàbí ka ìdámẹ́rin Israẹli? Jẹ́ kí èmi kú ikú olódodo, kí ìgbẹ̀yìn mi kí ó dà bí tirẹ̀!” Balaki sọ fún Balaamu pé, “Kí lo ṣe fún mi? Mo gbé ọ wá láti fi àwọn ọ̀tá mi bú, ṣùgbọ́n o kò ṣe nǹkan kan, ṣùgbọ́n o bùkún wọn!” Ó sì dáhùn wí pé, “Ṣé kí n má sọ nǹkan tí OLúWA fi sí mi lẹ́nu?” Nígbà náà Balaki sọ fún un pé, “Wá pẹ̀lú mi sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn; wà á rí díẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn. Láti ibẹ̀, wá fi wọ́n bú fún mi.” Ó sì lọ sí pápá Sofimu ní orí òkè Pisga, ó sì kọ́ pẹpẹ méje síbẹ̀ ó sì fi akọ màlúù àti àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan. Balaamu ṣo fún Balaki pé, “Dúró níbí ti ẹbọ sísun rẹ nígbà tí mo bá lọ pàdé rẹ̀ níbẹ̀.” OLúWA pàdé Balaamu ó sì fi ọ̀rọ̀ sí ní ẹnu wí pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ Balaki kí o sì jíṣẹ́ fún un.” Nígbà náà ó lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì bá à tí ó dúró ti ẹbọ sísun rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè Moabu. Balaki sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni OLúWA wí?” Nígbà náà ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ sísọ, “Dìde, Balaki; kí o sì gbọ́ mi ọmọ Sippori. Ọlọ́run kì í ṣe ènìyàn, tí yóò fi purọ́, tàbí ọmọ ènìyàn, tí ó lè yí ọkàn rẹ̀ padà. Ǹjẹ́ ó sọ̀rọ̀ kí ó má ṣe é? Ǹjẹ́ ó ti ṣèlérí kí ó má mu un ṣẹ? Èmi gba àṣẹ láti bùkún; Ó sì ti bùkún, èmi kò sì lè yípadà. “Kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kankan nínú Jakọbu, kò sì rí búburú kankan nínú Israẹli. OLúWA Ọlọ́run wọn sì wà pẹ̀lú wọn. Ìhó ọba sì wà pẹ̀lú wọn. Ọlọ́run mú wọn jáde láti Ejibiti wá, wọ́n ní agbára màlúù ẹhànnà. Kò ní àfọ̀ṣẹ sí Jakọbu, tàbí àfọ̀ṣẹ sí àwọn Israẹli. Nísinsin yìí a ó sọ nípa ti Jakọbu àti Israẹli, ‘Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe!’ Àwọn ènìyàn náà yóò dìde bí abo kìnnìún; wọ́n yóò sì gbé ara wọn sókè bí i kìnnìún òun kì yóò sì dùbúlẹ̀ títí yóò fi jẹ ohun ọdẹ títí yóò sì fi mu nínú ẹ̀jẹ̀ ohun pípa.” Nígbà náà ni Balaki wí fún Balaamu pé, “O kò kúkú fi wọ́n bú, bẹ́ẹ̀ ni o kò súre fún wọn rárá!” Balaamu dáhùn ó sì wí fún Balaki pé, “Ǹjẹ́ èmi kò ha ti wí fún ọ pé, gbogbo èyí tí OLúWA bá sọ, òun ni èmi yóò ṣe?” Nígbà náà Balaki sọ fún Balaamu pé, “Wá jẹ́ kí èmi kí ó mú ọ lọ sí ibòmíràn bóyá yóò tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn kí ó fi wọ́n bú láti ibẹ̀ lọ.” Balaki gbé Balaamu wá sí orí òkè Peori, tí ó kọjú sí aginjù. Balaamu sì wí fún Balaki pé, “Mọ pẹpẹ méje fún mi níbí kí o sì pèsè akọ màlúù àti àgbò fún mi.” Balaki sì ṣe bí Balaamu ti sọ fún un, ó sì gbé akọ màlúù kan àti àgbò lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.