Num 23:1-12
Num 23:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
BALAAMU si wi fun Balaki pe, Mọ pẹpẹ meje fun mi nihin, ki o si pèse akọ-malu meje, ati àgbo meje fun mi nihin. Balaki si ṣe bi Balaamu ti wi; ati Balaki ati Balaamu fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan. Balaamu si wi fun Balaki pe, Duro tì ẹbọ sisun rẹ, emi o si lọ; bọya OLUWA yio wá pade mi: ohunkohun ti o si fihàn mi emi o wi fun ọ. O si lọ si ibi giga kan. Ọlọrun si pade Balaamu: o si wi fun u pe, Emi ti pèse pẹpẹ meje silẹ, mo si ti fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan. OLUWA si fi ọ̀rọ si Balaamu li ẹnu, o si wipe, Pada tọ̀ Balaki lọ, bayi ni ki iwọ ki o si sọ. O si pada tọ̀ ọ lọ, si kiyesi i, on duro tì ẹbọ sisun rẹ̀, on ati gbogbo awọn ijoye Moabu. O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaki ọba Moabu mú mi lati Aramu wá, lati òke-nla ìla-õrún wá, wipe, Wá, fi Jakobu bú fun mi, si wá, ki o fi Israeli ré. Emi o ti ṣe fibú, ẹniti Ọlọrun kò fibú? tabi emi o si ti ṣe firé, ẹniti OLUWA kò firé? Nitoripe lati ori apata wọnni ni mo ri i, ati lati òke wọnni ni mo wò o: kiyesi i, awọn enia yi yio dágbé, a ki yio si kà wọn kún awọn orilẹ-ède. Tali o le kà erupẹ Jakobu, ati iye idamẹrin Israeli? Jẹ ki emi ki o kú ikú olododo, ki igbẹhin mi ki o si dabi tirẹ̀! Balaki si wi fun Balaamu pe, Kini iwọ nṣe si mi yi? mo mú ọ wá lati fi awọn ọtá mi bú, si kiyesi i, iwọ si sure fun wọn patapata. On si dahùn o si wipe, Emi ha le ṣe aiṣọra lati sọ eyiti OLUWA fi si mi li ẹnu bi?
Num 23:1-12 Yoruba Bible (YCE)
Balaamu sọ fún Balaki pé, “Tẹ́ pẹpẹ meje sí ibí yìí fún mi kí o sì pèsè akọ mààlúù meje ati àgbò meje.” Balaki ṣe gẹ́gẹ́ bí Balaamu ti wí, àwọn mejeeji sì fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan. Balaamu bá sọ fún Balaki pé, “Dúró níhìn-ín, lẹ́bàá ẹbọ sísun rẹ, n óo máa lọ bóyá OLUWA yóo wá pàdé mi. Ohunkohun tí ó bá fihàn mí, n óo sọ fún ọ.” Ó bá lọ sórí òkè kan. Ọlọrun lọ bá a níbẹ̀, Balaamu sì sọ fún Ọlọrun pé, “Mo ti tẹ́ pẹpẹ meje, mo sì ti fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.” OLUWA bá rán Balaamu pada sí Balaki, ó sọ ohun tí yóo sọ fún un. Nígbà tí ó pada dé, ó bá Balaki ati àwọn àgbààgbà Moabu, wọ́n dúró ti àwọn ẹbọ sísun náà. Balaamu bá bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní: “Láti Aramu, Balaki mú mi wá, ọba Moabu mú mi wá láti àwọn òkè ìlà oòrùn. Ó sọ pé, ‘Wá ba mi ṣépè lé Jakọbu, kí o sì fi Israẹli ré.’ Ẹni tí OLUWA kò gbé ṣépè, báwo ni mo ṣe lè ṣépè lé e? Ẹni tí OLUWA kò ṣépè lé, báwo ni mo ṣe lè gbé e ṣépè? Mo rí wọn láti òkè gíga, mò ń wò wọ́n láti orí àwọn òkè. Wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ń dá gbé; wọn kò da ara wọn pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Ta ló lè ka àwọn ọmọ Jakọbu tí ó pọ̀ bí iyanrìn? Tabi kí ó ka idamẹrin àwọn ọmọ Israẹli? Jẹ́ kí n kú ikú olódodo, kí ìgbẹ̀yìn mi sì dàbí tirẹ̀.” Nígbà náà ni Balaki sọ fún Balaamu pé, “Kí ni ò ń ṣe sí mi yìí? Mo mú ọ wá láti ṣépè lé àwọn ọ̀tá mi, ṣugbọn ò ń súre fún wọn.” Ó sì dáhùn pé, “Ohun tí OLUWA bá sọ fún mi ni mo gbọdọ̀ sọ.”
Num 23:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Balaamu wí fún Balaki pé, “Kọ́ pẹpẹ méje fún mi níbí, kí o sì mú akọ màlúù méje àti àgbò méje wá fún mi.” Balaki ṣe bí Balaamu ti sọ, àwọn méjèèjì fi akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan. Nígbà náà Balaamu sọ fún Balaki pé, “Dúró ti ẹbọ sísun rẹ kí èmi sì lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan. Bóyá OLúWA yóò farahàn mí. Ohunkóhun tí ó bá fihàn mí, èmi yóò wí fún ọ.” Nígbà náà ó sì lọ sí ibi gíga. Ọlọ́run sì pàdé rẹ̀, Balaamu sì sọ pé, “Mo tí ṣe pẹpẹ méje, lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan mo ti fi akọ màlúù àti àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ.” OLúWA sì fi ọ̀rọ̀ sí ẹnu Balaamu ó wí pé, “Padà sí ọ̀dọ̀ Balaki kí o sì jẹ́ iṣẹ́ yìí fún un.” Ó sì padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì ba tí ó dúró ti ẹbọ sísun rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìjòyè Moabu. Nígbà náà ni Balaamu sọ ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ jáde wí pé: “Balaki mú mi láti Aramu wá, Ọba Moabu láti òkè ìlà-oòrùn wá Ó wí pé, ‘Wá fi Jakọbu bú fún mi; wá, kí o sì jẹ́rìí sí Israẹli.’ Báwo ní èmi ó ṣe fi bú àwọn tí Ọlọ́run kò fi bú? Báwo ni èmi ó ṣe bá wọn wí àwọn tí OLúWA kò bá wí? Láti ṣóńṣó ibi gíga orí àpáta ni mo ti rí wọn, láti orí ibi gíga ni mo ti ń wò wọ́n. Mo rí àwọn ènìyàn tí ń gbé lọ́tọ̀ wọn kò sì ka ará wọn kún ara àwọn orílẹ̀-èdè. Ta ni ó lè ka eruku Jakọbu tàbí ka ìdámẹ́rin Israẹli? Jẹ́ kí èmi kú ikú olódodo, kí ìgbẹ̀yìn mi kí ó dà bí tirẹ̀!” Balaki sọ fún Balaamu pé, “Kí lo ṣe fún mi? Mo gbé ọ wá láti fi àwọn ọ̀tá mi bú, Ṣùgbọ́n o kò ṣe nǹkan kan Ṣùgbọ́n o bùkún wọn!” Ó sì dáhùn wí pé, “Ṣé kí n má sọ nǹkan tí OLúWA fi sí mi lẹ́nu?”