Num 22:3-6
Num 22:3-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Moabu si bẹ̀ru awọn enia na gidigidi, nitoriti nwọn pọ̀: aisimi si bá Moabu nitori awọn ọmọ Israeli. Moabu si wi fun awọn àgba Midiani pe, Nisisiyi li awọn ẹgbẹ yi yio lá ohun gbogbo ti o yi wa ká, bi akọmalu ti ilá koriko igbẹ́. Balaki ọmọ Sippori si jẹ́ ọba awọn ara Moabu ni ìgba na. O si ránṣẹ si Balaamu ọmọ Beori si Petori, ti o wà lẹba Odò, si ilẹ awọn ọmọ enia rẹ̀, lati pè e wá, wipe, Wò o, awọn enia kan ti ilẹ Egipti jade wá: si kiyesi i, nwọn bò oju ilẹ, nwọn si joko tì mi: Njẹ nisisiyi wa, emi bẹ̀ ọ, fi awọn enia yi bú fun mi; nitoriti nwọn lí agbara jù fun mi; bọya emi o bori, ki awa ki o kọlù wọn, ki emi ki o le lé wọn lọ kuro ni ilẹ yi: nitoriti emi mọ̀ pe ibukún ni fun ẹniti iwọ ba bukún, ifibú si ni ẹniti iwọ ba fibú.
Num 22:3-6 Yoruba Bible (YCE)
ẹ̀rù wọn ba òun ati àwọn eniyan rẹ̀ lọpọlọpọ, nítorí pé wọ́n pọ̀. Jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn ará Moabu nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ará Moabu ranṣẹ sí àwọn olórí Midiani pé, “Àwọn eniyan wọnyi yóo run gbogbo ohun tí ó wà ní àyíká wa bí ìgbà tí mààlúù bá jẹ koríko ninu pápá.” Nítorí náà, Balaki ọmọ Sipori, ọba Moabu ranṣẹ lọ pe Balaamu ọmọ Beori ní Petori lẹ́bàá Odò Yufurate ní ilẹ̀ Amawi pé, “Àwọn eniyan kan jáde ti ilẹ̀ Ijipti wá, wọ́n pàgọ́ sórí ilẹ̀ mi, wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ náà. Agbára wọn ju tèmi lọ, nítorí náà, wá bá mi ṣépè lé wọn, bóyá bí mo bá bá wọn jagun, n óo lè ṣẹgun wọn, kí n sì lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ mi. Mo mọ̀ dájú pé ibukun ni fún ẹni tí o bá súre fún; ẹni tí o bá ṣépè fún, olúwarẹ̀ gbé!”
Num 22:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
ẹ̀rù sì ba Moabu nítorí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn wà níbẹ̀ nítòótọ́, Moabu kún fún ẹ̀rù nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Moabu sọ fún àwọn àgbàgbà Midiani pé, “Nísinsin yìí ni àwọn wọ̀nyí yóò lá gbogbo ohun tí ó yí wa ká, bí màlúù ṣe ń jẹ koríko tí ó wà nínú oko.” Bẹ́ẹ̀ ni Balaki ọmọ Sippori, tí ó jẹ́ ọba Moabu nígbà náà, rán oníṣẹ́ pé Balaamu ọmọ Beori, tí ó wà ní Petori, ní ẹ̀bá odò Eufurate, ti ilẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ. Balaki sọ pé: “Àwọn ènìyàn kan jáde wá láti Ejibiti; wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ ayé wọ́n sì pa ibùdó súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi. Nísinsin yìí, wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú, nítorí wọ́n ní agbára jù fún mi. Nípa ṣíṣe èyí èmi ó ṣẹ́gun wọn, kí n sì lé wọn kúrò ní ilẹ̀ yìí. Nítorí tí mo mọ̀ pé ìbùkún ni fún àwọn tí ìwọ bá bùkún, ìfibú sì ni ẹni tí ìwọ bá fi bú.”