Num 22:1-41

Num 22:1-41 Bibeli Mimọ (YBCV)

AWỌN ọmọ Israeli si ṣí, nwọn si dó si pẹtẹlẹ̀ Moabu li apa keji Jordani ti o kọjusi Jeriko. Balaki ọmọ Sippori si ri gbogbo eyiti Israeli ti ṣe si awọn ọmọ Amori. Moabu si bẹ̀ru awọn enia na gidigidi, nitoriti nwọn pọ̀: aisimi si bá Moabu nitori awọn ọmọ Israeli. Moabu si wi fun awọn àgba Midiani pe, Nisisiyi li awọn ẹgbẹ yi yio lá ohun gbogbo ti o yi wa ká, bi akọmalu ti ilá koriko igbẹ́. Balaki ọmọ Sippori si jẹ́ ọba awọn ara Moabu ni ìgba na. O si ránṣẹ si Balaamu ọmọ Beori si Petori, ti o wà lẹba Odò, si ilẹ awọn ọmọ enia rẹ̀, lati pè e wá, wipe, Wò o, awọn enia kan ti ilẹ Egipti jade wá: si kiyesi i, nwọn bò oju ilẹ, nwọn si joko tì mi: Njẹ nisisiyi wa, emi bẹ̀ ọ, fi awọn enia yi bú fun mi; nitoriti nwọn lí agbara jù fun mi; bọya emi o bori, ki awa ki o kọlù wọn, ki emi ki o le lé wọn lọ kuro ni ilẹ yi: nitoriti emi mọ̀ pe ibukún ni fun ẹniti iwọ ba bukún, ifibú si ni ẹniti iwọ ba fibú. Ati awọn àgba Moabu, ati awọn àgba Midiani dide lọ ti awọn ti ọrẹ ìbere-afọṣẹ li ọwọ́ wọn; nwọn si tọ̀ Balaamu wá, nwọn si sọ ọ̀rọ Balaki fun u. O si wi fun wọn pe, Ẹ wọ̀ nihin li alẹ yi, emi o si mú ọ̀rọ pada tọ̀ nyin wá, bi OLUWA yio ti sọ fun mi: awọn ijoye Moabu si wọ̀ sọdọ Balaamu. Ọlọrun si tọ̀ Balaamu wá, o si wipe, Awọn ọkunrin wo ni wọnyi lọdọ rẹ? Balaamu si wi fun Ọlọrun pe, Balaki ọmọ Sippori, ọba Moabu, li o ranṣẹ si mi pe, Kiyesi i, awọn enia kan ti ilẹ Egipti jade wá, ti o bò oju ilẹ: wá nisisiyi, fi wọn bú fun mi; bọya emi o le bá wọn jà, emi a si lé wọn lọ. Ọlọrun si wi fun Balaamu pe, Iwọ kò gbọdọ bá wọn lọ; iwọ kò gbọdọ fi awọn enia na bú: nitoripe ẹni ibukún ni nwọn. Balaamu si dide li owurọ̀, o si wi fun awọn ijoye Balaki pe, Ẹ ma ba ti nyin lọ si ilẹ nyin: nitoriti OLUWA kọ̀ lati jẹ ki mbá nyin lọ. Awọn ijoye Moabu si dide, nwọn si tọ̀ Balaki lọ, nwọn si wipe, Balaamu kọ̀ lati bá wa wá. Balaki si tun rán awọn ijoye si i, ti o si lí ọlá jù wọn lọ. Nwọn tọ̀ Balaamu wá, nwọn si wi fun u pe, Bayi ni Balaki ọmọ Sippori wi pe, Emi bẹ̀ ọ, máṣe jẹ ki ohun kan ki o di ọ lọwọ lati tọ̀ mi wá: Nitoripe, emi o sọ ọ di ẹni nla gidigidi, emi o si ṣe ohunkohun ti iwọ wi fun mi: nitorina wá, emi bẹ̀ ọ, fi awọn enia yi bú fun mi. Balaamu si dahùn o si wi fun awọn iranṣẹ Balaki pe, Balaki iba fẹ́ fun mi ni ile rẹ̀ ti o kún fun fadaká ati wurà, emi kò le rekọja ọ̀rọ OLUWA Ọlọrun mi, lati ṣe ohun kekere tabi nla. Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ nyin, ẹ wọ̀ nihin pẹlu li oru yi, ki emi ki o le mọ̀ eyiti OLUWA yio wi fun mi si i. Ọlọrun si tọ̀ Balaamu wá li oru, o si wi fun u pe, Bi awọn ọkunrin na ba wá pè ọ, dide, bá wọn lọ; ṣugbọn kìki ọ̀rọ ti emi o sọ fun ọ, eyinì ni ki iwọ ki o ṣe. Balaamu si dide li owurọ̀, o si dì kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ ni gãri, o si bá awọn ijoye Moabu lọ. Ibinu Ọlọrun si rú nitoriti o lọ: angeli OLUWA si duro loju ọ̀na lati di i lọ̀na. Njẹ on gùn kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, awọn iranṣẹ rẹ̀ mejeji si wà pẹlu rẹ̀. Kẹtẹkẹtẹ na si ri angeli OLUWA duro loju ọ̀na, idà rẹ̀ fifàyọ si wà li ọwọ́ rẹ̀: kẹtẹkẹtẹ na si yà kuro loju ọ̀na, o si wọ̀ inu igbẹ́: Balaamu si lù kẹtẹkẹtẹ na, lati darí rẹ̀ soju ọ̀na. Nigbana ni angeli OLUWA duro li ọna toro ọgbà-àjara meji, ogiri mbẹ ni ìha ihin, ati ogiri ni ìha ọhún. Kẹtẹkẹtẹ na si ri angeli OLUWA, o fún ara rẹ̀ mọ́ ogiri, o si fún ẹsẹ̀ Balaamu mọ́ ogiri: on si tun lù u. Angeli OLUWA si tun sun siwaju, o si tun duro ni ibi tõro kan, nibiti àye kò sí lati yà si ọwọ́ ọtún tabi si òsi. Nigbati kẹtẹkẹtẹ na si ri angeli OLUWA, o wólẹ̀ labẹ Balaamu: ibinu Balaamu si rú pupọ̀, o si fi ọpá lu kẹtẹkẹtẹ na. OLUWA si là kẹtẹkẹtẹ na li ohùn, o si wi fun Balaamu pe, Kini mo fi ṣe ọ, ti iwọ fi lù mi ni ìgba mẹta yi? Balaamu si wi fun kẹtẹkẹtẹ na pe, Nitoriti iwọ fi mi ṣẹsin: idà iba wà li ọwọ́ mi, nisisiyi li emi iba pa ọ. Kẹtẹkẹtẹ na si wi fun Balaamu pe, Kẹtẹkẹtẹ rẹ ki emi ṣe, ti iwọ ti ngùn lati ìgba ti emi ti ṣe tirẹ titi di oni? emi a ha ma ṣe si ọ bẹ̃ rí? On si dahùn wipe, Ndao. Nigbana ni OLUWA là Balaamu li oju, o si ri angeli OLUWA duro loju ọ̀na, idà rẹ̀ fifàyọ si wà li ọwọ́ rẹ̀: o si tẹ̀ ori ba, o si doju rẹ̀ bolẹ. Angeli OLUWA si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi lù kẹtẹkẹtẹ rẹ ni ìgba mẹta yi? Kiyesi i, emi jade wá lati di ọ lọ̀na, nitori ọ̀na rẹ lòdi niwaju mi. Kẹtẹkẹtẹ na si ri mi, o si yà fun mi ni ìgba mẹta yi: bikoṣe bi o ti yà fun mi, pipa ni emi iba pa ọ, emi a si dá on si. Balaamu si wi fun angeli OLUWA pe, Emi ti ṣẹ̀; nitori emi kò mọ̀ pe iwọ duro dè mi li ọ̀na; njẹ bi kò ba ṣe didùn inu rẹ, emi o pada. Angeli OLUWA si wi fun Balaamu pe, Ma bá awọn ọkunrin na lọ: ṣugbọn kìki ọ̀rọ ti emi o sọ fun ọ, eyinì ni ki iwọ ki o sọ. Bẹ̃ni Balaamu bá awọn ijoye Balaki lọ. Nigbati Balaki gbọ́ pe Balaamu dé, o jade lọ ipade rẹ̀ si Ilu Moabu, ti mbẹ ni àgbegbe Arnoni, ti iṣe ipẹkun ipinlẹ na. Balaki si wi fun Balaamu pe, Emi kò ha ranṣẹ kanjukanju si ọ lati pè ọ? ẽṣe ti iwọ kò fi tọ̀ mi wá? emi kò ha to lati sọ ọ di ẹni nla? Balaamu si wi fun Balaki pe, Kiyesi i, emi tọ̀ ọ wá: emi ha lí agbara kan nisisiyi rára lati wi ohun kan? ọ̀rọ ti OLUWA fi si mi li ẹnu, on li emi o sọ. Balaamu si bá Balaki lọ, nwọn si wá si Kiriati-husotu. Balaki si rubọ akọmalu ati agutan, o si ranṣẹ si Balaamu, ati si awọn ijoye ti mbẹ pẹlu rẹ̀. O si ṣe ni ijọ́ keji, ni Balaki mú Balaamu, o si mú u wá si ibi giga Baali, ki o ba le ri apakan awọn enia na lati ibẹ̀ lọ.

Num 22:1-41 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn ọmọ Israẹli ṣí kúrò, wọ́n lọ pa àgọ́ wọn sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní òdìkejì Jọdani tí ó kọjú sí Jẹriko. Nígbà tí Balaki ọmọ Sipori, ọba Moabu rí gbogbo ohun tí àwọn ọmọ Israẹli ṣe sí àwọn ará Amori, ẹ̀rù wọn ba òun ati àwọn eniyan rẹ̀ lọpọlọpọ, nítorí pé wọ́n pọ̀. Jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn ará Moabu nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ará Moabu ranṣẹ sí àwọn olórí Midiani pé, “Àwọn eniyan wọnyi yóo run gbogbo ohun tí ó wà ní àyíká wa bí ìgbà tí mààlúù bá jẹ koríko ninu pápá.” Nítorí náà, Balaki ọmọ Sipori, ọba Moabu ranṣẹ lọ pe Balaamu ọmọ Beori ní Petori lẹ́bàá Odò Yufurate ní ilẹ̀ Amawi pé, “Àwọn eniyan kan jáde ti ilẹ̀ Ijipti wá, wọ́n pàgọ́ sórí ilẹ̀ mi, wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ náà. Agbára wọn ju tèmi lọ, nítorí náà, wá bá mi ṣépè lé wọn, bóyá bí mo bá bá wọn jagun, n óo lè ṣẹgun wọn, kí n sì lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ mi. Mo mọ̀ dájú pé ibukun ni fún ẹni tí o bá súre fún; ẹni tí o bá ṣépè fún, olúwarẹ̀ gbé!” Àwọn àgbààgbà Moabu ati Midiani mú owó iṣẹ́ aláfọ̀ṣẹ lọ́wọ́, wọ́n tọ Balaamu wá, wọ́n sì jíṣẹ́ Balaki fún un. Balaamu sọ fún wọn pé, “Ẹ sùn níbí ní alẹ́ yìí, bí ó bá di ọ̀la, n óo sọ ohun tí OLUWA bá sọ fún mi fun yín.” Àwọn àgbààgbà náà sì dúró lọ́dọ̀ Balaamu. Ọlọrun tọ Balaamu wá, ó bi í pé, “Àwọn ọkunrin wo ni wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ yìí?” Balaamu dáhùn pé, “Balaki ọba àwọn ará Moabu ni ó rán wọn sí mi pé, àwọn eniyan kan, tí wọ́n wá láti Ijipti, tẹ̀dó sórí gbogbo ilẹ̀ òun. Ó fẹ́ kí n wá bá òun ṣépè lé wọn, kí ó lè bá wọn jà, kí ó sì lè lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀.” Ọlọrun sọ fún Balaamu pé, “Má bá wọn lọ, má sì ṣépè lé àwọn eniyan náà nítorí ẹni ibukun ni wọ́n.” Nígbà tí Balaamu jí ní òwúrọ̀, ó sọ fún àwọn oníṣẹ́ Balaki pé, “Ẹ máa lọ sí ilẹ̀ yín nítorí OLUWA ti sọ pé n kò gbọdọ̀ ba yín lọ.” Nígbà náà ni wọ́n pada lọ sọ́dọ̀ Balaki, wọn sì sọ fún un wí pé Balaamu kọ̀, kò bá àwọn wá. Balaki tún rán àwọn àgbààgbà mìíràn tí wọ́n pọ̀, tí wọ́n sì ṣe pataki ju àwọn ti iṣaaju lọ sí ọ̀dọ̀ Balaamu. Wọ́n jíṣẹ́ fún un pé Balaki ní, “Mo bẹ̀ ọ́, má jẹ́ kí ohunkohun dí ọ lọ́wọ́ láti wá sọ́dọ̀ mi. N óo sọ ọ́ di eniyan pataki, ohunkohun tí o bá sọ, n óo ṣe é. Jọ̀wọ́ wá bá mi ṣépè lé àwọn eniyan wọnyi.” Balaamu dá àwọn oníṣẹ́ Balaki lóhùn pé, “Balaki ìbáà fún mi ní ààfin rẹ̀, kí ààfin náà sì kún fún fadaka ati wúrà, n kò ní lòdì sí àṣẹ OLUWA Ọlọrun mi, ninu nǹkan kékeré tabi nǹkan ńlá. Ṣugbọn ẹ sùn níbí ní alẹ́ yìí, kí n lè mọ ohun tí OLUWA yóo tún bá mi sọ.” Ní òru ọjọ́ náà, Ọlọrun tọ Balaamu wá, ó ní, “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ọkunrin wọnyi wá bẹ̀ ọ́ pé kí o bá wọn lọ, máa bá wọn lọ, ṣugbọn ohun tí mo bá sọ fún ọ ni o gbọdọ̀ ṣe.” Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Balaamu di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì bá àwọn àgbààgbà Moabu lọ. OLUWA bínú sí Balaamu nítorí pé ó bá wọn lọ. Bí ó ti ń lọ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ pẹlu àwọn iranṣẹ rẹ̀ meji, angẹli OLUWA dúró ní ojú ọ̀nà rẹ̀ ó dínà fún un. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí angẹli tí ó dúró ní ọ̀nà pẹlu idà ní ọwọ́ rẹ̀, ó yà kúrò ní ojú ọ̀nà sinu igbó. Balaamu lu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà láti darí rẹ̀ sójú ọ̀nà. Angẹli náà tún dúró ní ọ̀nà tóóró láàrin ọgbà àjàrà meji, ògiri sì wà ní ìhà mejeeji. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí i, ó fún ara rẹ̀ mọ́ ògiri, ẹsẹ̀ Balaamu sì fún mọ́ ògiri pẹlu, Balaamu bá tún lù ú. Lẹ́ẹ̀kan sí i, angẹli náà lọ siwaju, ó dúró ní ọ̀nà tóóró kan níbi tí kò sí ààyè rárá láti yà sí. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí angẹli náà, ó wó lulẹ̀ lábẹ́ Balaamu. Inú bí Balaamu gidigidi, ó sì fi ọ̀pá rẹ̀ na kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà. Nígbà náà ni OLUWA la kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà lóhùn ó sì sọ̀rọ̀ bí eniyan, ó sì sọ fún Balaamu pé, “Kí ni mo fi ṣe ọ́ tí o fi lù mí nígbà mẹta?” Balaamu dáhùn pé, “Nítorí tí ò ń fi mí ṣẹ̀sín, bí ó bá jẹ́ pé idà wà lọ́wọ́ mi ni, ǹ bá ti pa ọ́.” Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà dáhùn pé, “Ṣebí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ ni mí, tí o sì ti ń gùn mí láti iye ọjọ́ yìí títí di òní? Ǹjẹ́ mo hu irú ìwà báyìí sí ọ rí?” Balaamu dáhùn pé, “Rárá o.” Nígbà náà ni OLUWA la Balaamu lójú láti rí angẹli tí ó dúró lójú ọ̀nà pẹlu idà lọ́wọ́ rẹ̀, Balaamu sì dojúbolẹ̀. Angẹli náà bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló dé tí o fi lu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ nígbà mẹta? Mo wá láti dínà fún ọ nítorí pé kò yẹ kí o rin ìrìn àjò yìí. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ rí mi, ó sì yà fún mi nígbà mẹta, bí bẹ́ẹ̀ bá kọ́, ǹ bá ti pa ọ́, ǹ bá sì dá òun sí.” Balaamu dá angẹli náà lóhùn pé, “Mo ti dẹ́ṣẹ̀, n kò sì mọ̀ pé o dúró lójú ọ̀nà láti dínà fún mi. Ó dára, bí o kò bá fẹ́ kí n lọ, n óo pada.” Angẹli OLUWA sì dáhùn pé, “Máa bá àwọn ọkunrin náà lọ, ṣugbọn ohun tí mo bá sọ fún ọ ni kí o sọ.” Balaamu sì bá wọn lọ. Nígbà tí Balaki gbọ́ pé Balaamu ń bọ̀, ó jáde lọ pàdé rẹ̀ ní ìlú Moabu tí ó wà létí odò Arinoni ní ààlà ilẹ̀ Moabu. Balaki wí fún un pé, “Kí ló dé tí o kò fi wá nígbà tí mo ranṣẹ sí ọ lákọ̀ọ́kọ́? Ṣé o rò pé n kò lè sọ ọ́ di ẹni pataki ni?” Balaamu dáhùn pé, “Wíwá tí mo wá yìí, èmi kò ní agbára láti sọ ohunkohun bíkòṣe ohun tí OLUWA bá sọ fún mi.” Balaamu bá Balaki lọ sí ìlú Kiriati-husotu. Níbẹ̀ ni Balaki ti fi akọ mààlúù ati aguntan ṣe ìrúbọ, ó sì fún Balaamu ati àwọn àgbààgbà tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ninu ẹran náà. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Balaki mú Balaamu lọ sí ibi gegele Bamotu Baali níbi tí ó ti lè rí apá kan àwọn ọmọ Israẹli.

Num 22:1-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà àwọn ọmọ Israẹli rin ìrìnàjò lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu wọ́n sì pa ibùdó lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jordani tí ó kọjá lọ sí Jeriko. Nísinsin yìí, Balaki ọmọ Sippori rí gbogbo ohun tí àwọn Israẹli ti ṣe sí àwọn ará Amori, ẹ̀rù sì ba Moabu nítorí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn wà níbẹ̀ nítòótọ́, Moabu kún fún ẹ̀rù nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Moabu sọ fún àwọn àgbàgbà Midiani pé, “Nísinsin yìí ni àwọn wọ̀nyí yóò lá gbogbo ohun tí ó yí wa ká, bí màlúù ṣe ń jẹ koríko tí ó wà nínú oko.” Bẹ́ẹ̀ ni Balaki ọmọ Sippori, tí ó jẹ́ ọba Moabu nígbà náà, rán oníṣẹ́ pé Balaamu ọmọ Beori, tí ó wà ní Petori, ní ẹ̀bá odò Eufurate, ti ilẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ. Balaki sọ pé: “Àwọn ènìyàn kan jáde wá láti Ejibiti; wọ́n bo gbogbo ilẹ̀ ayé wọ́n sì pa ibùdó súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi. Nísinsin yìí, wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú, nítorí wọ́n ní agbára jù fún mi. Nípa ṣíṣe èyí èmi ó ṣẹ́gun wọn, kí n sì lé wọn kúrò ní ilẹ̀ yìí. Nítorí tí mo mọ̀ pé ìbùkún ni fún àwọn tí ìwọ bá bùkún, ìfibú sì ni ẹni tí ìwọ bá fi bú.” Àti àwọn àgbàgbà Moabu àti Midiani sì lọ pẹ̀lú owó àyẹ̀wò lọ́nà wọn, Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Balaamu, wọ́n sọ nǹkan tí Balaki sọ fún wọn. “Ẹ sùn níbí lálẹ́ yìí” Balaamu sọ fún un pé, “Èmi ó padà wá fún un yín ní èsì nǹkan tí OLúWA bá wí fún mi.” Nítorí tí àwọn ìjòyè Moabu dúró sọ́dọ̀ rẹ̀. Ọlọ́run tọ Balaamu wá ó sì wí pé, “Ta ni àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ yìí?” Balaamu sọ fún Ọlọ́run pé, “Balaki ọmọ Sippori, ọba Moabu, rán iṣẹ́ yìí sí mi pé: ‘Àwọn ènìyàn kan ti ilẹ̀ Ejibiti jáde wá tí wọ́n bo ojú ilẹ̀. Nísinsin yìí, wá, kí o wá fi wọ́n bú fún mi. Bóyá Èmi yóò lè bá wọn jà, èmi ó sì lé wọn jáde.’ ” Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún Balaamu pé, “Má ṣe bá wọn lọ. Ìwọ kò gbọdọ̀ gé ègún lé àwọn ènìyàn náà lórí, nítorí a ti bùkún wọn.” Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì Balaamu dìde ó sì sọ fún àwọn ìjòyè Balaki pé, “Ẹ padà sí orílẹ̀-èdè yín, nítorí tí OLúWA ti kọ̀ láti jẹ́ kí n tẹ̀lé yín.” Nígbà náà àwọn ìjòyè Moabu sì padà tọ Balaki lọ wọ́n sì wí pé, “Balaamu kọ̀ láti tẹ̀lé wa.” Nígbà náà Balaki rán àwọn ìjòyè mìíràn tí wọ́n pọ̀ àwọn tí wọ́n sì níyì ju alákọ́kọ́ lọ. Wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ Balaamu wọ́n sì sọ pé: “Èyí ni ohun tí Balaki ọmọ Sippori sọ: Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun kí ó dè ọ́ lọ́nà láti wá sí ọ̀dọ̀ mi, Nítorí pé èmi yóò fún ọ ní ẹ̀bùn dáradára, èmi yóò sì ṣe ohunkóhun tí ìwọ bá sọ. Wá, kí o sì wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú fún mi.” Ṣùgbọ́n Balaamu dá wọn lóhùn pé, “Kódà tí Balaki bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, èmi kò ní ṣe ohunkóhun tí ó tóbi tàbí kéré tí ó kọjá òfin OLúWA Ọlọ́run mi. Nísinsin yìí ẹ dúró níbí di ọjọ́ kejì gẹ́gẹ́ bí àwọn tókù ti ṣe nígbà náà èmi yóò mọ ohun tí OLúWA yóò tún sọ fún mi.” Ní alẹ́ ọjọ́ náà Ọlọ́run sì tọ Balaamu wá ó sì sọ wí pé, “Nígbà tí ọkùnrin yìí ti wá pè ọ́, lọ pẹ̀lú wọn, ṣùgbọ́n ẹnu nǹkan tí mo sọ fún ọ ni kí o ṣe.” Balaamu dìde ní òwúrọ̀, ó sì di ẹrù lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ òun pẹ̀lú àwọn ìjòyè Moabu. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run bínú gidigidi, angẹli OLúWA sì dúró lójú ọ̀nà láti dojú ìjà kọ ọ́. Balaamu ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ lọ, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ méjì sì wà pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sì rí angẹli OLúWA tí ó dúró ní ojú ọ̀nà pẹ̀lú idà tí a fàyọ ní ọwọ́ rẹ̀, ó kọjú kúrò ní ọ̀nà lọ sínú oko. Balaamu sì lù ú pé kí ó gbé òhun padà lọ sí ojú ọ̀nà. Nígbà náà angẹli OLúWA dúró ní ojú ọ̀nà tóóró láàrín ọgbà àjàrà, pẹ̀lú ògiri ní ọ̀nà méjèèjì. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí angẹli OLúWA, ó lẹ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ ògiri, ó sì rún ẹsẹ̀ Balaamu mọ́ ògiri. Nígbà náà, ó tún nà án, lẹ́ẹ̀kan sí i. Nígbà náà angẹli OLúWA súnmọ́ wájú ó sì dúró níbi ọ̀nà tóóró níbi tí kò ti sí ọ̀nà láti yípadà, bóyá ní ọ̀tún tàbí òsì. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí angẹli OLúWA, ó sì jókòó ní abẹ́ Balaamu, inú sì bí i tó sì nà án pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀. Nígbà náà OLúWA ṣí ẹnu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì sọ fún Balaamu pé, “Kí ni mo ṣe fún ọ tí o fi nà mí lẹ́ẹ̀mẹ́ta?” Balaamu sọ fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pé, “Nítorí ìwọ fi mí ṣẹ̀sín! Bí mo bá ní idà ní ọwọ́ ni èmi ìbá pa ọ́ nísinsin yìí.” Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sọ fún Balaamu pé, “Ṣé mi kì í ṣe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ ni, tí o máa ń gùn ní gbogbo ìgbà, láti ìgbà pípẹ́ wá? Ǹjẹ́ mo hu irú ìwà báyìí sí ọ rí?” “Rárá,” Ó dáhùn. Nígbà náà OLúWA ṣí ojú Balaamu, ó sì rí angẹli OLúWA tí ó dúró ní ojú ọ̀nà pẹ̀lú idà rẹ̀ tí ó fàyọ. Ó sì tẹ orí rẹ̀ ba. Nígbà náà angẹli OLúWA béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni ó dé tí o fi na kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ nígbà mẹ́ta yìí? Mo wá síbí láti kọ ojú ìjà sí ọ nítorí ọ̀nà rẹ kò tọ́ níwájú mi. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí mi ó sì yà kúrò fún mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta yìí. Tí ó bá jẹ́ wí pé kò yà kúrò. Èmi kì ìbá ti pa ọ́ pátápátá nísinsin yìí, ṣùgbọ́n Èmi yóò sì dá òun sí.” Balaamu sọ fún angẹli OLúWA pé, “Mo ti dẹ́ṣẹ̀, èmi kò mọ̀ pé o dúró níwájú ọ̀nà láti dojúkọ mí, Nísinsin yìí tí inú rẹ kò bá dùn, èmi ó padà.” Angẹli OLúWA sọ fún Balaamu pé, “Lọ pẹ̀lú àwọn arákùnrin náà, ṣùgbọ́n nǹkan tí mo sọ fún ọ nìkan ni kí o sọ.” Nígbà náà Balaamu lọ pẹ̀lú àwọn ìjòyè Balaki. Nígbà tí Balaki gbọ́ pé Balaamu ń bọ̀ wá, ó jáde lọ láti lọ pàdé rẹ̀ ní ìlú Moabu tí ó wà ní agbègbè Arnoni, ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ rẹ̀. Balaki sì sọ fún Balaamu pé, “Ǹjẹ́ èmi kò a ránṣẹ́ kánjúkánjú sí ọ? Kí ló dé tí ìwọ kò fi wá sí ọ̀dọ̀ mi? Ṣé èmi kò tó láti sọ ọ́ di ẹni ńlá?” Balaamu sì wí fún Balaki pé “Kíyèsi, èmi tọ̀ ọ́ wá, èmi kò ha ní agbára kan nísinsin yìí rárá láti wí ohun kan? Mo gbọdọ̀ sọ nǹkan tí Ọlọ́run fi sí mi lẹ́nu.” Nígbà náà Balaamu lọ pẹ̀lú Balaki sí Kiriati-Hosotia. Balaki rú ẹbọ akọ màlúù pẹ̀lú àgùntàn, ó sì fún Balaamu ní díẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè tí ó wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì Balaki gbé Balaamu lọ sí Bamoti Baali, láti ibẹ̀ ló ti rí apá kan àwọn ènìyàn.