Num 21:6-9
Num 21:6-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si rán ejò amubina si awọn enia na, nwọn si bù awọn enia na ṣan; ọ̀pọlọpọ ninu Israeli si kú. Nitorina li awọn enia na ṣe tọ̀ Mose wá, nwọn si wipe, Awa ti ṣẹ̀, nitoriti awa ti bá OLUWA ati iwọ sọ̀; gbadura si OLUWA ki o mú ejò wọnyi kuro lọdọ wa. Mose si gbadura fun awọn enia na. OLUWA si wi fun Mose pe, Rọ ejò amubina kan, ki o si fi i sori ọpá-gigùn kan: yio si ṣe, olukuluku ẹniti ejò ba bùṣan, nigbati o ba wò o, yio yè. Mose si rọ ejò idẹ kan, o si fi i sori ọpá-gigùn na: o si ṣe, pe bi ejò kan ba bù enia kan ṣan, nigbati o ba wò ejò idẹ na, on a yè.
Num 21:6-9 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA bá rán ọpọlọpọ ejò amúbíiná sí àwọn eniyan náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bù wọ́n jẹ, ọpọlọpọ ninu wọn sì kú. Wọ́n bá wá sọ́dọ̀ Mose, wọ́n ní, “A ti ṣẹ̀ nítorí tí a ti sọ̀rọ̀ òdì sí OLUWA ati sí ọ. Gbadura sí OLUWA kí ó mú ejò wọnyi kúrò lọ́dọ̀ wa.” Mose bá gbadura fún àwọn eniyan náà. OLUWA sọ fún Mose pé, “Fi idẹ rọ ejò amúbíiná kan, kí o gbé e kọ́ sórí ọ̀pá gígùn kan, ẹnikẹ́ni tí ejò bá bù jẹ, tí ó bá wo ejò idẹ náà yóo yè.” Mose bá rọ ejò idẹ kan, ó gbé e kọ́ sórí ọ̀pá gígùn kan, ẹnikẹ́ni tí ejò bá bù jẹ, tí ó bá ti wò ó, a sì yè.
Num 21:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni OLúWA rán ejò olóró sí àárín wọn; wọ́n gé àwọn ènìyàn jẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Israẹli sì kú. Àwọn ènìyàn sì wá sí ọ̀dọ̀ Mose wọn wí pé, “A ti dá ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí asọ̀rọ̀-òdì sí OLúWA àti sí ìwọ pẹ̀lú. Gba àdúrà pé kí OLúWA mú ejò náà kúrò lọ́dọ̀ wa.” Nígbà náà ni Mose gbàdúrà fún àwọn ènìyàn. OLúWA sọ fún Mose pé, “Rọ ejò, a ó sì gbé e kọ́ sókè lórí igi, ẹni tí ejò bá ti gé jẹ lè wò ó yóò sì yè.” Nígbà náà ni Mose sì rọ ejò onírin ó sì gbé e kọ́ sórí igi, Bí ejò bá sì bu ẹnikẹ́ni jẹ bí ó bá ti wò ó yóò sì yè.