Num 21:4-9
Num 21:4-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn si rìn lati òke Hori lọ li ọ̀na Okun Pupa, lati yi ilẹ Edomu ká: sũru si tán awọn enia na pupọ̀pupọ nitori ọ̀na na. Awọn enia na si bá Ọlọrun, ati Mose sọ̀ pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mú wa gòke lati Egipti jade wá lati kú li aginjù? nitoripe àkara kò sí, bẹ̃ni kò sí omi; onjẹ futẹfutẹ yi si sú ọkàn wa. OLUWA si rán ejò amubina si awọn enia na, nwọn si bù awọn enia na ṣan; ọ̀pọlọpọ ninu Israeli si kú. Nitorina li awọn enia na ṣe tọ̀ Mose wá, nwọn si wipe, Awa ti ṣẹ̀, nitoriti awa ti bá OLUWA ati iwọ sọ̀; gbadura si OLUWA ki o mú ejò wọnyi kuro lọdọ wa. Mose si gbadura fun awọn enia na. OLUWA si wi fun Mose pe, Rọ ejò amubina kan, ki o si fi i sori ọpá-gigùn kan: yio si ṣe, olukuluku ẹniti ejò ba bùṣan, nigbati o ba wò o, yio yè. Mose si rọ ejò idẹ kan, o si fi i sori ọpá-gigùn na: o si ṣe, pe bi ejò kan ba bù enia kan ṣan, nigbati o ba wò ejò idẹ na, on a yè.
Num 21:4-9 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọmọ Israẹli gbéra láti òkè Hori, wọ́n gba ọ̀nà Òkun Pupa, láti yípo lọ lẹ́yìn ilẹ̀ Edomu. Ṣugbọn sùúrù tán àwọn eniyan náà lójú ọ̀nà, wọ́n sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun ati Mose, wọ́n ní, “Kí ló dé tí ẹ fi kó wa wá láti Ijipti, pé kí á wá kú ninu aṣálẹ̀ yìí? Kò sí oúnjẹ, kò sí omi, burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ yìí ti sú wa.” OLUWA bá rán ọpọlọpọ ejò amúbíiná sí àwọn eniyan náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bù wọ́n jẹ, ọpọlọpọ ninu wọn sì kú. Wọ́n bá wá sọ́dọ̀ Mose, wọ́n ní, “A ti ṣẹ̀ nítorí tí a ti sọ̀rọ̀ òdì sí OLUWA ati sí ọ. Gbadura sí OLUWA kí ó mú ejò wọnyi kúrò lọ́dọ̀ wa.” Mose bá gbadura fún àwọn eniyan náà. OLUWA sọ fún Mose pé, “Fi idẹ rọ ejò amúbíiná kan, kí o gbé e kọ́ sórí ọ̀pá gígùn kan, ẹnikẹ́ni tí ejò bá bù jẹ, tí ó bá wo ejò idẹ náà yóo yè.” Mose bá rọ ejò idẹ kan, ó gbé e kọ́ sórí ọ̀pá gígùn kan, ẹnikẹ́ni tí ejò bá bù jẹ, tí ó bá ti wò ó, a sì yè.
Num 21:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wọ́n rin ìrìnàjò láti òkè Hori lọ sí ọ̀nà tó lọ sí Òkun Pupa, láti kọjá yípo Edomu. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn bínú ní ojú ọ̀nà; wọ́n sì sọ̀rọ̀ lòdì sí Ọlọ́run àti Mose, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde láti Ejibiti kí a ba le wá kú sí aginjù yìí? Kò sí oúnjẹ! Kò sì sí omi! Àwa sì kórìíra oúnjẹ tí kò dára yìí!” Nígbà náà ni OLúWA rán ejò olóró sí àárín wọn; wọ́n gé àwọn ènìyàn jẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Israẹli sì kú. Àwọn ènìyàn sì wá sí ọ̀dọ̀ Mose wọn wí pé, “A ti dá ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí asọ̀rọ̀-òdì sí OLúWA àti sí ìwọ pẹ̀lú. Gba àdúrà pé kí OLúWA mú ejò náà kúrò lọ́dọ̀ wa.” Nígbà náà ni Mose gbàdúrà fún àwọn ènìyàn. OLúWA sọ fún Mose pé, “Rọ ejò, a ó sì gbé e kọ́ sókè lórí igi, ẹni tí ejò bá ti gé jẹ lè wò ó yóò sì yè.” Nígbà náà ni Mose sì rọ ejò onírin ó sì gbé e kọ́ sórí igi, Bí ejò bá sì bu ẹnikẹ́ni jẹ bí ó bá ti wò ó yóò sì yè.