Num 21:1-20
Num 21:1-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹni ara Kenaani, ọba Aradi, ti ngbé ìha Gusù, gbọ́ pe Israeli gbà ọ̀na amí yọ; nigbana li o bá Israeli jà, o si mú ninu wọn ni igbekun. Israeli si jẹ́ ẹjẹ́ fun OLUWA, wipe, Bi iwọ ba fi awọn enia yi lé mi lọwọ nitõtọ, njẹ emi o run ilu wọn patapata. OLUWA si gbọ́ ohùn Israeli, o si fi awọn ara Kenaani tọrẹ, nwọn si run wọn patapata, ati ilu wọn: o si sọ orukọ ibẹ̀ na ni Horma. Nwọn si rìn lati òke Hori lọ li ọ̀na Okun Pupa, lati yi ilẹ Edomu ká: sũru si tán awọn enia na pupọ̀pupọ nitori ọ̀na na. Awọn enia na si bá Ọlọrun, ati Mose sọ̀ pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mú wa gòke lati Egipti jade wá lati kú li aginjù? nitoripe àkara kò sí, bẹ̃ni kò sí omi; onjẹ futẹfutẹ yi si sú ọkàn wa. OLUWA si rán ejò amubina si awọn enia na, nwọn si bù awọn enia na ṣan; ọ̀pọlọpọ ninu Israeli si kú. Nitorina li awọn enia na ṣe tọ̀ Mose wá, nwọn si wipe, Awa ti ṣẹ̀, nitoriti awa ti bá OLUWA ati iwọ sọ̀; gbadura si OLUWA ki o mú ejò wọnyi kuro lọdọ wa. Mose si gbadura fun awọn enia na. OLUWA si wi fun Mose pe, Rọ ejò amubina kan, ki o si fi i sori ọpá-gigùn kan: yio si ṣe, olukuluku ẹniti ejò ba bùṣan, nigbati o ba wò o, yio yè. Mose si rọ ejò idẹ kan, o si fi i sori ọpá-gigùn na: o si ṣe, pe bi ejò kan ba bù enia kan ṣan, nigbati o ba wò ejò idẹ na, on a yè. Awọn ọmọ Israeli si ṣi siwaju, nwọn si dó ni Obotu. Nwọn si ṣi lati Obotu lọ, nwọn si dó si Iye-abarimu, li aginjù ti mbẹ niwaju Moabu, ni ìha ìla-õrùn. Lati ibẹ̀ lọ nwọn ṣí, nwọn si dó si afonifoji Seredi. Lati ibẹ̀ lọ nwọn ṣí, nwọn si dó si ìha keji Arnoni, ti mbẹ li aginjù, ti o ti àgbegbe awọn ọmọ Amori wá: nitoripe Arnoni ni ipinlẹ Moabu, lãrin Moabu ati awọn Amori. Nitorina ni a ṣe wi ninu iwé Ogun OLUWA pe, Ohun ti o ṣe li Okun Pupa, ati li odò Arnoni. Ati ni iṣàn-odò nì ti o darí si ibujoko Ari, ti o si gbè ipinlẹ Moabu. Lati ibẹ̀ nwọn si lọ si Beeri: eyinì ni kanga eyiti OLUWA sọ fun Mose pe, Pe awọn enia jọ, emi o si fun wọn li omi. Nigbana ni Israeli kọrin yi pe: Sun jade iwọ kanga; ẹ ma kọrin si i: Kanga na, ti awọn olori wà, ti awọn ọlọlá awọn enia si fi ọpá-alade na, ati ọpá wọn wà. Ati lati aginjù na, nwọn lọ si Mattana. Ati Mattana nwọn lọ si Nahalieli: ati lati Nahalieli nwọn lọ si Bamotu: Ati lati Bamotu li afonifoji nì, ti mbẹ ni ilẹ Moabu, si óke Pisga, ti o si kọjusi aginjù.
Num 21:1-20 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ọba Aradi ará Kenaani tí ń gbé ìhà gúsù ní Nẹgẹbu Kenaani gbọ́ pé àwọn ọmọ Israẹli ń gba ọ̀nà Atarimu bọ̀, ó lọ bá wọn jagun, ó sì kó ninu wọn lẹ́rú. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli bá OLUWA jẹ́jẹ̀ẹ́ pé, Bí ó bá ti àwọn lẹ́yìn tí àwọn bá ṣẹgun àwọn eniyan náà, àwọn óo pa àwọn eniyan náà run patapata. OLUWA gbọ́ ohùn àwọn ọmọ Israẹli, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣẹgun àwọn ará Kenaani. Wọ́n run àwọn ati àwọn ìlú wọn patapata. Àwọn ọmọ Israẹli sì sọ ibẹ̀ ní Horima. Àwọn ọmọ Israẹli gbéra láti òkè Hori, wọ́n gba ọ̀nà Òkun Pupa, láti yípo lọ lẹ́yìn ilẹ̀ Edomu. Ṣugbọn sùúrù tán àwọn eniyan náà lójú ọ̀nà, wọ́n sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun ati Mose, wọ́n ní, “Kí ló dé tí ẹ fi kó wa wá láti Ijipti, pé kí á wá kú ninu aṣálẹ̀ yìí? Kò sí oúnjẹ, kò sí omi, burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ yìí ti sú wa.” OLUWA bá rán ọpọlọpọ ejò amúbíiná sí àwọn eniyan náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bù wọ́n jẹ, ọpọlọpọ ninu wọn sì kú. Wọ́n bá wá sọ́dọ̀ Mose, wọ́n ní, “A ti ṣẹ̀ nítorí tí a ti sọ̀rọ̀ òdì sí OLUWA ati sí ọ. Gbadura sí OLUWA kí ó mú ejò wọnyi kúrò lọ́dọ̀ wa.” Mose bá gbadura fún àwọn eniyan náà. OLUWA sọ fún Mose pé, “Fi idẹ rọ ejò amúbíiná kan, kí o gbé e kọ́ sórí ọ̀pá gígùn kan, ẹnikẹ́ni tí ejò bá bù jẹ, tí ó bá wo ejò idẹ náà yóo yè.” Mose bá rọ ejò idẹ kan, ó gbé e kọ́ sórí ọ̀pá gígùn kan, ẹnikẹ́ni tí ejò bá bù jẹ, tí ó bá ti wò ó, a sì yè. Àwọn ọmọ Israẹli ṣí kúrò níbẹ̀, wọ́n pa àgọ́ wọn sí Obotu. Lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Obotu wọ́n pa àgọ́ sí Òkè-Abarimu ní aṣálẹ̀ tí ó wà níwájú Moabu, ní ìhà ìlà oòrùn. Wọ́n gbéra láti ibẹ̀, wọ́n lọ pa àgọ́ sí àfonífojì Seredi. Wọ́n tún ṣí kúrò ní àfonífojì Seredi, wọ́n pa àgọ́ wọn sí òdìkejì odò Arinoni, tí ó wà ní aṣálẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ láti agbègbè àwọn ará Amori. Odò Arinoni jẹ́ ààlà ilẹ̀ Moabu, ó wà láàrin ilẹ̀ Moabu ati ilẹ̀ Amori. Nítorí náà ni a ṣe kọ ọ́ sinu Ìwé Ogun OLUWA pé: “Ìlú Wahebu ní agbègbè Sufa, ati àwọn àfonífojì Arinoni, ati ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àwọn àfonífojì náà tí ó lọ títí dé ìlú Ari, tí ó lọ dé ààlà Moabu.” Láti ibẹ̀, wọ́n ṣí lọ sí Beeri, níbi kànga tí ó wà níbẹ̀ ni OLUWA ti sọ fún Mose pé, “Pe àwọn eniyan náà jọ, n óo sì fún wọn ní omi.” Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí pe: “Ẹ sun omi jáde, ẹ̀yin kànga! Ẹ máa kọrin sí i! Kànga tí àwọn ọmọ aládé gbẹ́, tí àwọn olórí wà pẹlu ọ̀pá àṣẹ ọba ati ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ wọn.” Wọ́n sì ṣí kúrò níbẹ̀ lọ sí aṣálẹ̀ Matana. Láti Matana, wọ́n ṣí lọ sí Nahalieli, láti Nahalieli wọ́n ṣí lọ sí Bamotu, láti Bamotu wọ́n ṣí lọ sí àfonífojì tí ó wà ní ilẹ̀ àwọn Moabu ní ìsàlẹ̀ òkè Pisiga tí ó kọjú sí aṣálẹ̀.
Num 21:1-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ọba Aradi ará Kenaani, tí ń gbé ní gúúsù gbọ́ wí pé Israẹli ń bọ̀ wá ní ojú ọ̀nà Atarimu, ó bá Israẹli jà ó sì fi agbára mú díẹ̀ lára wọn. Nígbà náà ni Israẹli jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLúWA pé: “Bí o bá lè fi àwọn ènìyàn yìí lé wa lọ́wọ́, gbogbo ìlú wọn ni a ó parun.” OLúWA gbọ́ ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli, ó sì fi àwọn ará Kenaani lé wọn lọ́wọ́. Wọ́n pa wọ́n run pátápátá; torí náà ni a ṣe ń pe ibẹ̀ ní Horma. Wọ́n rin ìrìnàjò láti òkè Hori lọ sí ọ̀nà tó lọ sí Òkun Pupa, láti kọjá yípo Edomu. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn bínú ní ojú ọ̀nà; wọ́n sì sọ̀rọ̀ lòdì sí Ọlọ́run àti Mose, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde láti Ejibiti kí a ba le wá kú sí aginjù yìí? Kò sí oúnjẹ! Kò sì sí omi! Àwa sì kórìíra oúnjẹ tí kò dára yìí!” Nígbà náà ni OLúWA rán ejò olóró sí àárín wọn; wọ́n gé àwọn ènìyàn jẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Israẹli sì kú. Àwọn ènìyàn sì wá sí ọ̀dọ̀ Mose wọn wí pé, “A ti dá ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí asọ̀rọ̀-òdì sí OLúWA àti sí ìwọ pẹ̀lú. Gba àdúrà pé kí OLúWA mú ejò náà kúrò lọ́dọ̀ wa.” Nígbà náà ni Mose gbàdúrà fún àwọn ènìyàn. OLúWA sọ fún Mose pé, “Rọ ejò, a ó sì gbé e kọ́ sókè lórí igi, ẹni tí ejò bá ti gé jẹ lè wò ó yóò sì yè.” Nígbà náà ni Mose sì rọ ejò onírin ó sì gbé e kọ́ sórí igi, Bí ejò bá sì bu ẹnikẹ́ni jẹ bí ó bá ti wò ó yóò sì yè. Àwọn ọmọ Israẹli tẹ̀síwájú wọ́n sì péjọ sí Obotu. Wọ́n gbéra ní Obotu wọ́n sì pa ibùdó sí Iye-Abarimu, ní aginjù tí ó kọjú sí Moabu ní ìdojúkọ ìlà-oòrùn. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti gbéra wọ́n sì pa ibùdó ní Àfonífojì Seredi. Láti ibẹ̀ lọ, wọn ṣí, wọ́n sì dó sí ìhà kejì Arnoni, tí ó wà ní aginjù tí ó wà ní agbègbè ilẹ̀ àwọn ọmọ Amori. Arnoni jẹ́ ààlà fún ilẹ̀ Moabu, láàrín Moabu àti Amori. Ìdí nìyìí tí ìwé ogun OLúWA se wí pé: “…Wahebu ní Sufa, Òkun pupa àti ní odò Arnoni àti ní ìṣàn odò tí ó darí sí ibùjókòó Ari tí ó sì fi ara ti ìpínlẹ̀ Moabu.” Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ rìn dé Beeri, èyí ni kànga tí OLúWA sọ fún Mose, “Kó àwọn ènìyàn jọ èmi ó sì fún wọn ní omi.” Nígbà náà ni Israẹli kọ orin yìí pé: “Sun jáde, ìwọ kànga! Ẹ máa kọrin nípa rẹ̀, nípa kànga tí àwọn ọmọ-aládé gbẹ́, nítorí àwọn ọlọ́lá ènìyàn ni ó gbẹ́ ẹ; tí àwọn ọlọ́lá àwọn ènìyàn sì fi ọ̀pá aládé àti ọ̀pá oyè wọn gbẹ́.” Nígbà náà wọ́n kúrò láti aginjù lọ sí Mattana, láti Mattana lọ sí Nahalieli, láti Nahalieli lọ sí Bamoti, àti láti Bamoti lọ sí àfonífojì ní Moabu níbi tí òkè Pisga, tí ó wà ní òkè ilé omi ti kọjú sí aginjù.