Num 20:14-18
Num 20:14-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mose si rán onṣẹ lati Kadeṣi si ọba Edomu, wipe, Bayi ni Israeli arakunrin rẹ wi, Iwọ sá mọ̀ gbogbo ìrin ti o bá wa: Bi awọn baba wa ti sọkalẹ lọ si Egipti, ti awa si ti gbé Egipti ni ìgba pipẹ; awọn ara Egipti si ni wa lara, ati awọn baba wa: Nigbati awa si kepè OLUWA, o gbọ́ ohùn wa, o si rán angeli kan, o si mú wa lati Egipti jade wá; si kiyesi i, awa mbẹ ni Kadeṣi, ilu kan ni ipinlẹ àgbegbe rẹ: Jẹ ki awa ki o là ilẹ rẹ kọja lọ, awa bẹ̀ ọ: awa ki yio là inu oko rẹ, tabi inu ọgbà-àjara, bẹ̃li awa ki yio mu ninu omi kanga: ọ̀na opópo ọba li awa o gbà, awa ki o yà si ọwọ́ ọtún tabi si òsi, titi awa o fi kọja ipinlẹ rẹ. Edomu si wi fun u pe, Iwọ ki yio kọja lọdọ mi, ki emi ki o má ba jade si ọ ti emi ti idà.
Num 20:14-18 Yoruba Bible (YCE)
Mose rán oníṣẹ́ láti Kadeṣi sí ọba Edomu pé, “Arakunrin rẹ ni àwa ọmọ Israẹli jẹ́, o sì mọ gbogbo àwọn ìṣòro tí ó ti dé bá wa. Bí àwọn baba ńlá wa ṣe lọ sí ilẹ̀ Ijipti, tí wọ́n sì gbé ibẹ̀ fún ìgbà pípẹ́. Àwọn ará Ijipti lo àwọn baba ńlá wa ati àwa náà ní ìlò ẹrú. Nígbà tí a ké pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́, ó gbọ́ adura wa, ó sì rán angẹli rẹ̀ láti mú wa jáde kúrò ní Ijipti. Nisinsinyii a ti dé Kadeṣi, ìlú kan tí ó wà lẹ́yìn odi agbègbè rẹ. Jọ̀wọ́ gbà wá láàyè kí á gba ilẹ̀ rẹ kọjá. Àwa ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa kò ní yà kúrò ní ojú ọ̀nà sinu oko yín tabi ọgbà àjàrà yín. Bẹ́ẹ̀ ni a kò ní mu omi inú kànga yín. Ojú ọ̀nà ni a óo máa tọ̀, a kò ní yà sí ọ̀tún tabi òsì títí tí a óo fi kọjá ilẹ̀ rẹ.” Ṣugbọn àwọn ará Edomu dáhùn pé, “A kò ní jẹ́ kí ẹ gba ilẹ̀ wa kọjá, bí ẹ bá sì fẹ́ kọjá pẹlu agídí, a óo ba yín jagun.”
Num 20:14-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mose sì ránṣẹ́ láti Kadeṣi sí ọba Edomu, wí pé: “Èyí ni nǹkan tí arákùnrin rẹ Israẹli sọ: Ìwọ ti mọ̀ nípa gbogbo ìnira, tí ó wá sí orí wa. Àwọn baba ńlá wa sọ̀kalẹ̀ wá sí Ejibiti, a sì gbé ibẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn ará Ejibiti ni wá lára àti àwọn baba wa, ṣùgbọ́n nígbà tí a sọkún sí OLúWA, ó gbọ́ ẹkún wa, ó sì rán angẹli kan sí wa, ó sì mú wa jáde láti Ejibiti. “Báyìí àwa wà ní Kadeṣi, ìlú tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ rẹ. Jọ̀wọ́ jẹ́ kí a gba orílẹ̀-èdè rẹ kọjá, Àwa kì yóò gba inú oko tàbí ọgbà àjàrà rẹ kọjá, tàbí mu omi láti inú kànga. A ó ma kọjá ní òpópónà ọba, àwa kì yóò yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì títí àwa yóò fi kọjá ní ilẹ̀ rẹ.” Ṣùgbọ́n Edomu dáhùn pé: “Ẹ̀yin kò le gba ibí kọjá; bí ẹ bá dán an wò, a ó dìde ogun sí yín, a ó sì bá yín jà pẹ̀lú idà.”