Num 20:10-12
Num 20:10-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mose ati Aaroni si pe ijọ awọn enia jọ niwaju apata na, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin gbọ̀ nisisiyi, ẹnyin ọlọtẹ; ki awa ki o ha mú omi lati inu apata yi fun nyin wá bi? Mose si gbé ọwọ́ rẹ̀ soke, o si fi ọpá rẹ̀ lù apata na lẹ̃meji: omi si tú jade li ọ̀pọlọpọ, ijọ awọn enia si mu, ati ẹran wọn pẹlu. OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, Nitoriti ẹnyin kò gbà mi gbọ́, lati yà mi simimọ́ loju awọn ọmọ Israeli, nitorina ẹnyin ki yio mú ijọ awọn enia yi lọ si ilẹ na ti mo fi fun wọn.
Num 20:10-12 Yoruba Bible (YCE)
Òun ati Aaroni kó gbogbo àwọn eniyan náà jọ siwaju àpáta náà. Mose sì wí fún wọn pé, “ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀, ṣé kí á mú omi jáde fun yín láti inú àpáta yìí?” Mose bá mu ọ̀pá rẹ̀ ó fi lu àpáta náà nígbà meji, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí tú jáde lọpọlọpọ; àwọn eniyan náà ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì rí omi mu. Ṣugbọn OLUWA bínú sí Mose ati Aaroni, ó ní, “Nítorí pé ẹ kò gbà mí gbọ́, ẹ kò sì fi títóbi agbára mi hàn níwájú àwọn eniyan náà, ẹ̀yin kọ́ ni yóo kó wọn dé ilẹ̀ tí mo ti ṣèlérí láti fún wọn.”
Num 20:10-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Òun àti Aaroni pe àwọn ènìyàn jọ sí ojú kan níwájú àpáta, Mose sì sọ fún wọn, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀, àwa kì yóò lè mú omi jáde láti inú àpáta yìí wá bí?” Nígbà náà ni Mose gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ó sì fi ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ lu àpáta lẹ́ẹ̀méjì. Omi sì tú jáde, gbogbo ìjọ ènìyàn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì mu. Ṣùgbọ́n OLúWA sọ fún Mose àti Aaroni pé, “Nítorí pé ẹ̀yin kò gbà mí gbọ́ tó láti bu ọlá fún mi níwájú àwọn ọmọ Israẹli, ìwọ kò ní kó àwọn ìjọ ènìyàn yìí dé ilẹ̀ tí mo fún wọn.”