Num 20:1-13
Num 20:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
AWỌN ọmọ Israeli si wá, ani gbogbo ijọ, si aginjù Sini li oṣù kini: awọn enia na si joko ni Kadeṣi; Miriamu si kú nibẹ̀, a si sin i nibẹ̀. Omi kò si sí fun ijọ: nwọn si kó ara wọn jọ pọ̀ si Mose ati si Aaroni. Awọn enia si mbá Mose sọ̀, nwọn si wipe, Awa iba kuku ti kú nigbati awọn arakunrin wa kú niwaju OLUWA! Ẽha si ti ṣe ti ẹnyin fi mú ijọ OLUWA wá si aginjù yi, ki awa ati ẹran wá ki o kú nibẹ̀? Ẽha si ti ṣe ti ẹnyin fi mú wa gòke ti Egipti wá, lati mú wa wá si ibi buburu yi? ki iṣe ibi irugbìn, tabi ti ọpọtọ, tabi ti àjara, tabi ti pomegranate; bẹ̃ni kò sí omi lati mu. Mose ati Aaroni si lọ kuro niwaju ijọ si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, nwọn si doju wọn bolẹ: ogo OLUWA si hàn si wọn. OLUWA si sọ fun Mose pe, Mú ọpá nì, ki o si pe ijọ awọn enia jọ, iwọ, ati Aaroni arakunrin rẹ, ki ẹ sọ̀rọ si apata nì li oju wọn, yio si tú omi rẹ̀ jade; iwọ o si mú omi lati inu apata na jade fun wọn wá: iwọ o si fi fun ijọ ati fun ẹran wọn mu. Mose si mú ọpá na lati iwaju OLUWA lọ, bi o ti fun u li aṣẹ. Mose ati Aaroni si pe ijọ awọn enia jọ niwaju apata na, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin gbọ̀ nisisiyi, ẹnyin ọlọtẹ; ki awa ki o ha mú omi lati inu apata yi fun nyin wá bi? Mose si gbé ọwọ́ rẹ̀ soke, o si fi ọpá rẹ̀ lù apata na lẹ̃meji: omi si tú jade li ọ̀pọlọpọ, ijọ awọn enia si mu, ati ẹran wọn pẹlu. OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, Nitoriti ẹnyin kò gbà mi gbọ́, lati yà mi simimọ́ loju awọn ọmọ Israeli, nitorina ẹnyin ki yio mú ijọ awọn enia yi lọ si ilẹ na ti mo fi fun wọn. Wọnyi li omi Meriba; nitoriti awọn ọmọ Israeli bá OLUWA sọ̀, o si di ẹni ìya-simimọ́ ninu wọn.
Num 20:1-13 Yoruba Bible (YCE)
Ní oṣù kinni, àwọn ọmọ Israẹli dé aṣálẹ̀ Sini, wọ́n sì ṣe ibùdó wọn sí Kadeṣi. Níbẹ̀ ni Miriamu kú sí, tí wọn sì sin ín sí. Kò sí omi fún àwọn eniyan náà níbi tí wọ́n ṣe ibùdó sí, wọ́n sì kó ara wọn jọ sí Mose ati Aaroni. Wọ́n ń kùn pé: “Ìbá sàn fún wa bí ó bá jẹ́ pé a ti kú nígbà tí àwọn arakunrin wa kú níwájú OLUWA. Kí ló dé tí ẹ fi mú àwọn eniyan OLUWA wá sinu aṣálẹ̀ yìí? Ṣé kí àwa ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa lè kú ni? Kí ló dé tí ẹ fi mú wa wá láti Ijipti sí ibi burúkú yìí, kò sí ọkà, kò sí èso ọ̀pọ̀tọ́, tabi èso àjàrà tabi èso pomegiranate, bẹ́ẹ̀ ni kò sí omi mímu.” Mose ati Aaroni kúrò níwájú àwọn eniyan náà, wọ́n lọ dúró ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, wọ́n dojúbolẹ̀, ògo OLUWA sì farahàn. OLUWA sọ fún Mose pé, “Mú ọ̀pá tí ó wà níwájú Àpótí Majẹmu, kí ìwọ ati Aaroni kó àwọn eniyan náà jọ, kí o sọ̀rọ̀ sí àpáta níwájú wọn, àpáta náà yóo sì tú omi jáde. Bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe fún àwọn eniyan náà ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ní omi.” Mose lọ mú ọ̀pá náà níwájú OLUWA gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. Òun ati Aaroni kó gbogbo àwọn eniyan náà jọ siwaju àpáta náà. Mose sì wí fún wọn pé, “ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀, ṣé kí á mú omi jáde fun yín láti inú àpáta yìí?” Mose bá mu ọ̀pá rẹ̀ ó fi lu àpáta náà nígbà meji, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí tú jáde lọpọlọpọ; àwọn eniyan náà ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì rí omi mu. Ṣugbọn OLUWA bínú sí Mose ati Aaroni, ó ní, “Nítorí pé ẹ kò gbà mí gbọ́, ẹ kò sì fi títóbi agbára mi hàn níwájú àwọn eniyan náà, ẹ̀yin kọ́ ni yóo kó wọn dé ilẹ̀ tí mo ti ṣèlérí láti fún wọn.” Èyí ni omi Meriba, nítorí níbẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli ti ṣe gbolohun asọ̀ pẹlu OLUWA, tí OLUWA sì fi ara rẹ̀ hàn wọ́n pé mímọ́ ni òun.
Num 20:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní oṣù kìn-ín-ní, gbogbo àgbájọ ọmọ Israẹli gúnlẹ̀ sí pápá Sini, wọ́n sì dúró ní Kadeṣi. Níbẹ̀ ni Miriamu kú, wọ́n sì sin ín. Omi kò sí fún ìjọ ènìyàn, àwọn ènìyàn sì kó ara wọn jọ pọ̀ sí Mose àti Aaroni, Wọ́n bá Mose jà wọ́n sì wí pé, “Ìbá kúkú sàn kí a kú nígbà tí àwọn arákùnrin ti kú níwájú OLúWA! Kí ni ó dé tí o sì kó gbogbo ìjọ ènìyàn OLúWA wá sí aginjù yìí, kí àwa àti àwọn ẹran ọ̀sìn wa bá à kú síbí? Kí ni ó dé tí o fi mú wa gòkè kúrò ní Ejibiti wá sí ibi búburú yìí? Ibi tí kò ní oúnjẹ tàbí igi ọ̀pọ̀tọ́, èso àjàrà tàbí pomegiranate. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí omi tí a ó mu níhìn-ín!” Mose àti Aaroni kúrò ní ibi àpéjọ, wọ́n sì lọ dojúbolẹ̀ sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ògo OLúWA sì farahàn wọ́n. OLúWA sọ fún Mose pé, “Mú ọ̀pá, náà kí o sì pe ìjọ àwọn ènìyàn jọ, ìwọ àti Aaroni arákùnrin rẹ, kí ẹ sọ̀rọ̀ sí àpáta náà ní ojú wọn, yóò sì tú omi rẹ̀ jáde, ìwọ ó sì fún ìjọ àti ẹran wọn mu.” Báyìí ni Mose mú ọ̀pá láti iwájú OLúWA wá, gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún un. Òun àti Aaroni pe àwọn ènìyàn jọ sí ojú kan níwájú àpáta, Mose sì sọ fún wọn, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀, àwa kì yóò lè mú omi jáde láti inú àpáta yìí wá bí?” Nígbà náà ni Mose gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ó sì fi ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ lu àpáta lẹ́ẹ̀méjì. Omi sì tú jáde, gbogbo ìjọ ènìyàn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì mu. Ṣùgbọ́n OLúWA sọ fún Mose àti Aaroni pé, “Nítorí pé ẹ̀yin kò gbà mí gbọ́ tó láti bu ọlá fún mi níwájú àwọn ọmọ Israẹli, ìwọ kò ní kó àwọn ìjọ ènìyàn yìí dé ilẹ̀ tí mo fún wọn.” Èyí ni omi ti Meriba, níbi tí àwọn ọmọ Israẹli ti bá OLúWA jà àti ibi tí O ti fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni mímọ́ láàrín wọn.