Num 2:1-34

Num 2:1-34 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, Ki olukuluku awọn ọmọ Israeli ki o pa agọ́ rẹ̀ lẹba ọpagun rẹ̀, pẹlu asia ile baba wọn: ki nwọn ki o pagọ́ kọjusi agọ́ ajọ yiká. Ki awọn ti iṣe ti ọpagun ibudó Juda ki o dó ni ìha ìla-õrùn si ìha ìla-õrùn, gẹgẹ bi ogun wọn: Naṣoni ọmọ Amminadabu yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Juda. Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹtadilogoji o le ẹgbẹta. Ati awọn ti o pagọ́ gbè e ki o jẹ́ ẹ̀ya Issakari: Netaneli ọmọ Suari yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Issakari: Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹtadilọgbọ̀n o le irinwo. Ati ẹ̀ya Sebuluni: Eliabu ọmọ Heloni yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Sebuluni: Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mejidilọgbọ̀n o le egbeje. Gbogbo awọn ti a kà ni ibudó Juda jẹ́ ẹgba mẹtalelãdọrun o le irinwo, gẹgẹ bi ogun wọn. Awọn yi ni yio kọ́ ṣí. Ni ìha gusù ni ki ọpagun ibudó Reubeni ki o wà, gẹgẹ bi ogun wọn: Elisuru ọmọ Ṣedeuru yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Reubeni: Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹtalelogun o le ẹdẹgbẹta. Ati awọn ti o pagọ́ tì i ki o jẹ́ ẹ̀ya Simeoni: Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai ni yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Simeoni: Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mọkandilọgbòn o le ẹdegbeje. Ati ẹ̀ya Gadi: Eliasafu ọmọ Deueli ni yio si jẹ́ olori ogun ti awọn ọmọ Gadi: Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mejilelogun o le ãdọtalelẹgbẹjọ. Gbogbo awọn ti a kà ni ibudó Reubeni jẹ́ ẹgba marundilọgọrin o le ãdọtalelegbeje, gẹgẹ bi ogun wọn. Awọn ni yio si ṣí ṣikeji. Nigbana ni agọ́ ajọ yio si ṣí, pẹlu ibudó, awọn ọmọ Lefi lãrin ibudó: bi nwọn ti dó bẹ̃ni nwọn o ṣí, olukuluku ni ipò rẹ̀, pẹlu ọpagun wọn. Ni ìha ìwọ-õrùn ni ki ọpagun ibudó Efraimu ki o wà gẹgẹ bi ogun wọn: Eliṣama ọmọ Ammihudu yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Efraimu: Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹta. Ati lẹba rẹ̀ ni ki ẹ̀ya Manasse ki o wà: Gamalieli ọmọ Pedahsuru yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Manasse: Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹrindilogun o le igba. Ati ẹ̀ya Benjamini: Abidani ọmọ Gideoni yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Benjamini: Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹtadilogun o le egbeje. Gbogbo awọn ti a kà ni ibudó Efraimu, jẹ́ ẹgba mẹrinlelãdọta o le ọgọrun, gẹgẹ bi ogun wọn. Awọn ni yio si ṣí ṣikẹta. Ọpagun ibudó Dani ni ki o wà ni ìha ariwa gẹgẹ bi ogun wọn: Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Dani. Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mọkanlelọgbọ̀n o le ẹdẹgbẹrin. Ati awọn ti o dó tì i ni ki o jẹ́ ẹ̀ya Aṣeri: Pagieli ọmọ Okrani yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Aṣeri: Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹjọ. Ati ẹ̀ya Naftali: Ahira ọmọ Enani yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Naftali: Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹrindilọgbọ̀n o le egbeje. Gbogbo awọn ti a kà ni ibudó Dani, jẹ́ ẹgba mejidilọgọrin o le ẹgbẹjọ. Awọn ni yio ṣí kẹhin pẹlu ọpagun wọn. Eyi li awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ile baba wọn: gbogbo awọn ti a kà ni ibudó gẹgẹ bi ogun wọn, jẹ́ ọgbọ̀n ọkẹ o le egbejidilogun din ãdọta. Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi li a kò kà mọ́ awọn ọmọ Israeli; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. Awọn ọmọ Israeli si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun Mose: bẹ̃ni nwọn si dó pẹlu ọpagun wọn, bẹ̃ni nwọn si nṣí, olukuluku nipa idile wọn, gẹgẹ bi ile baba wọn.

Num 2:1-34 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé: Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli yóo bá pàgọ́ wọn, kí olukuluku máa pàgọ́ rẹ̀ lábẹ́ àsíá ẹ̀yà rẹ̀, ati lábẹ́ ọ̀págun ìdílé rẹ̀. Kí wọ́n máa pàgọ́ wọn yí Àgọ́ náà ká. Kí àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ àsíá ẹ̀yà Juda máa pàgọ́ wọn sí ìhà ìlà oòrùn ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí; Naṣoni ọmọ Aminadabu ni yóo jẹ́ olórí wọn. Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọn jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlogoji ó lé ẹgbẹta (74,600). Kí ẹ̀yà Isakari pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Juda; Netaneli ọmọ Suari ni yóo jẹ́ olórí wọn. Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọn jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlọgbọn ó lé irinwo (54,400). Kí ẹ̀yà Sebuluni pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Isakari. Eliabu ọmọ Heloni ni yóo jẹ́ olórí wọn. Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọn jẹ́ ẹgbaa mejidinlọgbọn ó lé egbeje (57,400). Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ibùdó Juda jẹ́ ẹgbaa mẹtalelaadọrun-un ó lé irinwo (186,400). Àwọn ni yóo máa ṣáájú nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá fẹ́ kó kúrò ní ibùdó kan lọ sí ibòmíràn. Àsíá ibùdó ẹ̀yà Reubẹni yóo máa wà ní ìhà gúsù ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí; Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni yóo jẹ́ olórí wọn. Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọ́n jẹ́ ẹgbaa mẹtalelogun ó lé ẹẹdẹgbẹta (46,500). Ẹ̀yà Simeoni ni yóo pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Reubẹni; Ṣelumieli ọmọ Suriṣadai ni yóo jẹ́ olórí wọn. Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọ́n jẹ́ ẹgbaa mọkandinlọgbọn ó lé eedegbeje (59,300). Ẹ̀yà Gadi ni yóo pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Simeoni; Eliasafu ọmọ Reueli ni yóo jẹ́ olórí wọn. Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọ́n jẹ́ ẹgbaa mejilelogun ó lé aadọta lé ní ẹgbẹjọ (45,650). Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ibùdó Reubẹni jẹ́ ẹgbaa marundinlọgọrin ó lé aadọta lé ní egbeje (151,450). Àwọn ni yóo máa tẹ̀lé ibùdó Juda nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá fẹ́ kó kúrò ní ibùdó kan lọ sí ibòmíràn. Lẹ́yìn náà, Àgọ́ Ẹ̀rí yóo ṣí, pẹlu àgọ́ àwọn ọmọ Lefi. Bí wọ́n ti pàgọ́ yí Àgọ́ náà ká, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo ṣe máa ṣí, olukuluku ní ipò rẹ̀, pẹlu àsíá ẹ̀yà rẹ̀. Àsíá ibùdó ẹ̀yà Efuraimu yóo máa wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn ní ìsọ̀rí-ìsọrí; Eliṣama ọmọ Amihudu ni yóo jẹ́ olórí wọn. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (40,500). Ẹ̀yà Manase ni yóo pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Efuraimu; Gamalieli, ọmọ Pedasuri, ni yóo sì jẹ́ olórí wọn. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaafa ó lé igba (32,200). Ẹ̀yà Bẹnjamini ni yóo pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Manase; Abidoni, ọmọ Gideoni ni yóo sì jẹ́ olórí wọn. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a kà jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlogun ó lé egbeje (35,400). Àpapọ̀ gbogbo àgọ́ Efuraimu ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí jẹ́ ọ̀kẹ́ marun-un ó lé ẹgbaarin ati ọgọrun-un (108,100). Àwọn ni wọn yóo jẹ́ ìpín kẹta tí àwọn ọmọ Israẹli bá fẹ́ ṣí láti ibùdó kan sí òmíràn. Àsíá ibùdó ẹ̀yà Dani yóo wà ní ìhà àríwá ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí; Ahieseri, ọmọ Amiṣadai, ni yóo jẹ́ olórí wọn. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹta ó lé ẹẹdẹgbẹsan-an (62,700). Ẹ̀yà Aṣeri ni yóo pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Dani; Pagieli, ọmọ Okirani, ni yóo sì jẹ́ olórí wọn. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹẹdẹgbẹjọ (41,500). Lẹ́yìn náà ni ẹ̀yà Nafutali; Ahira, ọmọ Enani ni yóo jẹ́ olórí wọn. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹẹdẹgbaaje ati irinwo (53,400). Àpapọ̀ gbogbo àgọ́ Efuraimu ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, jẹ́ ọ̀kẹ́ meje ó lé ẹẹdẹgbaasan-an ati ẹgbẹta (157,600). Àwọn ni wọn yóo tò sẹ́yìn patapata. Ó jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ọmọ Israẹli tí a kà, gẹ́gẹ́ bí ìdílé baba wọn. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní àgọ́ tí a kà ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹtadinlogun ati aadọjọ (603,550). Ṣugbọn a kò ka àwọn ẹ̀yà Lefi mọ́ àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún Mose. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose, wọ́n pàgọ́ ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe tẹ̀síwájú, olukuluku wà ninu ìdílé tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.

Num 2:1-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA sọ fún Mose àti Aaroni pé: “Kí àwọn ọmọ Israẹli pa àgọ́ wọn yí àgọ́ ìpàdé ká, kí wọ́n jẹ́ kí àgọ́ wọn jìnnà sí i díẹ̀, oníkálùkù lábẹ́ ọ̀págun pẹ̀lú àsíá ìdílé wọn.” Ní ìlà-oòrùn, ní ìdojúkọ àtiyọ oòrùn: ni kí ìpín ti Juda pa ibùdó wọn sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Juda ni Nahiṣoni ọmọ Amminadabu. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàdínlógójì ó-lé-ẹgbẹ̀ta (74,600). Ẹ̀yà Isakari ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Isakari ni Netaneli ọmọ Ṣuari. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó-lé-irínwó (54,400). Ẹ̀yà Sebuluni ni yóò tẹ̀lé e. Olórí Sebuluni ni Eliabu ọmọ Heloni. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-méjì-dínlọ́gbọ̀n ó-lé-egbèje (57,400). Gbogbo àwọn tí a yàn sí ibùdó Juda, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàléláàdọ́run ó-lé-irínwó (186,400). Àwọn ni yóò kọ́kọ́ ṣáájú. Ní ìhà gúúsù: ni ìpín ti Reubeni pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Reubeni ni Elisuri ọmọ Ṣedeuri. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàlélógún ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (46,500). Ẹ̀yà Simeoni ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Simoni ni Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbéje. (59,300). Ẹ̀yà Gadi ló tẹ̀lé wọn. Olórí Gadi ni Eliasafu ọmọ Deueli. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-méjìlélógún ó-lé-àádọ́ta-lé-ẹgbẹ̀jọ (45,650). Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Reubeni, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá-márùn-dínlọ́gọ́rin ó-lé-àádọ́ta-lé-légbéje (151,450). Àwọn ni yóò jáde sìkéjì. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Lefi Àti àgọ́ ìpàdé yóò tẹ̀síwájú láàrín ibùdó àwọn ènìyàn, wọn yóò tẹ̀síwájú ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe pa ibùdó, olúkúlùkù láààyè rẹ̀, àti lábẹ́ ọ̀págun rẹ̀. Ní ìhà ìlà-oòrùn: ni ìpín Efraimu yóò pa ibùdó rẹ̀ sí lábẹ́ ọ́págun rẹ̀. Olórí Efraimu ni Eliṣama ọmọ Ammihudu. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (40,500). Ẹ̀yà Manase ni yóò tẹ̀lé wọn. Olórí Manase ni Gamalieli ọmọ Pedasuri. Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá-mẹ́rìn-dínlógún ó-lé-igba (32,200). Ẹ̀yà Benjamini ni yóò tẹ̀lé e. Olórí Benjamini ni Abidani ọmọ Gideoni. Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá-mẹ́tà-dínlógún ó-lé-egbèje (35,400). Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Efraimu, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìnléláàdọ́ta ó-lé-ọgọ́rùn-ún (108,100). Àwọn ni yóò jáde sìkẹ́ta. Ní ìhà àríwá: ni ìpín Dani yóò pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Dani ni Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlélọ̀gbọ̀n ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin. (62,700). Ẹ̀yà Aṣeri ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Aṣeri ni Pagieli ọmọ Okanri. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (41,500). Ẹ̀yà Naftali ni yóò kàn lẹ́yìn wọn. Olórí Naftali ni Ahira ọmọ Enani. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìn-dínlógún ó-lé-egbèje (53,400). Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Dani jẹ́ ẹgbàá-méjì-dínlọ́gọ̀rin ó-lé-ẹgbẹ̀jọ (157,600). Àwọn ni yóò jáde kẹ́yìn lábẹ́ ọ̀págun wọn. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n kà nípa ìdílé wọn. Gbogbo àwọn tó wà ní ibùdó, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó-lé-egbéjì-dínlógún-dínàádọ́ta (603,550). Ṣùgbọ́n a kò ka àwọn ọmọ Lefi papọ̀ mọ́ àwọn Israẹli gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pa á láṣẹ fún Mose. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe gbogbo ohun tí OLúWA pàṣẹ fún Mose, báyìí ni wọ́n ṣe pa ibùdó lábẹ́ ọ̀págun wọn, bẹ́ẹ̀ náà sì ni wọ́n ṣe jáde, oníkálùkù pẹ̀lú ẹbí àti ìdílé rẹ̀.