Num 19:2-10

Num 19:2-10 Bibeli Mimọ (YBCV)

Eyi ni ìlana ofin, ti OLUWA palaṣẹ, wipe, Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o mú ẹgbọrọ abomalu pupa kan tọ̀ ọ wá, alailabawọ́n, ati alailabùku, ati lara eyiti a kò ti dì àjaga mọ́: Ki ẹnyin si fi i fun Eleasari alufa, ki on ki o mú u jade lọ sẹhin ibudó, ki ẹnikan ki o si pa a niwaju rẹ̀: Ki Eleasari alufa, ki o fi iká rẹ̀ mú ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, ki o si fi ninu ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n iwaju agọ́ ajọ ni ìgba meje. Ki ẹnikan ki o si sun ẹgbọrọ abomalu na li oju rẹ̀; awọ rẹ̀, ati ẹran rẹ̀, ati ẹ̀jẹ rẹ̀, pẹlu igbẹ́ rẹ̀, ni ki o sun: Ki alufa na ki o mú igi opepe, ati hissopu, ati ododó, ki o si jù u sãrin ẹgbọrọ abomalu ti a nsun. Nigbana ni ki alufa na ki o fọ̀ ãṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, lẹhin na ki o si wá si ibudó, ki alufa na ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. Ki ẹniti o sun u ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀ ninu omi, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. Ki ọkunrin kan ti o mọ́ ki o si kó ẽru ẹgbọrọ abomalu na, ki o si kó o jọ si ibi kan ti o mọ́ lẹhin ibudó, ki a si pa a mọ́ fun ijọ awọn ọmọ Israeli fun omi ìyasapakan: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni. Ki ẹniti o si kó ẽru ẹgbọrọ abomalu na ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: yio si jẹ́ ilana titilai, fun awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ti nṣe atipo ninu wọn.

Num 19:2-10 Yoruba Bible (YCE)

“Ìlànà tí èmi OLUWA fi lélẹ̀ nìyí: Ẹ sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọ́n mú ẹgbọ̀rọ̀ abo mààlúù pupa kan wá. Kò gbọdọ̀ ní àbààwọ́n kankan, wọn kò sì gbọdọ̀ tíì fi ṣiṣẹ́ rí. O óo fún Eleasari alufaa, yóo mú un lọ sí ẹ̀yìn ibùdó, wọn óo sì pa á níbẹ̀ níṣojú rẹ̀. Eleasari yóo gbà ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, yóo fi ìka rẹ̀ wọ́n ọn sí apá ìhà Àgọ́ Àjọ ní ìgbà meje. Kí wọ́n sun ìyókù mààlúù náà: awọ rẹ̀ ati ẹran ara rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ati ìgbẹ́ rẹ̀; kí wọ́n sun gbogbo rẹ̀ níwájú alufaa. Kí alufaa ju igi kedari ati hisopu ati aṣọ pupa sinu iná náà. Lẹ́yìn náà kí ó wẹ̀, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì pada sí ibùdó. Ṣugbọn yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. Ẹni tí ó sun mààlúù náà gbọdọ̀ wẹ̀ kí ó sì fọ aṣọ rẹ̀, òun náà yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. Ẹnìkan tí ó jẹ́ mímọ́ yóo kó eérú mààlúù náà jọ sí ibìkan tí ó mọ́ lẹ́yìn ibùdó. Eérú náà ni àwọn ọmọ Israẹli yóo máa lò fún omi ìwẹ̀nùmọ́, fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹni tí ó bá kó eérú náà jọ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, òun náà yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. Èyí yóo jẹ́ ìlànà fún àwọn ọmọ Israẹli ati fún àwọn àlejò tí ó wà láàrin wọn títí lae.

Num 19:2-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Èyí ni ohun tí òfin OLúWA pàṣẹ béèrè lọ́wọ́ yín: Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí wọn mú ẹgbọrọ ọ̀dọ́ màlúù pupa tí kò lábùkù tàbí àbàwọ́n, lára èyí tí a kò tí ì di àjàgà mọ́. Ẹ mú fún Eleasari àlùfáà, yóò sì mu jáde lọ sí ẹ̀yìn ibùdó kí ó sì pa á ní ojú rẹ. Nígbà náà ni Eleasari àlùfáà yóò mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sórí ìka ọwọ́ rẹ̀ yóò sì wọn lẹ́ẹ̀méje ní ọ̀kánkán iwájú àgọ́ ìpàdé. Ní ojú rẹ̀ ni àlùfáà yóò ti sun ọ̀dọ́ abo màlúù yìí: awọ ara rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹran-ara àti ìgbẹ́ rẹ̀. Àlùfáà yóò mú igi kedari, hísópù àti òwú òdòdó yóò sì jù wọ́n sí àárín ọ̀dọ́ abo màlúù tí a ń sun. Lẹ́yìn náà, àlùfáà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi lẹ́yìn náà ó lè wá sínú àgọ́. Ṣùgbọ́n yóò jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Ẹni tí ó sun ún náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ pẹ̀lú omi, òun náà yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. “Ẹni tó wà ní mímọ́ ni yóò kó eérú ọ̀dọ́ màlúù náà lọ sí ibi tí a yà sí mímọ́ lẹ́yìn ibùdó. Kí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli kó o pamọ́ fún lílò fún omi ìwẹ̀nùmọ́. Ó jẹ́ ìwẹ̀nùmọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. Ọkùnrin tí ó kó eérú ọ̀dọ́ abo màlúù náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, òun náà yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà láéláé fún àwọn ọmọ Israẹli àti fún àwọn àjèjì tí ó ń gbé láàrín wọn.