Num 19:17-19
Num 19:17-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati fun ẹni aimọ́ kan ki nwọn ki o mú ninu ẽru sisun ẹbọ ẹ̀ṣẹ nì, ki a si bù omi ti nṣàn si i ninu ohun-èlo kan: Ki ẹnikan ti o mọ́ ki o si mú hissopu, ki o si tẹ̀ ẹ bọ̀ inu omi na, ki o si fi i wọ́n agọ́ na, ati ohun-èlo gbogbo, ati sara awọn enia ti o wá nibẹ̀, ati sara ẹniti o fọwọkàn egungun kan, tabi ẹnikan ti a pa, tabi ẹnikan ti o kú, tabi isà-okú: Ki ẹniti o mọ́ na ki o si bùwọ́n alaimọ́ na ni ijọ́ kẹta, ati ni ijọ́ keje: ati ni ijọ́ keje ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́; ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omì, yio si di mimọ́ li aṣalẹ.
Num 19:17-19 Yoruba Bible (YCE)
“Tí ẹ bá fẹ́ ṣe ìwẹ̀nùmọ́ wọn, ẹnìkan tí ó jẹ́ mímọ́ yóo mú lára eérú mààlúù pupa tí a sun fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, yóo bu omi odò tí ń ṣàn sí i. Lẹ́yìn náà yóo mú hisopu, yóo tì í bọ omi náà, yóo sì fi wọ́n àgọ́ náà ati àwọn ohun èlò tí wọ́n wà ninu rẹ̀ ati àwọn eniyan tí wọ́n wà ninu rẹ̀. Yóo fi wọ́n ẹni tí ó fọwọ́ kan egungun òkú tabi tí ó fọwọ́ kan ẹni tí wọ́n pa, tabi ẹni tí ó kú fúnrarẹ̀, tabi ibojì òkú. Yóo sì bu omi náà wọ́n aláìmọ́ náà ní ọjọ́ kẹta ati ikeje. Ní ọjọ́ keje, yóo wẹ̀, yóo sì di mímọ́. Aláìmọ́ náà yóo fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì wẹ̀ ninu omi, yóo sì di mímọ́ ní ìrọ̀lẹ́.
Num 19:17-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Fún aláìmọ́ ènìyàn, mú eérú díẹ̀ lára eérú ọrẹ ìwẹ̀nùmọ́ sínú ìgò, kí o sì da omi tó ń sàn lé e lórí. Nígbà náà, ọkùnrin tí a yà sí mímọ́ yóò mú hísópù díẹ̀ yóò rì í sínú omi yóò sì fi wọ́n àgọ́ àti gbogbo ohun èlò tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ àti àwọn ènìyàn tí ó wà níbẹ̀. O gbọdọ̀ tún fi wọ́n ẹnikẹ́ni tí ó fi ọwọ́ kan egungun òkú ènìyàn tàbí isà òkú, tàbí ẹni tí ó kú ikú ara rẹ̀, tàbí ẹni tí ó kú ikú àti ọ̀run wá. Ọkùnrin tí ó mọ́ ni kí ó bu omi wọ́n àwọn ènìyàn aláìmọ́ ní ọjọ́ kẹta àti ọjọ́ keje, ní ọjọ́ keje ó gbọdọ̀ wẹ ara rẹ̀ mọ́, Ẹni tí a wẹ̀mọ́ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ pẹ̀lú omi, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà yóò mọ́.