Num 19:1-22

Num 19:1-22 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, Eyi ni ìlana ofin, ti OLUWA palaṣẹ, wipe, Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o mú ẹgbọrọ abomalu pupa kan tọ̀ ọ wá, alailabawọ́n, ati alailabùku, ati lara eyiti a kò ti dì àjaga mọ́: Ki ẹnyin si fi i fun Eleasari alufa, ki on ki o mú u jade lọ sẹhin ibudó, ki ẹnikan ki o si pa a niwaju rẹ̀: Ki Eleasari alufa, ki o fi iká rẹ̀ mú ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, ki o si fi ninu ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n iwaju agọ́ ajọ ni ìgba meje. Ki ẹnikan ki o si sun ẹgbọrọ abomalu na li oju rẹ̀; awọ rẹ̀, ati ẹran rẹ̀, ati ẹ̀jẹ rẹ̀, pẹlu igbẹ́ rẹ̀, ni ki o sun: Ki alufa na ki o mú igi opepe, ati hissopu, ati ododó, ki o si jù u sãrin ẹgbọrọ abomalu ti a nsun. Nigbana ni ki alufa na ki o fọ̀ ãṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, lẹhin na ki o si wá si ibudó, ki alufa na ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. Ki ẹniti o sun u ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀ ninu omi, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. Ki ọkunrin kan ti o mọ́ ki o si kó ẽru ẹgbọrọ abomalu na, ki o si kó o jọ si ibi kan ti o mọ́ lẹhin ibudó, ki a si pa a mọ́ fun ijọ awọn ọmọ Israeli fun omi ìyasapakan: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni. Ki ẹniti o si kó ẽru ẹgbọrọ abomalu na ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: yio si jẹ́ ilana titilai, fun awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ti nṣe atipo ninu wọn. Ẹniti o ba fọwọkàn okú ẹnikan ki o jẹ́ alaimọ ni ijọ́ meje. Ki oluwarẹ̀ ki o fi i wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́ ni ijọ́ kẹta, ati ni ijọ́ keje yio di mimọ́: ṣugbọn bi kò ba wẹ̀ ara rẹ̀ ni ijọ́ kẹta, njẹ ni ijọ́ keje ki yio di mimọ́. Ẹnikẹni ti o ba fọwọkàn okú ẹnikan ti o kú, ti kò si wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́, o bà agọ́ OLUWA jẹ́; ọkàn na li a o si ke kuro ninu Israeli: nitoriti a kò wọ́n omi ìyasapakan si i lara, alaimọ́ li o jẹ̀; aimọ́ rẹ̀ mbẹ lara rẹ̀ sibẹ̀, Eyi li ofin na, nigbati enia kan ba kú ninu agọ́ kan: gbogbo ẹniti o wọ̀ inu agọ́ na, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu agọ́ na, yio jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje. Ati ohun-èlo gbogbo ti o ṣi silẹ, ti kò ní ideri lori rẹ̀, alaimọ́ ni. Ẹnikẹni ti o ba si fọwọkàn ẹnikan ti a fi idà pa ni gbangba igbẹ́, tabi okú kan, tabi egungun ẹnikan, tabi isà-okú, yio jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje. Ati fun ẹni aimọ́ kan ki nwọn ki o mú ninu ẽru sisun ẹbọ ẹ̀ṣẹ nì, ki a si bù omi ti nṣàn si i ninu ohun-èlo kan: Ki ẹnikan ti o mọ́ ki o si mú hissopu, ki o si tẹ̀ ẹ bọ̀ inu omi na, ki o si fi i wọ́n agọ́ na, ati ohun-èlo gbogbo, ati sara awọn enia ti o wá nibẹ̀, ati sara ẹniti o fọwọkàn egungun kan, tabi ẹnikan ti a pa, tabi ẹnikan ti o kú, tabi isà-okú: Ki ẹniti o mọ́ na ki o si bùwọ́n alaimọ́ na ni ijọ́ kẹta, ati ni ijọ́ keje: ati ni ijọ́ keje ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́; ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omì, yio si di mimọ́ li aṣalẹ. Ṣugbọn ẹniti o ba jẹ́ alaimọ́, ti kò ba wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́, ọkàn na li a o ke kuro ninu ijọ, nitoriti o bà ibi-mimọ́ OLUWA jẹ́: a kò si ta omi ìyasapakan si i lara; alaimọ́ li on. Yio si ma jẹ́ ìlana lailai fun wọn, pe ẹniti o ba bú omi ìyasapakan wọ́n ẹni, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀; ati ẹniti o si fọwọkàn omi ìyasapakan na yio jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ. Ati ohunkohun ti ẹni aimọ́ na ba si farakàn, yio jẹ́ alaimọ́; ọkàn ti o ba si farakàn a, yio jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

Num 19:1-22 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé, “Ìlànà tí èmi OLUWA fi lélẹ̀ nìyí: Ẹ sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọ́n mú ẹgbọ̀rọ̀ abo mààlúù pupa kan wá. Kò gbọdọ̀ ní àbààwọ́n kankan, wọn kò sì gbọdọ̀ tíì fi ṣiṣẹ́ rí. O óo fún Eleasari alufaa, yóo mú un lọ sí ẹ̀yìn ibùdó, wọn óo sì pa á níbẹ̀ níṣojú rẹ̀. Eleasari yóo gbà ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, yóo fi ìka rẹ̀ wọ́n ọn sí apá ìhà Àgọ́ Àjọ ní ìgbà meje. Kí wọ́n sun ìyókù mààlúù náà: awọ rẹ̀ ati ẹran ara rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ati ìgbẹ́ rẹ̀; kí wọ́n sun gbogbo rẹ̀ níwájú alufaa. Kí alufaa ju igi kedari ati hisopu ati aṣọ pupa sinu iná náà. Lẹ́yìn náà kí ó wẹ̀, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì pada sí ibùdó. Ṣugbọn yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. Ẹni tí ó sun mààlúù náà gbọdọ̀ wẹ̀ kí ó sì fọ aṣọ rẹ̀, òun náà yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. Ẹnìkan tí ó jẹ́ mímọ́ yóo kó eérú mààlúù náà jọ sí ibìkan tí ó mọ́ lẹ́yìn ibùdó. Eérú náà ni àwọn ọmọ Israẹli yóo máa lò fún omi ìwẹ̀nùmọ́, fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹni tí ó bá kó eérú náà jọ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, òun náà yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. Èyí yóo jẹ́ ìlànà fún àwọn ọmọ Israẹli ati fún àwọn àlejò tí ó wà láàrin wọn títí lae. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú yóo jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ meje. Ní ọjọ́ kẹta ati ọjọ́ keje, yóo wẹ ara rẹ̀ pẹlu omi ìwẹ̀nùmọ́, yóo sì di mímọ́. Kò ní di mímọ́ bí kò bá wẹ ara rẹ̀ ní ọjọ́ kẹta ati ọjọ́ keje. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú, tí kò bá fi omi ìwẹ̀nùmọ́ wẹ̀, yóo sọ ibi mímọ́ OLUWA di aláìmọ́. A óo yọ olúwarẹ̀ kúrò láàrin ọmọ Israẹli, nítorí kò fi omi ìwẹ̀nùmọ́ wẹ̀; ó sì jẹ́ aláìmọ́ sibẹ. “Tí ẹnìkan bá kú ninu àgọ́ kan ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ninu àgọ́ náà, ati ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ ibẹ̀ yóo di aláìmọ́ fún ọjọ́ meje. Gbogbo ohun èlò tí ó bá wà ninu àgọ́ náà tí wọn kò fi ọmọrí dé di aláìmọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ẹni tí wọ́n fi idà pa, tabi òkú, tabi egungun òkú tabi ibojì òkú ninu pápá yóo di aláìmọ́ fún ọjọ́ meje. “Tí ẹ bá fẹ́ ṣe ìwẹ̀nùmọ́ wọn, ẹnìkan tí ó jẹ́ mímọ́ yóo mú lára eérú mààlúù pupa tí a sun fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, yóo bu omi odò tí ń ṣàn sí i. Lẹ́yìn náà yóo mú hisopu, yóo tì í bọ omi náà, yóo sì fi wọ́n àgọ́ náà ati àwọn ohun èlò tí wọ́n wà ninu rẹ̀ ati àwọn eniyan tí wọ́n wà ninu rẹ̀. Yóo fi wọ́n ẹni tí ó fọwọ́ kan egungun òkú tabi tí ó fọwọ́ kan ẹni tí wọ́n pa, tabi ẹni tí ó kú fúnrarẹ̀, tabi ibojì òkú. Yóo sì bu omi náà wọ́n aláìmọ́ náà ní ọjọ́ kẹta ati ikeje. Ní ọjọ́ keje, yóo wẹ̀, yóo sì di mímọ́. Aláìmọ́ náà yóo fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì wẹ̀ ninu omi, yóo sì di mímọ́ ní ìrọ̀lẹ́. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ aláìmọ́ tí kò sì ṣe ìwẹ̀nùmọ́, yóo jẹ́ aláìmọ́ sibẹ nítorí pé a kò tíì da omi ìwẹ̀nùmọ́ sí i lára. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ sọ ibi mímọ́ OLUWA di aláìmọ́. A óo yọ olúwarẹ̀ kúrò láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Ẹ gbọdọ̀ pa ìlànà yìí mọ́ láti ìrandíran. Ẹni tí ó bá wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ náà sí aláìmọ́ lára gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan omi náà yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. Ohunkohun tí aláìmọ́ bá fọwọ́ kàn yóo di aláìmọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fọwọ́ kan ohun tí aláìmọ́ náà bá fọwọ́ kàn yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.”

Num 19:1-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA sọ fún Mose àti Aaroni pé: “Èyí ni ohun tí òfin OLúWA pàṣẹ béèrè lọ́wọ́ yín: Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí wọn mú ẹgbọrọ ọ̀dọ́ màlúù pupa tí kò lábùkù tàbí àbàwọ́n, lára èyí tí a kò tí ì di àjàgà mọ́. Ẹ mú fún Eleasari àlùfáà, yóò sì mu jáde lọ sí ẹ̀yìn ibùdó kí ó sì pa á ní ojú rẹ. Nígbà náà ni Eleasari àlùfáà yóò mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sórí ìka ọwọ́ rẹ̀ yóò sì wọn lẹ́ẹ̀méje ní ọ̀kánkán iwájú àgọ́ ìpàdé. Ní ojú rẹ̀ ni àlùfáà yóò ti sun ọ̀dọ́ abo màlúù yìí: awọ ara rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹran-ara àti ìgbẹ́ rẹ̀. Àlùfáà yóò mú igi kedari, hísópù àti òwú òdòdó yóò sì jù wọ́n sí àárín ọ̀dọ́ abo màlúù tí a ń sun. Lẹ́yìn náà, àlùfáà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi lẹ́yìn náà ó lè wá sínú àgọ́. Ṣùgbọ́n yóò jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Ẹni tí ó sun ún náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ pẹ̀lú omi, òun náà yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. “Ẹni tó wà ní mímọ́ ni yóò kó eérú ọ̀dọ́ màlúù náà lọ sí ibi tí a yà sí mímọ́ lẹ́yìn ibùdó. Kí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli kó o pamọ́ fún lílò fún omi ìwẹ̀nùmọ́. Ó jẹ́ ìwẹ̀nùmọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. Ọkùnrin tí ó kó eérú ọ̀dọ́ abo màlúù náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, òun náà yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà láéláé fún àwọn ọmọ Israẹli àti fún àwọn àjèjì tí ó ń gbé láàrín wọn. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú ẹnikẹ́ni, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje. Ó gbọdọ̀ wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje; nígbà náà ni yóò jẹ́ mímọ́. Ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ pé kò wẹ ara rẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje yóò jẹ́ aláìmọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú ẹnìkan tí kò sì wẹ ara rẹ̀ mọ́, ó ba àgọ́ OLúWA jẹ́. A ó ké irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ọmọ Israẹli. Nítorí pé a kò tí ì wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ lé e lórí, ó jẹ́ aláìmọ́, àìmọ́ rẹ̀ sì wà lára rẹ̀. “Èyí ni òfin tí ó jẹ mọ́ bí ènìyàn bá kú nínú àgọ́: Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ inú àgọ́ àti ẹni tí ó wà nínú àgọ́ yóò di aláìmọ́ fún ọjọ́ méje, Gbogbo ohun èlò tí a kò bá fi omọrí dé ni yóò jẹ́ aláìmọ́. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ní ìta tí ó sì fi ọwọ́ kan ẹni tí a fi idà pa tàbí ẹni tí ó kú ikú àtọ̀runwá, tàbí bí ẹnìkan bá fi ọwọ́ kan egungun òkú ènìyàn tàbí isà òkú, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje. “Fún aláìmọ́ ènìyàn, mú eérú díẹ̀ lára eérú ọrẹ ìwẹ̀nùmọ́ sínú ìgò, kí o sì da omi tó ń sàn lé e lórí. Nígbà náà, ọkùnrin tí a yà sí mímọ́ yóò mú hísópù díẹ̀ yóò rì í sínú omi yóò sì fi wọ́n àgọ́ àti gbogbo ohun èlò tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ àti àwọn ènìyàn tí ó wà níbẹ̀. O gbọdọ̀ tún fi wọ́n ẹnikẹ́ni tí ó fi ọwọ́ kan egungun òkú ènìyàn tàbí isà òkú, tàbí ẹni tí ó kú ikú ara rẹ̀, tàbí ẹni tí ó kú ikú àti ọ̀run wá. Ọkùnrin tí ó mọ́ ni kí ó bu omi wọ́n àwọn ènìyàn aláìmọ́ ní ọjọ́ kẹta àti ọjọ́ keje, ní ọjọ́ keje ó gbọdọ̀ wẹ ara rẹ̀ mọ́, Ẹni tí a wẹ̀mọ́ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ pẹ̀lú omi, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà yóò mọ́. Ṣùgbọ́n bí ẹni tí ó bá jẹ́ aláìmọ́ kò bá wẹ ara rẹ̀ mọ́, a gbọdọ̀ gé e kúrò nínú ìjọ ènìyàn, nítorí wí pé ó ti ba àgọ́ OLúWA jẹ́. A kò tí ì fi omi ìwẹ̀nùmọ́ sí ara rẹ̀, ó sì jẹ́ aláìmọ́. Èyí jẹ́ ìlànà láéláé fún wọn. “Ọkùnrin tí ó wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ àti ẹnikẹ́ni tí ó fi ọwọ́ kan omi ìwẹ̀nùmọ́ yóò di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Gbogbo ohun tí ẹni tí ó jẹ́ aláìmọ́ bá fi ọwọ́ kàn yóò di àìmọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ọwọ́ kàn án yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.”