Num 18:1-32
Num 18:1-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si sọ fun Aaroni pe, Iwọ ati awọn ọmọ rẹ, ati ile baba rẹ pẹlu rẹ, ni yio ma rù ẹ̀ṣẹ ibi-mimọ́: ati iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio ma rù ẹ̀ṣẹ iṣẹ-alufa nyin. Ati awọn arakunrin rẹ pẹlu, ẹ̀ya Lefi, ẹ̀ya baba rẹ, ni ki o múwa pẹlu rẹ, ki nwọn ki o le dàpọ pẹlu rẹ, ki nwọn ki o ma ṣe iranṣẹ fun ọ: ṣugbọn iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio ma ṣe iranṣẹ niwaju agọ́ ẹrí. Ki nwọn ki o ma pa aṣẹ rẹ mọ́, ki nwọn ki o si ma ṣe itọju gbogbo agọ́, kìki pe nwọn kò gbọdọ sunmọ ohun-èlo ibi-mimọ́ ati pẹpẹ, ki ati awọn, ati ẹnyin pẹlu ki o má ba kú. Ki nwọn ki o si dàpọ pẹlu rẹ, ki nwọn ki o si ma ṣe itọju agọ́ ajọ, gẹgẹ bi gbogbo iṣẹ-ìsin agọ́: alejò kan kò sí gbọdọ sunmọ ọdọ nyin. Ki ẹnyin ki o si ma ṣe itọju ibi-mimọ́, ati itọju pẹpẹ: ki ibinu ki o má ba sí mọ́ lori awọn ọmọ Israeli. Ati emi, kiyesi i, mo ti mú awọn arakunrin nyin, awọn ọmọ Lefi kuro ninu awọn ọmọ Israeli: ẹnyin li a fi wọn fun bi ẹ̀bun fun OLUWA, lati ma ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ. Iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio si ma ṣe itọju iṣẹ-alufa nyin niti ohun gbogbo ti iṣe ti pẹpẹ, ati ti inu aṣọ-ikele: ẹnyin o si ma sìn: emi ti fi iṣẹ-alufa nyin fun nyin, bi iṣẹ-ìsin ẹ̀bun: alejò ti o ba si sunmọtosi li a o pa. OLUWA si sọ fun Aaroni pe, Kiyesi i, emi si ti fi itọju ẹbọ igbesọsoke mi fun ọ pẹlu, ani gbogbo ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli, iwọ li emi fi wọn fun ni ipín, ati fun awọn ọmọ rẹ, bi ipín lailai. Eyi ni yio ṣe tirẹ ninu ohun mimọ́ julọ, ti a mú kuro ninu iná; gbogbo ọrẹ-ẹbọ wọn, gbogbo ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati gbogbo ẹbọ ẹ̀ṣẹ wọn, ati gbogbo ẹbọ ẹbi wọn, ti nwọn o mú fun mi wá, mimọ́ julọ ni yio jasi fun iwọ ati fun awọn ọmọ rẹ. Bi ohun mimọ́ julọ ni ki iwọ ki o ma jẹ ẹ: gbogbo ọkunrin ni yio jẹ ẹ; mimọ́ ni yio jẹ́ fun ọ. Eyi si ni tirẹ; ẹbọ igbesọsoke ẹ̀bun wọn, pẹlu gbogbo ẹbọ fifì awọn ọmọ Israeli: emi ti fi wọn fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati fun awọn ọmọ rẹ obinrin pẹlu rẹ, bi ipín lailai: gbogbo awọn ti o mọ́ ninu ile rẹ ni ki o jẹ ẹ. Gbogbo oróro daradara, ati gbogbo ọti-waini daradara, ati alikama, akọ́so ninu wọn ti nwọn o mú fun OLUWA wá, iwọ ni mo fi wọn fun. Akọ́so gbogbo ohun ti o wà ni ilẹ wọn, ti nwọn o mú fun OLUWA wá, tirẹ ni yio jẹ́; gbogbo ẹniti o mọ́ ni ile rẹ ni ki o jẹ ẹ. Ohun ìyasọtọ gbogbo ni Israeli ni ki o jẹ́ tirẹ. Gbogbo akọ́bi ninu gbogbo ohun alãye, ti nwọn o mú wa fun OLUWA, iba ṣe ti enia tabi ti ẹranko, ki o jẹ́ tirẹ: ṣugbọn rirà ni iwọ o rà akọ́bi enia silẹ, ati akọ́bi ẹran alaimọ́ ni ki iwọ ki o rà silẹ. Gbogbo awọn ti a o ràsilẹ, lati ẹni oṣù kan ni ki iwọ ki o ràsilẹ, gẹgẹ bi idiyelé rẹ, li owo ṣekeli marun, nipa ṣekeli ibi-mimọ́ (ti o jẹ́ ogun gera). Ṣugbọn akọ́bi akọmalu, tabi akọbi agutan, tabi akọ́bi ewurẹ, ni iwọ kò gbọdọ ràsilẹ; mimọ́ ni nwọn: ẹ̀jẹ wọn ni ki iwọ ki o ta sori pẹpẹ, ki iwọ ki o si sun ọrá wọn li ẹbọ ti a fi iná ṣe, fun õrùn didùn si OLUWA. Ki ẹran wọn ki o si jẹ́ tirẹ, bi àiya fifì, ati bi itan ọtún, ni yio jẹ́ tirẹ. Gbogbo ẹbọ igbesọsoke ohun mimọ́ wọnni, ti awọn ọmọ Israeli múwa fun OLUWA, ni mo ti fi fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati fun awọn ọmọ rẹ obinrin pẹlu rẹ, bi ipín lailai: majẹmu iyọ̀ ni lailai niwaju OLUWA fun ọ ati fun irú-ọmọ rẹ pẹlu rẹ. OLUWA si sọ fun Aaroni pe, Iwọ ki yio ní iní ninu ilẹ wọn, bẹ̃ni iwọ ki yio ní ipín lãrin wọn: Emi ni ipín rẹ ati iní rẹ lãrin awọn ọmọ Israeli. Si kiyesi i, emi si ti fi gbogbo idamẹwa ni Israeli fun awọn ọmọ Lefi ni iní, nitori iṣẹ-ìsin wọn ti nwọn nṣe, ani iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ. Awọn ọmọ Israeli kò si gbọdọ sunmọ agọ́ ajọ, ki nwọn ki o má ba rù ẹ̀ṣẹ, ki nwọn má ba kú. Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi ni ki o ma ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ, awọn ni yio si ma rù ẹ̀ṣẹ wọn: ìlana lailai ni ni iran-iran nyin, ati lãrin awọn ọmọ Israeli, nwọn kò gbọdọ ní ilẹ-iní. Nitori idamẹwa awọn ọmọ Israeli, ti nwọn múwa li ẹbọ igbesọsoke fun OLUWA, ni mo ti fi fun awọn ọmọ Lefi lati ní: nitorina ni mo ṣe wi fun wọn pe, Nwọn kò gbọdọ ní ilẹ-iní lãrin awọn ọmọ Israeli. OLUWA si sọ fun Mose pe, Si sọ fun awọn ọmọ Lefi, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba ngbà idamẹwa ti mo ti fi fun nyin ni ilẹiní nyin lọwọ awọn ọmọ Israeli, nigbana ni ki ẹnyin ki o mú ẹbọ igbesọsoke ninu rẹ̀ wá fun OLUWA, idamẹwa ninu idamẹwa na. A o si kà ẹbọ igbesọsoke nyin yi si nyin, bi ẹnipe ọkà lati ilẹ ipakà wá, ati bi ọti lati ibi ifunti wá. Bayi li ẹnyin pẹlu yio ma mú ẹbọ igbesọsoke wá fun OLUWA ninu gbogbo idamẹwa nyin, ti ẹnyin ngbà lọwọ awọn ọmọ Israeli; ki ẹnyin ki o si mú ẹbọ igbesọsoke OLUWA ninu rẹ̀ tọ̀ Aaroni alufa wá. Ninu gbogbo ẹ̀bun nyin ni ki ẹnyin ki o si mú gbogbo ẹbọ igbesọsoke OLUWA wá, ninu gbogbo eyiti o dara, ani eyiti a yàsimimọ́ ninu rẹ̀. Nitorina ki iwọ ki o wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba fi eyiti o dara ninu rẹ̀ ṣe ẹbọ igbesọsoke, nigbana ni ki a kà a fun awọn ọmọ Lefi bi ọkà ilẹ-ipakà, ati bi ibisi ibi-ifunti. Ẹnyin o si jẹ ẹ ni ibi gbogbo, ati ẹnyin ati awọn ara ile nyin: nitoripe ère nyin ni fun iṣẹ-ìsin nyin ninu agọ́ ajọ. Ẹnyin ki yio si rù ẹ̀ṣẹ nitori rẹ̀, nigbati ẹnyin ba fi eyiti o dara ninu rẹ̀ ṣe ẹbọ igbesọsoke: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ bà ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli jẹ́, ki ẹnyin ki o má ba kú.
Num 18:1-32 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA sọ fún Aaroni pé, “Ìwọ, ati àwọn ọmọ rẹ, ati ìdílé baba rẹ ni yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n bá dá ní ibi mímọ́. Ṣugbọn ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ nìkan ni yóo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn alufaa bá dá. Pe àwọn eniyan rẹ, àwọn ọmọ Lefi, ẹ̀yà ìdílé baba rẹ, pé kí wọn wà pẹlu rẹ, kí wọ́n sì máa jíṣẹ́ fún ọ nígbà tí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ bá ń ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Ẹ̀rí. Wọn óo máa jíṣẹ́ fún ọ, wọn óo sì máa ṣe iṣẹ́ wọn ninu Àgọ́ Ẹ̀rí, ṣugbọn wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ọ̀kan ninu àwọn ohun mímọ́ tí ó wà ninu ibi mímọ́ tabi pẹpẹ ìrúbọ, kí gbogbo wọn má baà kú. Wọn óo máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ wọn ninu Àgọ́ Àjọ pẹlu rẹ. Ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe ọmọ Lefi kò gbọdọ̀ bá ọ ṣiṣẹ́. Ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ nìkan ni yóo máa ṣiṣẹ́ ninu ibi mímọ́ ati níbi pẹpẹ, kí ibinu mi má baà wá sórí àwọn ọmọ Israẹli mọ́. Mo ti yan àwọn eniyan rẹ, àwọn ọmọ Lefi, láàrin àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún ọ. Wọ́n jẹ́ ẹ̀bùn fún OLUWA, wọn óo sì máa ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ. Ṣugbọn ìwọ pẹlu àwọn ọmọ rẹ nìkan ni alufaa ti yóo máa ṣiṣẹ́ níbi pẹpẹ ìrúbọ ati níbi aṣọ ìbòjú. Èyí ni yóo jẹ́ iṣẹ́ yín nítorí ẹ̀bùn ni mo fi iṣẹ́ alufaa ṣe fun yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ àwọn ohun mímọ́ yóo kú.” OLUWA sọ fún Aaroni pé, “Mo ti fún ọ ní gbogbo ohun tí ó kù ninu àwọn ohun tí wọ́n bá fi rúbọ sí mi, ati gbogbo ohun tí àwọn ọmọ Israẹli bá yà sọ́tọ̀. Ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni mo fún gẹ́gẹ́ bi ìpín yín títí lae. Ninu gbogbo ẹbọ mímọ́ tí a kò sun lórí pẹpẹ, ẹbọ ọrẹ, ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, tí wọn ń rú sí mi yóo jẹ́ mímọ́ jùlọ fún ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ. Níbi mímọ́ ni ẹ ti gbọdọ̀ jẹ wọ́n. Àwọn ọkunrin ààrin yín nìkan ni wọ́n gbọdọ̀ jẹ wọ́n nítorí wọ́n jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ. “Bákan náà, gbogbo àwọn ọrẹ ẹbọ, ati àwọn ẹbọ fífì tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún mi, yóo jẹ́ tiyín. Mo fún ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ lọkunrin ati lobinrin, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn títí lae. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ mímọ́ ninu wọn lè jẹ ẹ́. “Mo fún ọ ní gbogbo èso àkọ́so tí àwọn ọmọ Israẹli ń mú wá fún mi lọdọọdun, ati òróró tí ó dára jùlọ, ọtí waini tí ó dára jùlọ, ati ọkà. Gbogbo àwọn àkọ́so tí ó pọ́n ní ilẹ̀ náà tí wọn bá mú wá fún OLUWA yóo jẹ́ tìrẹ, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ mímọ́ ninu ilé rẹ lè jẹ ẹ́. “Gbogbo ohun tí àwọn ọmọ Israẹli bá yà sọ́tọ̀ fún mi, tìrẹ ni. “Gbogbo àwọn àkọ́bí eniyan tabi ti ẹranko tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún mi, tìrẹ ni. Ṣugbọn o óo gba owó ìràpadà dípò àkọ́bí eniyan ati ti ẹranko tí ó bá jẹ́ aláìmọ́. Àwọn òbí yóo ra àwọn ọmọ wọn pada nígbà tí wọ́n bá pé ọmọ oṣù kan. Owó ìràpadà wọn jẹ́ ìwọ̀n ṣekeli marun-un. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́, èyí tíí ṣe ogún ìwọ̀n gera ni kí wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Ṣugbọn wọn kò ní ra àwọn àkọ́bí mààlúù, ati ti aguntan ati ti ewúrẹ́ pada, nítorí wọ́n jẹ́ mímọ́. Da ẹ̀jẹ̀ wọn sí ara pẹpẹ kí o sì fi ọ̀rá wọn rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí mi. Gbogbo ẹran wọn jẹ́ tìrẹ, gẹ́gẹ́ bí àyà tí a fì níwájú pẹpẹ, ati itan ọ̀tún ṣe jẹ́ tìrẹ. “Gbogbo àwọn ẹbọ mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún mi ni mo fún ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ, lọkunrin ati lobinrin, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn títí lae. Èyí jẹ́ majẹmu pataki tí mo bá ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ dá.” OLUWA sọ fún Aaroni pé, “O kò gbọdọ̀ gba ohun ìní kan tí eniyan lè jogún tabi ilẹ̀ ní Israẹli. Èmi OLUWA ni yóo jẹ́ ìpín ati ìní rẹ láàrin àwọn ọmọ Israẹli.” OLUWA wí pé, “Mo ti fún àwọn ọmọ Lefi ní gbogbo ìdámẹ́wàá tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún mi gẹ́gẹ́ bí ìní wọn fún iṣẹ́ ìsìn wọn ninu Àgọ́ Àjọ. Àwọn ọmọ Israẹli yòókù kò gbọdọ̀ súnmọ́ Àgọ́ Àjọ náà, kí wọn má baà dẹ́ṣẹ̀, kí wọn má baà kú. Ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi nìkan ni yóo máa ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ, wọn óo sì ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ìlànà ayérayé ni èyí fún arọmọdọmọ yín, wọn kò tún gbọdọ̀ ní ohun ìní kan mọ́, láàrin àwọn ọmọ Israẹli; nítorí pé gbogbo ìdámẹ́wàá tí àwọn ọmọ Israẹli mú wá fún mi ni mo ti fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìní. Ìdí sì nìyí tí mo fi sọ fun wọn pé wọn kò lè ní ohun ìní kan mọ́, láàrin àwọn ọmọ Israẹli.” OLUWA rán Mose: kí ó sọ fún àwọn ọmọ Lefi pé, “Nígbà tí ẹ bá gba ìdámẹ́wàá tí OLUWA ti fún yín gẹ́gẹ́ bí ìní yín, ẹ óo san ìdámẹ́wàá ninu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún OLUWA. Ọrẹ yìí yóo dàbí ọrẹ ọkà titun, ati ọtí waini titun, tí àwọn àgbẹ̀ ń mú wá fún OLUWA. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ọrẹ yín wá fún OLUWA ninu ìdámẹ́wàá tí àwọn ọmọ Israẹli bá san fun yín. Ẹ óo mú ọrẹ tí ó jẹ́ ti OLUWA wá fún Aaroni alufaa. Ninu èyí tí ó dára jù ninu àwọn ohun tí ẹ bá gbà ni kí ẹ ti san ìdámẹ́wàá yín. Nígbà tí ẹ bá ti san ìdámẹ́wàá yín lára èyí tí ó dára jù, ìyókù jẹ́ tiyín, gẹ́gẹ́ bí àgbẹ̀ ṣe máa ń kórè oko rẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti san ìdámẹ́wàá rẹ̀. Ẹ̀yin ati ẹbí yín lè jẹ ìyókù níbikíbi tí ẹ bá fẹ́, nítorí pé ó jẹ́ èrè yín fún iṣẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe ninu Àgọ́ Àjọ. Ẹ kò ní jẹ̀bi nígbà tí ẹ bá jẹ ẹ́, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti san ìdámẹ́wàá ninu èyí tí ó dára jù. Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà sọ ọrẹ mímọ́ àwọn ọmọ Israẹli di àìmọ́ nípa jíjẹ wọ́n láìsan ìdámẹ́wàá wọn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ óo kú.”
Num 18:1-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sọ fún Aaroni pé, “Ìwọ, àti àwọn ọmọ rẹ àti ìdílé baba rẹ ni yóò ru gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti dá fún ilé tí a yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run, àti ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ nìkan ni yóò máa ru ẹ̀ṣẹ̀ iṣẹ́ àlùfáà yín. Kí o sì mú àwọn ènìyàn rẹ ará Lefi láti ẹ̀yà ìran rẹ láti dàpọ̀ mọ́ ìwọ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ nígbà tí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin bá ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ níwájú Àgọ́ ẹ̀rí. Àwọn ni ó yẹ láti dúró fún ọ àti láti ṣe gbogbo iṣẹ́ ti Àgọ́, ṣùgbọ́n wọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ ibi tí a ti ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ tí a sì yà sí mímọ́ tàbí ibi pẹpẹ, tàbí gbogbo wọn àti ìwọ ló máa kú. Ó yẹ kí wọ́n darapọ̀ mọ́ ọ láti jẹ ìyà iṣẹ́ fún àìtọ́jú ibi ti àgọ́ ìpàdé àti gbogbo iṣẹ́ tí ó wà ní ibi àgọ́, àti wí pé kò sí àlejò tí ó le wá sí ẹ̀gbẹ́ ibi tí o wà. “Kí o sì mójútó iṣẹ́ ibi mímọ́ àti iṣẹ́ ibi pẹpẹ, kí ìbínú má ba wá sí orí àwọn ọmọ Israẹli mọ́. Èmi fúnra mi ti yan àwọn arákùnrin rẹ tí í ṣe ọmọ Lefi kún àwọn ọmọ Israẹli yòókù, wọn jẹ́ ẹ̀bùn fún ọ, èyí ni a fún OLúWA láti ṣe iṣẹ́ tí ó wà ní àgọ́ ìpàdé. Ṣùgbọ́n ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ni yóò mójútó iṣẹ́ àlùfáà yín fún gbogbo ohun tó bá jẹ mọ́ ibi pẹpẹ àti ti ẹ̀yin aṣọ títa, ẹ ó sì máa ṣiṣẹ́ ibi pẹpẹ àti nínú aṣọ tí a ta. Mo fún ọ ní iṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn. Ṣùgbọ́n àlejò tí ó bá súnmọ́ tòsí ibi ìyàsímímọ́ fún Ọlọ́run ni a ó pa.” Nígbà náà ni OLúWA sọ fún Aaroni pé, “Èmi fúnra mi ti fi ọ́ ṣọ́ ìdí gbogbo ẹbọ tí a bá mú wá fún gbogbo ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli bá fún mi, mo fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpín rẹ tí yóò máa ṣe. Ìwọ ni kí o ni ìpín ọrẹ mímọ́ jùlọ tí a mú kúrò ní ibi iná, nínú gbogbo ọrẹ tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ mímọ́ jùlọ, yálà ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ẹbọ ẹ̀bi, ìpín wọ̀nyí jẹ́ ti ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ. Ẹ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́ jùlọ, gbogbo ọkùnrin ni ó gbọdọ̀ jẹ ẹ́. Ó gbọdọ̀ kà á sí mímọ́. “Èyí tún jẹ́ tìrẹ pẹ̀lú: ohunkóhun tí a bá yà sọ́tọ̀ lára ẹ̀bùn ọrẹ fífì àwọn ọmọ Israẹli. Mó fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìpín tí yóò máa ṣe déédé nínú ìdílé rẹ, tí o bá wà ní mímọ́ ni o le jẹ ẹ́. “Mo fún ọ ní gbogbo òróró tí ó dára jùlọ àti gbogbo ọtí tuntun dáradára jùlọ àti ọkà tí wọ́n mú wá fún OLúWA ní àkọ́so ohun ọ̀gbìn wọn tí wọ́n kórè. Gbogbo àkọ́so nǹkan ilẹ̀ wọ́n tí wọn mú wá fún OLúWA yóò jẹ́ tìrẹ, Ẹnikẹ́ni nínú ìdílé rẹ, àwọn tí ó jẹ́ mímọ́ nínú ìdílé rẹ lè jẹ ẹ́. “Gbogbo nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ fún OLúWA ní Israẹli jẹ́ tìrẹ. Gbogbo àkọ́bí nínú gbogbo ohun alààyè tí wọ́n mú wá fún OLúWA, ìbá à jẹ́ ti ènìyàn tàbí ti ẹranko jẹ́ tìrẹ ṣùgbọ́n o gbọdọ̀ ra gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin padà àti àkọ́bí àwọn ẹranko aláìmọ́. Nígbà tí wọ́n bá pé oṣù kan, o gbọdọ̀ rà wọ́n padà ní iye owó ìràpadà tí í ṣe ṣékélì márùn-ún fàdákà, gẹ́gẹ́ bí iye ṣékélì ibi mímọ́ tí ó wọn ìwọ̀n ogún (20) gera. “Ṣùgbọ́n o kò gbọdọ̀ ra àwọn àkọ́bí ọmọ màlúù, àgùntàn tàbí ewúrẹ́; wọ́n jẹ́ mímọ́. Wọ́n ẹ̀jẹ̀ wọn sórí pẹpẹ kí o sì sun ọ̀rá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àfinásun, ẹbọ òórùn dídùn sí OLúWA. Ẹran wọn gbọdọ̀ jẹ́ tìrẹ, gẹ́gẹ́ bí igẹ̀ ọrẹ ẹbọ fífì àti itan ọ̀tún ṣe jẹ́ tìrẹ. Ohunkóhun tí a bá ti yà sọ́tọ̀ nínú ọrẹ àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n mú wá fún OLúWA ni mo fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìpín rẹ tí yóò máa ṣe déédé. Ó jẹ́ májẹ̀mú iyọ̀ láéláé níwájú OLúWA fún ìwọ àti ọmọ rẹ.” OLúWA sọ fún Aaroni pé, “O kò ní ní ogún nínú ilẹ̀ wọn bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ní ní ìpín láàrín wọn, Èmi ni ìpín àti ogún rẹ láàrín àwọn ọmọ Israẹli. “Mó ti fún àwọn ọmọ Lefi ní gbogbo ìdámẹ́wàá ní Israẹli gẹ́gẹ́ bí ogún fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe, nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ níbi àgọ́ ìpàdé Láti ìsinsin yìí àwọn ọmọ Israẹli, kò gbọdọ̀ súnmọ́ àgọ́ ìpàdé, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ wọn yóò jẹ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọn á sì kú Àwọn ọmọ Lefi ní ó gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ tí ó wà nínú àgọ́ ìpàdé, wọn yóò sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí wọ́n bá kúrò láti ṣe é. Èyí ni ìlànà láéláé fún àwọn ìran tí ó ń bọ̀. Wọn kò nígbà ogún kankan láàrín àwọn ọmọ Israẹli. Kàkà bẹ́ẹ̀, mo fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí ogún wọn, ìdákan nínú ìdámẹ́wàá tí àwọn ọmọ Israẹli pèsè gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí OLúWA. Èyí ni mo wí nípa wọn: Wọn kò nígba ogún kankan láàrín àwọn ọmọ Israẹli.” OLúWA sọ fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Lefi kí o sì wí fún wọn pé: ‘Nígbà tí ìdámẹ́wàá bá ń wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ. O gbọdọ̀ mú ìdámẹ́wàá lára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ OLúWA. A ó ka ọrẹ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọkà irúgbìn láti ilẹ̀ ìpakà tàbí wáìnì láti fún wa. Báyìí ni ìwọ gan an náà yóò mú ọrẹ wa fún OLúWA láti ara ìdámẹ́wàá tí ìwọ gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli. Láti ara ìdámẹ́wàá ó gbọdọ̀ mú ọrẹ OLúWA fún Aaroni àlùfáà. Ìwọ gbọdọ̀ mú wá gẹ́gẹ́ bí ìpín OLúWA èyí tí ó dára jùlọ àti tí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ lára gbogbo nǹkan tí wọ́n mú wá fún ọ.’ “Sọ fún àwọn ọmọ pé: ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá mú ìpín tí ó dára jù wá, a ó kà á sí fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí ìkórè láti ilẹ̀ ìpakà tàbí ìfúntí yín. Ìwọ àti àwọn ìdílé rẹ̀ le jẹ èyí tí ó kù ní ibikíbi gbogbo. Nítorí pé ó jẹ́ ọrẹ fún iṣẹ́ rẹ níbi àgọ́ ìpàdé. Nípa ṣíṣe ìgbékalẹ̀ ìpín tí ó dára jùlọ o kò ní jẹ̀bi lórí ọ̀rọ̀ yìí, ìwọ kò sì ní ba ọrẹ mímọ́ àwọn ọmọ Israẹli jẹ́, ìwọ kì yóò sì kú.’ ”