Num 16:1-40

Num 16:1-40 Bibeli Mimọ (YBCV)

NJẸ Kora, ọmọ Ishari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi, ati Datani on Abiramu, awọn ọmọ Eliabu, ati On, ọmọ Peleti, awọn ọmọ Reubeni, dìmọ: Nwọn si dide niwaju Mose, pẹlu ãdọtalerugba ọkunrin ninu awọn ọmọ Israeli, ijoye ninu ijọ, awọn olorukọ ninu ajọ, awọn ọkunrin olokikí: Nwọn si kó ara wọn jọ pọ̀ si Mose ati si Aaroni, nwọn si wi fun wọn pe, O tó gẹ, nitoripe gbogbo ijọ li o jẹ́ mimọ́, olukuluku wọn, OLUWA si mbẹ lãrin wọn: nitori kili ẹnyin ha ṣe ngbé ara nyin ga jù ijọ OLUWA lọ? Nigbati Mose gbọ́, o doju rẹ̀ bolẹ: O si sọ fun Kora ati fun gbogbo ẹgbẹ rẹ̀ pe, Li ọla OLUWA yio fi ẹniti iṣe tirẹ̀ hàn, ati ẹniti o mọ́; yio si mu u sunmọ ọdọ rẹ̀: ani ẹniti on ba yàn ni yio mu sunmọ ọdọ rẹ̀. Ẹ ṣe eyi; Ẹ mú awo-turari, Kora, ati gbogbo ẹgbẹ rẹ̀; Ki ẹ si fi iná sinu wọn, ki ẹ si fi turari sinu wọn niwaju OLUWA li ọla: yio si ṣe, ọkunrin ti OLUWA ba yàn, on ni ẹni mimọ́: o tó gẹ, ẹnyin ọmọ Lefi. Mose si wi fun Kora pe, Emi bẹ̀ nyin, ẹnyin ọmọ Lefi, ẹ gbọ́: Ohun kekere ha ni li oju nyin, ti Ọlọrun Israeli yà nyin kuro ninu ijọ Israeli, lati mú nyin sunmọ ọdọ ara rẹ̀ lati ma ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ OLUWA, ati lati ma duro niwaju ijọ lati ma ṣe iranṣẹ fun wọn; O si mú iwọ sunmọ ọdọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ gbogbo, awọn ọmọ Lefi pẹlu rẹ; ẹnyin si nwá iṣẹ-alufa pẹlu? Nitorina, iwọ ati gbogbo ẹgbẹ rẹ kójọ pọ̀ si OLUWA: ati kini Aaroni, ti ẹnyin nkùn si i? Mose si ranṣẹ pè Datani ati Abiramu, awọn ọmọ Eliabu: nwọn si wipe, Awa ki yio gòke wá: Ohun kekere ha ni ti iwọ mú wa gòke lati ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin wá, lati pa wa li aginjù, ti iwọ fi ara rẹ jẹ́ alade lori wa patapata? Pẹlupẹlu iwọ kò ti imú wa dé ilẹ kan ti nṣàn fun warà ati fun oyin, bẹ̃ni iwọ kò fun wa ni iní ilẹ ati ọgba-àjara: iwọ o yọ oju awọn ọkunrin wọnyi bi? awa ki yio gòke wá. Mose si binu gidigidi, o si wi fun OLUWA pe, Máṣe kà ẹbọ wọn si: emi kò gbà kẹtẹkẹtẹ kan lọwọ wọn, bẹ̃li emi kò pa ẹnikan wọn lara. Mose wi fun Kora pe, Ki iwọ ati gbogbo ẹgbẹ rẹ ki o wá siwaju OLUWA, iwọ, ati awọn, ati Aaroni li ọla: Ki olukuluku wọn ki o mú awo-turari rẹ̀, ki ẹ si fi turari sinu wọn, ki olukuluku nyin ki o mú awo-turari rẹ̀ wá siwaju OLUWA, ãdọtalerugba awo-turari; iwọ pẹlu ati Aaroni, olukuluku awo-turari rẹ̀. Olukuluku wọn si mú awo-turari rẹ̀, nwọn si fi iná sinu wọn, nwọn si fi turari lé ori wọn, nwọn si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, pẹlu Mose ati Aaroni. Kora si kó gbogbo ijọ enia jọ si wọn si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: ogo OLUWA si hàn si gbogbo ijọ enia na. OLUWA si sọ fun Mose ati Aaroni pe, Ẹ yà ara nyin kuro lãrin ijọ yi, ki emi ki o run wọn ni iṣéju kan. Nwọn si doju wọn bolẹ, nwọn wipe, Ọlọrun, Ọlọrun ẹmi gbogbo enia, ọkunrin kan ha le ṣẹ̀, ki iwọ ki o si binu si gbogbo ijọ? OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun ijọ pe, Ẹ gòke wá kuro ni sakani agọ́ Kora, Datani, ati Abiramu. Mose si dide, o si tọ̀ Datani ati Abiramu lọ; awọn àgba Israeli si tẹle e. O si sọ fun ijọ pe, Mo bẹ̀ nyin, ẹ kuro ni ibi agọ́ awọn ọkunrin buburu yi, ẹ má si ṣe fọwọkàn ohun kan ti iṣe ti wọn, ki ẹ má ba run ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn. Bẹ̃ni nwọn si gòke lọ kuro nibi agọ́ Kora, Datani ati Abiramu, ni ìha gbogbo: Datani ati Abiramu si jade, nwọn si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ wọn, ati awọn aya wọn, ati awọn ọmọ wọn ọkunrin, ati awọn ọmọ wọn wẹ́wẹ. Mose si wipe, Nipa eyi li ẹnyin o mọ̀ pe OLUWA li o rán mi lati ṣe gbogbo iṣẹ wọnyi; ati pe emi kò ṣe wọn lati inu ara mi wá. Bi awọn ọkunrin wọnyi ba kú bi gbogbo enia ti ikú, tabi bi a ba si bẹ̀ wọn wò bi ãti ibẹ̀ gbogbo enia wò; njẹ OLUWA ki o rán mi. Ṣugbọn bi OLUWA ba ṣe ohun titun, ti ilẹ ba si là ẹnu rẹ̀, ti o si gbe wọn mì, pẹlu ohun gbogbo ti iṣe ti wọn, ti nwọn si sọkalẹ lọ si ipò-okú lãye; nigbana ẹnyin o mọ̀ pe awọn ọkunrin wọnyi ti gàn OLUWA. O si ṣe, bi o ti pari gbogbo ọ̀rọ wọnyi ni sisọ, ni ilẹ là pẹrẹ nisalẹ wọn: Ilẹ si yà ẹnu rẹ̀, o si gbe wọn mì, ati awọn ara ile wọn, ati gbogbo awọn enia ti iṣe ti Kora, ati gbogbo ẹrù wọn. Awọn, ati ohun gbogbo ti iṣe ti wọn, sọkalẹ lọ lãye si ipò-okú, ilẹ si pa ẹnu dé mọ́ wọn, nwọn si run kuro ninu ijọ. Gbogbo enia Israeli ti o yi wọn ká si salọ nitori igbe wọn: nitoriti nwọn wipe, Ki ilẹ ki o má ba gbe wa mì pẹlu. Iná si jade wá lati ọdọ OLUWA, o si run awọn ãdọtalerugba ọkunrin nì ti nwọn mú turari wá. OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun Eleasari ọmọ Aaroni alufa, pe ki o mú awo-turari wọnni kuro ninu ijóna, ki iwọ ki o si tu iná na ká sọhún; nitoripe nwọn jẹ́ mimọ́. Awo-turari ti awọn ẹlẹṣẹ wọnyi si ọkàn ara wọn, ni ki nwọn ki o fi ṣe awo fẹlẹfẹlẹ fun ibori pẹpẹ: nitoriti nwọn mú wọn wá siwaju OLUWA, nitorina ni nwọn ṣe jẹ́ mimọ́: nwọn o si ma ṣe àmi fun awọn ọmọ Israeli. Eleasari alufa si mú awo-turari idẹ wọnni, eyiti awọn ẹniti o jóna fi mú ẹbọ wá; a si rọ wọn li awo fẹlẹfẹlẹ fun ibori pẹpẹ: Lati ma ṣe ohun iranti fun awọn ọmọ Israeli, ki alejò kan, ti ki iṣe irú-ọmọ Aaroni, ki o máṣe sunmọtosi lati mú turari wá siwaju OLUWA; ki o má ba dabi Kora, ati awọn ẹgbẹ rẹ̀: bi OLUWA ti wi fun u lati ọwọ́ Mose wá.

Num 16:1-40 Yoruba Bible (YCE)

Kora ọmọ Iṣari láti inú ìdílé Kohati ọmọ Lefi, pẹlu Datani ati Abiramu àwọn ọmọ Eliabu, pẹlu Ooni ọmọ Peleti láti inú ẹ̀yà Reubẹni gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n kó aadọtaleerugba (250) ọkunrin tí wọ́n jọ jẹ́ olórí ati olókìkí ninu àwọn ọmọ Israẹli sòdí láti dìtẹ̀ mọ́ Mose. Wọ́n dojú kọ Mose ati Aaroni, wọ́n ní, “Ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí kọjá ààyè yín, nítorí pé olukuluku àwọn ọmọ Israẹli ni ó jẹ́ ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA, OLUWA sì ń bẹ láàrin wọn. Kí ló dé tí ẹ̀yin gbé ara yín ga ju gbogbo àwọn eniyan OLUWA lọ?” Nígbà tí Mose gbọ́, ó dojúbolẹ̀, Ó sì sọ fún Kora ati àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Ní ọ̀la OLUWA yóo fi ẹni tí í ṣe tirẹ̀ tí ó jẹ́ ẹni mímọ́ hàn. Ẹni tí OLUWA bá sì yàn ni yóo mú kí ó súnmọ́ òun. Ní ọ̀la ìwọ ati àwọn ẹgbẹ́ rẹ, ẹ mú àwo turari, kí ẹ fi iná sinu wọn, kí ẹ sì gbé wọn lọ siwaju OLUWA. Ẹni tí OLUWA bá yàn ni yóo jẹ́ ẹni mímọ́; ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí kọjá ààyè yín, ẹ̀yin ọmọ Lefi!” Mose bá kọjú sí Kora, ó ní: “Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ọmọ Lefi! Ṣé nǹkan kékeré ni, pé Ọlọrun Israẹli yà yín sọ́tọ̀ láàrin àwọn ọmọ Israẹli láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ninu Àgọ́ Àjọ OLUWA, ati fún ìjọ eniyan Israẹli? OLUWA ti fún ẹ̀yin ati àwọn ọmọ Lefi yòókù ní anfaani yìí, ṣugbọn nisinsinyii, ẹ̀ ń ṣe ojú kòkòrò sí iṣẹ́ alufaa. Ṣé ẹ kò mọ̀ pé OLUWA ni ìwọ ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí, nígbà tí ẹ̀ ń fi ẹ̀sùn kan Aaroni? Ta ni Aaroni tí ẹ̀yin ń fi ẹ̀sùn kàn?” Mose bá ranṣẹ lọ pe Datani ati Abiramu, àwọn ọmọ Eliabu, ṣugbọn wọ́n kọ̀ wọn kò wá. Wọ́n ní, “O mú wa wá láti ilẹ̀ ọlọ́ràá Ijipti tí ó kún fún wàrà ati fún oyin, o fẹ́ wá pa wá sinu aṣálẹ̀ yìí, sibẹ kò tó ọ, o tún fẹ́ sọ ara rẹ di ọba lórí gbogbo wa. O kò tíì kó wa dé ilẹ̀ tí ó lọ́ràá tí ó kún fún wàrà ati oyin, tabi kí o fún wa ní ọgbà àjàrà ati oko. Ṣé o fẹ́ fi júújúú bo àwọn eniyan wọnyi lójú ni, a kò ní dá ọ lóhùn.” Mose bínú gidigidi, ó sì sọ fún OLUWA pé, “OLUWA, má ṣe gba ẹbọ àwọn eniyan wọnyi. N kò ṣe ibi sí ẹnikẹ́ni ninu wọn bẹ́ẹ̀ ni ń kò gba kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹnikẹ́ni wọn.” Mose bá sọ fún Kora pé, “Ní ọ̀la kí ìwọ ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ wá siwaju Àgọ́ Àjọ. Aaroni pẹlu yóo wà níbẹ̀. Kí olukuluku yín ati Aaroni pẹlu mú àwo turari rẹ̀, kí ẹ sì fi turari sí i láti rúbọ sí OLUWA. Gbogbo rẹ̀ yóo jẹ́ aadọtaleerugba (250) àwo turari.” Olukuluku wọn sì mú àwo turari tirẹ̀, wọ́n fi ẹ̀yinná ati turari sí i, wọ́n sì dúró ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ pẹlu Mose ati Aaroni. Kora kó gbogbo ìjọ eniyan náà jọ sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ láti dojú kọ Mose ati Aaroni; Ògo OLUWA sì farahàn, àwọn eniyan náà sì rí i. OLUWA sì sọ fún Mose ati Aaroni pé: “Ẹ bọ́ sí apá kan kí n lè rí ààyè pa àwọn eniyan náà run ní ìṣẹ́jú kan.” Mose ati Aaroni bá dojúbolẹ̀, wọ́n gbadura sí OLUWA, pé, “Ọlọrun, ìwọ ni orísun ìyè, ìwọ yóo ha tìtorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkan bínú sí gbogbo ìjọ eniyan bí?” OLUWA bá dá Mose lóhùn pé, “Sọ fún àwọn eniyan náà kí wọ́n kúrò ní agbègbè àgọ́ àwọn Kora ati Datani ati Abiramu.” Mose bá dìde pẹlu àwọn àgbààgbà Israẹli, wọ́n lọ sọ́dọ̀ Datani ati Abiramu. Ó sì sọ fún àwọn eniyan pé, “Ẹ kúrò ní agbègbè àgọ́ àwọn ọkunrin burúkú wọnyi, kí ẹ má sì fọwọ́ kan nǹkankan tí ó jẹ́ tiwọn, kí ẹ má baà pín ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” Àwọn eniyan náà bá kúrò ní agbègbè àgọ́ àwọn Kora ati Datani ati Abiramu. Datani ati Abiramu pẹlu aya ati àwọn ọmọ wọn jáde wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ wọn. Mose sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Nisinsinyii ni ẹ óo mọ̀ pé èmi kọ́ ni mo yan ara mi ṣugbọn OLUWA ni ó rán mi láti ṣe gbogbo ohun tí mò ń ṣe. Bí àwọn ọkunrin wọnyi bá kú ikú tí kò mú ìbẹ̀rù lọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, a jẹ́ wí pé kì í ṣe OLUWA ni ó rán mi. Ṣugbọn bí OLUWA bá ṣe ohun tí etí kò gbọ́ rí, tí ilẹ̀ bá yanu tí ó gbé wọn mì pẹlu àwọn eniyan wọn ati àwọn ohun ìní wọn, tí wọn sì bọ́ sinu ibojì láàyè, ẹ óo mọ̀ pé wọ́n ti kọ OLUWA sílẹ̀.” Ní kété tí Mose parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ilẹ̀ tí wọ́n dúró lé lórí là sí meji, ó yanu, ó sì gbé wọn mì, ati àwọn ati ìdílé wọn, ati ohun ìní wọn. Ilẹ̀ sì gbé Kora mì pẹlu àwọn eniyan rẹ̀ ati gbogbo ohun ìní wọn. Gbogbo wọn, ati ohun ìní wọn, ati àwọn eniyan wọn, lọ sí ipò òkú láàyè, ilẹ̀ panudé, wọ́n sì ṣègbé kúrò láàrin ìjọ eniyan Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli tí ó wà níbẹ̀ sì sálọ nígbà tí wọn gbọ́ igbe wọn. Wọ́n bẹ̀rù kí ilẹ̀ má baà gbé àwọn náà mì. OLUWA sì rán iná láti run àwọn aadọtaleerugba (250) ọkunrin tí wọn mú àwo turari wá siwaju Àgọ́ Àjọ. OLUWA sọ fún Mose pé, “Sọ fún Eleasari ọmọ Aaroni, alufaa pé kí ó kó àwọn àwo turari wọ̀n-ọn-nì kúrò láàrin àjókù àwọn eniyan náà. Kí ó sì da iná inú wọn káàkiri jìnnà jìnnà nítorí àwọn àwo turari náà jẹ́ mímọ́. Kí ó mú àwo turari àwọn ọkunrin tí wọ́n kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kí ó fi wọ́n rọ àwo fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ fún ìbòrí pẹpẹ, nítorí níwọ̀n ìgbà tí wọ́n ti mú wọn wá siwaju OLUWA, wọ́n ti di mímọ́. Èyí yóo sì jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli.” Eleasari bá kó àwọn àwo turari náà tí àwọn tí ó jóná fi rú ẹbọ, ó fi wọ́n rọ àwo fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ fún ìbòrí pẹpẹ. Èyí sì jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli pé ẹnikẹ́ni tí kì í bá ṣe ọmọ Aaroni kò gbọdọ̀ wá siwaju pẹpẹ OLUWA láti sun turari, kí ẹni náà má baà dàbí Kora ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti rán Mose pé kí ó sọ fún Eleasari.

Num 16:1-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Kora ọmọ Isari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi àwọn ọmọ Reubeni: Datani àti Abiramu, àwọn ọmọ Eliabu, àti Oni ọmọ Peleti mú ènìyàn mọ́ra. Wọ́n sì dìde sí Mose, pẹ̀lú àádọ́tà-lé-nígba (250) ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Israẹli, ìjòyè nínú ìjọ, àwọn olórúkọ nínú àjọ, àwọn ọkùnrin olókìkí. Wọ́n kó ara wọn jọ láti tako Mose àti Aaroni, wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ ti kọjá ààyè yín, ó tó gẹ́ẹ́! Mímọ́ ni gbogbo ènìyàn, kò sí ẹni tí kò mọ́ láàrín wọn, OLúWA sì wà pẹ̀lú wọn, nítorí kí wá ni ẹ̀yin ṣe gbé ara yín ga ju ìjọ ènìyàn OLúWA lọ?” Nígbà tí Mose gbọ́ èyí, ó dojúbolẹ̀, Ó sì sọ fún Kora àti gbogbo ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Ní ọ̀la ni OLúWA yóò fi ẹni tí í ṣe tirẹ̀ àti ẹni tó mọ́ hàn, yóò sì mú kí ẹni náà súnmọ́ òun. Ẹni tí ó bá yàn ni yóò mú kí ó súnmọ́ òun. Kí Kora àti gbogbo ẹgbẹ́ rẹ̀ ṣe èyí, Ẹ mú àwo tùràrí. Kí ẹ sì fi iná àti tùràrí sínú rẹ̀ lọ́la níwájú OLúWA, yóò sì ṣe, ọkùnrin tí OLúWA bá yàn òun ni. Ẹ̀yin ọmọ Lefi, ẹ ti kọjá ààyè yín!” Mose sì tún sọ fún Kora pé, “Ẹ gbọ́ báyìí o, ẹ̀yin ọmọ Lefi! Kò ha tọ́ fún yín pé Ọlọ́run Israẹli ti yà yín sọ́tọ̀ lára ìjọ Israẹli yòókù, tó sì mú yín súnmọ́ ara rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ OLúWA àti láti dúró ṣiṣẹ́ ìsìn níwájú àwọn ènìyàn? Ó ti mú àwọn ènìyàn yín tó jẹ́ ọmọ Lefi súnmọ́ ara rẹ̀, ṣùgbọ́n báyìí ẹ tún ń wá ọnà láti ṣiṣẹ́ àlùfáà. OLúWA ni ìwọ àti gbogbo ẹlẹgbẹ́ rẹ takò. Ta a ni Aaroni jẹ́ tí ẹ̀yin ó fi kùn sí i?” Mose sì ránṣẹ́ sí Datani àti Abiramu àwọn ọmọ Eliabu. Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé “Àwa kò ní í wá! Kò ha tó gẹ́ẹ́ pé o ti mú wa jáde láti ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin láti pa wá sínú aginjù yìí? O tún wá fẹ́ sọ ara rẹ di olúwa lé wa lórí bí? Síbẹ̀síbẹ̀ ìwọ kò sì tí ì mú wa dé ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, bẹ́ẹ̀ ni o kò sì pín ilẹ̀ ìní àti ọgbà àjàrà. Ìwọ ha fẹ́ sọ wá di ẹrú bí? Rárá o, àwa kì yóò gòkè wá!” Nígbà náà ni Mose bínú gidigidi, ó sì sọ fún OLúWA pé, “Má ṣe gba ọrẹ wọn, èmi kò gba kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ́wọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì pa ẹnikẹ́ni nínú wọn lára!” Mose sọ fún Kora pé, “Ìwọ àti ọmọ lẹ́yìn rẹ gbọdọ̀ fi ara hàn níwájú OLúWA lọ́la—gbogbo yín, ìwọ, àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ àti Aaroni. Kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín mú àwo tùràrí, kí ó sì fi tùràrí sínú rẹ̀, kí gbogbo rẹ̀ jẹ́ àádọ́tà-lé-nígba àwo tùràrí (250) kí ẹ sì ko wá síwájú OLúWA. Ìwọ àti Aaroni yóò mú àwo tùràrí wá pẹ̀lú.” Nígbà náà ni oníkálùkù wọn mú àwo tùràrí, wọ́n fi iná àti tùràrí sí i nínú, wọ́n sì dúró sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, àwọn pẹ̀lú Mose àti Aaroni. Nígbà tí Kora kó gbogbo àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ jọ sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ògo OLúWA sì farahan gbogbo ìjọ ènìyàn. OLúWA sì sọ fún Mose àti Aaroni pé, “Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò láàrín ìjọ wọ̀nyí, kí ń ba à le pa wọ́n run lẹ́ẹ̀kan náà.” Ṣùgbọ́n Mose àti Aaroni dojúbolẹ̀ wọ́n sì kígbe sókè pé, “Ọlọ́run, Ọlọ́run ẹ̀mí gbogbo ènìyàn, Ìwọ ó wa bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn nígbà tó jẹ́ pé ẹnìkan ló ṣẹ̀?” OLúWA tún sọ fún Mose pé, “Sọ fún ìjọ ènìyàn pé, ‘Kí wọ́n jìnnà sí àgọ́ Kora, Datani àti Abiramu.’ ” Mose sì dìde lọ bá Datani àti Abiramu àwọn àgbàgbà Israẹli sì tẹ̀lé. Ó sì kìlọ̀ fún ìjọ ènìyàn pé, “Ẹ kúrò ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú yìí! Ẹ má ṣe fọwọ́ kan ohun kan tí í ṣe tiwọn kí ẹ má ba à parun nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” Àwọn ènìyàn sì sún kúrò ní àgọ́ Kora, Datani àti Abiramu. Datani àti Abiramu jáde, àwọn ìyàwó wọn àti àwọn ọmọ wọn sì dúró sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ wọn. Nígbà náà ni Mose wí pé, “Báyìí ni ẹ ó ṣe mọ̀ pé OLúWA ló rán mi láti ṣe gbogbo iṣẹ́ wọ̀nyí àti pé kì í ṣe ìfẹ́ inú mi ni àwọn ohun tí mò ń ṣe. Bí àwọn ènìyàn yìí bá kú bí gbogbo ènìyàn ti ń kú, bí ìrírí wọn kò bá sì yàtọ̀ sí ti àwọn ènìyàn yòókù, a jẹ́ pé kì í ṣe OLúWA ló rán mi. Ṣùgbọ́n bí OLúWA bá ṣe ohun tuntun, tí ilẹ̀ sì la ẹnu, tó gbé wọn mì, àwọn pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ní, tí wọ́n sì wọ inú ibojì wọn lọ láààyè, nígbà náà ni ẹ̀yin ó mọ̀ pé àwọn ènìyàn yìí ti kẹ́gàn OLúWA.” Bí ó sì ṣe parí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ilẹ̀ pín sí méjì nísàlẹ̀ wọn, ilẹ̀ sì lanu ó sì gbé wọn mì pẹ̀lú gbogbo ará ilé wọn àti àwọn ènìyàn Kora àti gbogbo ohun tí wọ́n ní. Gbogbo wọn sì sọ̀kalẹ̀ sínú ibojì wọn láààyè pẹ̀lú ohun gbogbo tí wọ́n ní, ilẹ̀ sì padé mọ́ wọn, wọ́n sì ṣègbé kúrò láàrín ìjọ ènìyàn. Gbogbo ènìyàn Israẹli tí ó yí wọn ká sì sálọ tí àwọn yòókù gbọ́ igbe wọn, wọ́n wí pé, “Ilẹ̀ yóò gbé àwa náà mì pẹ̀lú.” Iná sì jáde láti ọ̀dọ̀ OLúWA ó sì run àádọ́tà-lé-nígba ọkùnrin (250) tí wọ́n mú tùràrí wá. OLúWA sọ fún Mose pé, “Sọ fún Eleasari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà, pé kí ó mú àwọn àwo tùràrí jáde kúrò nínú iná nítorí pé wọ́n jẹ́ mímọ́, kí ó sì tan iná náà káàkiri sí ibi tó jìnnà. Èyí ni àwo tùràrí àwọn tí ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Kí ẹ gún àwo tùràrí yìí, kí ẹ sì fi ṣe ìbòrí fún pẹpẹ, wọ́n jẹ́ mímọ́ nítorí pé wọ́n ti mú wọn wá síwájú OLúWA. Kí wọ́n jẹ́ ààmì fún àwọn ọmọ Israẹli.” Eleasari tí í ṣe àlùfáà sì kó gbogbo àwo tùràrí tí àwọn tí ó jóná mú wa, ó gún wọn pọ̀, ó fi ṣe ìbòrí fún pẹpẹ, Gẹ́gẹ́ bí OLúWA ṣe sọ láti ẹnu Mose. Èyí yóò jẹ́ ohun ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, àlejò yàtọ̀ sí irú-ọmọ Aaroni kò gbọdọ̀ jó tùràrí níwájú OLúWA, ẹni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóò dàbí Kora àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀.